Ogun House of Assembly Crisis: Dare Kadiri ní òun kìí ṣe olè, wọ́n lo ayédèrú ìbuwọ́lù òun láti gbé ₦50m jáde

Oríṣun àwòrán, Ogun State House of Assembly Facebook
Igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Dare Kadiri ti ke gbajare pe awọn eeyan kan fi ẹda ibuwọlu oun, ta mọsi ‘Signature’ gba aadọta miliọnu naira ninu apo ifowopamọ banki, ti ile asofin naa n lo.
Kadiri, ti họwu-họwu ti wa laarin oun ati olori ile naa, iyẹn Olakunle Oluomo lori iyọnipo rẹ sọ pe, oun n fẹ lati mọ bi wọn ṣe lo orukọ oun lati gba owo ti oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ jade.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn iwe ti oun foju ganni nigba ti wọn ke si oun ni ọọfisi ajọ EFCC l'Eko fi han pe, wọn lo ibuwọlu oun lati gba owo to iye rẹ to ọpọ miliọnu naira fun awọn idanilẹkọọ kan loke okun, ti oun ko si mọ ohunkohun nipa rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
- Daddy Freeze pe ọmọ David Oyedepo níjà lórí ìdí tó fi ri bíbélì 15 mọ́lẹ̀ sínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners l'Amerika
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Ìjọba Eko fi ẹ̀bùn ńlá tọrẹ fún ìyá ọmọ tó kú lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation l‘Ojota
- Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú kí irun pọ̀ lára obìnrin láì ṣe ọkùnrin
- Àìsàn ‘Dementia’ ló ń bá ọkọ́ mi Olu Jacobs fínra láti ọdún díẹ̀ - Joke Silva
- Àlàyé rèé lórí ohun tó fa ìkúnsínú nínú ẹgbẹ́ Ìlana Omo Oodua
O ni "Mo ka iroyin lori ayelujara ti wọn fi ibuwọlu mi si, lẹyin ọjọ mẹta si asiko naa ni EFCC pe mi, mo si tẹkọ leti lọ si ọọfisi wọn."
"Nigba ti mo de ibẹ, wọn bi mi ni awọn ibeere kan, mo si ṣalaye pe mi o mọ ohunkohun nipa iwe naa ati owo ti wọn n sọrọ rẹ, mo si sọ fun wọn pe ki wọn lọ beere lọwọ abẹnugan ile aṣofin, wọn si ni ki n maa ba temi lọ."
Aṣofin naa ni oun mọ pe EFCC n ṣe iwadii ile aṣofin ipinlẹ Ogun, ati pe ile naa mọọmọ yọ oun nipo igbakeji abẹnugan ile nitori awọn ibeere oun nipa bi eto iṣuna ile naa ṣe n lọ.
Kadiri sọ pe gẹgẹ bii igbakeji olori ile, oun ko mọ ohunkohun nipa bi owo ṣe n wọle ati bi owo ṣe n jade nile ọhun, koda, o ni oun ko si ninu igbimọ kankan nitori olori ti yọ kuro ninu gbogbo awọn igbimọ amuṣẹya to wa ninu ile ọhun ṣaaju.
Ni ti awọn nnkan toju rẹ ri ni ọọfisi EFCC, Kadiri sọ pe iwe meji pere ni oun ri ni ori ayelujara to ni ibuwọlu oun, ṣugbọn oniruru iwe ni oun foju ganni ni ọọfisi EFCC, eyi ti wọn ni oun fi gbe owo jade.
O ni "Mo ri apo Ghana-Must-Go ti ayederu iwe kun inu rẹ pẹlu ibuwọlu mi ati ibuwọlu awọn ọmọ ile miran eyii ti wọn ni mo lo lati gbe owo jade fun idanikẹkọọ loke oke, ṣugbọn n ko mọ ohunkohun nipa owo tabi idanilẹkọọ kankan."
Emi ko se ayederu ibuwọlu Kadiri, n kii se akapo ile asofin - Olori ile sọrọ
Ẹwẹ,olori ile asofin naa, Oluomo sọ pe irọ nla gba a ni pe oun loun ṣe ayederu ibuwọlu Kadiri nitori pe oun kọ ni akapo ile.
Oluomo ni oun ti pe igbakeji oun nigba kan ri naa lẹjọ lori ẹsun pe o pe oun ni ole.
Gẹgẹ bii ohun ti Oluomo sọ, ipade oun ati Kadiri di ile ẹjọ.


















