Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi ru àwọn tó ń bèèrè fún 'Yoruba Nation'

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi rú àwọn tó ń bèrè fún 'Yoruba Nation'

Olugbọn ti Orile-Igbọn, Ọba Francis Alao ti kesi awọn lọbalọba ni ilẹ Yoruba lati maṣe sọ ọrọ ''Yoruba Nation di ọrọ oṣelu.

Ọba Francis lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ohun gbogbo ni wọn ti ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria lo yẹ ki aarẹ Buhari dojukọ kii ṣe Sunday Igboho tabi Nnamdi Kanu.

Olugbọn ni iya ati iṣẹ ti ohun ba awọn ọmọ Naijiria finra lo jẹ ki awọn eniyan ma a lọgun lati da duro gẹgẹ bi ẹya.

Olugbọn ti Orile-Igbọn, Ọba Francis Alaorọ Aarẹ Buhari lati tun orukọ rẹ ṣe nitori kii ṣe Buhari ti awọn mọ ni ọdun 1980 ni eleyii mọ.

Ẹ wo ẹkunrẹrẹ fidio naa fun ero Ọba Francis lori idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023.