Osun Hotel Murder: Ìyàwó Timothy Adegoke bú sẹ́kún pé àwọn kan ti ń fi owó lọ abúrò ọkọ òhun lórí ẹjọ́ yìí

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ẹni to jẹ oludasile Hilton Hotel, Rahman Adedoyin to jẹ ilé ìtura ti ìròyìn sọ pé akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì Obafemi Awolowo ti Ilé-Ifẹ̀, Timothy Adegoke kú si ti sọ̀rọ̀ pe oun ko mọ nkankan nipa iku rẹ rara.
Adedoyin to ti wa ni ahamo Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Osun bayii lori ẹ̀sùn ikú Adegoke to jẹ akẹ́kọ̀ọ́ imọ ipele Masters jẹ ko di mimọ pe oun ko padi àpò pọ mọ awọn oṣiṣẹ oun tabi ẹnikẹ́ni lati pá akẹ́kọ̀ọ́ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, igba àkọ́kọ́ ti yoo gbọ́ nipa Adegoke ni igba ti awọn Ọlọpaa kede rẹ pe o di awati.
- Mo ti ṣetán láti pín ₦250m sí ilé àwọn ọmọ aláìníyàá káàkiri Naijiria - Davido
- Irú ikú wo gan ló pa àbúrò Dangote? Aliko Dangote ṣàlàyé àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí abúrò rẹ̀ tó kú
- Ó yẹ́ kí àwọn olóṣèlú kẹ́kọ̀ọ́ lára Goodluck Jonathan, olùfẹ́ ìrẹ́pọ̀ ni - Lawan
- Wọ́n lù mí bíi ẹní máa kú, wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn nílé Princess kí n tó dé àgọ́ ọlọ́pàá - Baba Ijesha
- EndSARS Panel report: Amẹrika ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ìwàdìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn Lekki toll gate
- Buhari ní òun á gbé ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu yẹ̀wò
- Buhari buwọ́lu N656 bílíọ́nù owó ìdólà fún àwọn ìpínlẹ̀
'Saaju ni iroyin ti sọ pe Adegoke lọ si ilu Ile-Ife lati lọ kọ idanwo kan ni Fasiti OAU ni nigba ti ikede rẹ jade pe o di awati lọjọ Keje oṣu Kọkanla nigba ti wọn gbọ pe wọn ko rii ninu kilaasi idanwo lọjọ Kẹfa ti iyawo rẹ ati ẹbi ko si gburo rẹ lori foonu.
Wọn ri oku Adegoke lẹyin igba ti ọwọ Ọlọpaa tẹ awọn afurasi atawọn oṣiṣẹ ile itura naa. Igba to ya ni awọn Ọlọpaa kede pe wọn ti ri oku rẹ.
Iroyin taa tun gbọ ni pe Rahmon Adedoyin yii kan naa ni oludari Fasiti Oduduwa.
Nigba ti Adedoyin n sọrọ ẹwẹ, o sọ lede Yoruba wipe oun n ṣiṣẹ karakara fun owo ati ọrọ oun ni to si n rọ awọn eeyan pe ki wọn sọ oun "lorukọ apaayan tabi afini ṣogun owo".

Ninu ọ̀rọ̀ kika silẹ kan to tẹ awọn oniroyin lọwọ ti ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ sọ pe lootọ ni ọrọ ni oludasilẹ ile itura ọhun n rawọ ẹbẹ si awọn araalu pe ki wọn duro de iwadii awọn Ọlọpaa.
O ni:
"Emi Rahmon Adedoyin ko ki n ṣe apaniyan tabi afini ṣogun owo. Ọlọrun ti baba bukun mi na to ti fun mi lowo latigba ti mo wa lọmọ ọdun mẹ́rindinlọgbọn titi di isinsiyii ti mo ti pe ẹni ọdun marundinlaadọrin bayii".
Adedoyin fi kun un pe oun ko paayan ri laye oun. "Musulumi ododo ni mi. Adegoke gba yara nọmba 305 ni Hilton Hotel. Ile itura to fi orukọ rẹ sil ko kọkọ san owo ni orukọ rẹ sinu asunwọn owo ile itura".
Bakan naa lo ni ko si akọsilẹ pe o san owo si asunwo owo Banki WEMA. "Mi o mọ bi wọ́n ṣe fun un ni yara lai san owo sinu asunwọn owo to jẹ ti ileeṣẹ gangan.
"Igba ti awọn Ọlọpaa bẹrẹ si ni wa Timothy ni wọn ṣẹṣẹ sọ iru nkan bẹẹ fun mi.
Nigba ti awọn Ọlọpaa ṣewadii ti wọn ri oku Timothy nibi ti wọn ju oku rẹ si ti awọn ọga Ọlọpaa yẹ gbogbo ara rẹ wo ti wọn rii pe ko si ẹya ara to sọnu lo wa ye wipe ko sẹni to ran wọn ki wọn yọ ẹya rẹ kankan."
O ni oun n rọ gbogbo eeyan pe ki wọn ni suuru ki wọn jẹ ki awọn ọlọpaa ṣe iṣẹ wọn.
O ṣalaye bo ṣe bẹrẹ kekeke ni Ile-Ife gẹgẹ bii olukọ to n kọ awọn ọmọ nile ko to wa lọ sile iwe giga awọn olukọni ati Fasiti.
"Mi o figba kan kuro ni Ile-Ife ri ki Ọlọrun to bunkun fun mi to sọ mi di olowo. Ọrọ mi mọ. Mi o si na owo ẹjẹ".
Wọ́n ti ń bèrè lọ́wọ́ abúrò ọkọ mi pé èlò ni wọ́n fẹ́ gbà, ẹ ṣàánú wa o! - Ìyàwó Timothy
Lẹyin ti ọwọ awọn agbofinro tẹ awọn afurasi to se iku pa arakurin Timothy Adegoke ni ile itura kan ni ilu Ile ife, awọn idile Adegoke ti kigbe sita pe awon afurasi ti n bere pe elo ni a fẹ gba.
Iroyin ti j ka mọ pe oludasile ile iwe giga fasiti Oduduwa University, Ọmọwe Ramon Adedoyin to si jẹ pe oun naa lo ni ile itura Hilton Hotel ti Timothy ku si.

Iyawo oloogbe, Arabinrin Adegoke Bolatito Victoria, ninu ifọrọwerọ pẹlu ile iṣẹ́ BBC NEWS YORUBA lo fi ẹsun kan afurasi ti Ọlọpaa mu pe awọn kan lọ ba aburo ọkọ oun to maa n pe ni baba ọkọ ti wọn si n gbe igbese lati fun idile awọn ni owo ki wọn le yanju ọ̀rọ̀ naa lai pariwo sita. Amọ BBC Yoruba ko lee fidi eleyii mulẹ.
Ninu itara o ni, "wọn fi owo lọ baba ọkọ mi, ṣe owo le da ọkọ mi pada ni. Ẹyin ijoba ẹ ma wo wa niran, ẹyin ọmọ Naijiria ẹ dide iranlọwọ fun wa o!"
Iyawo Timothy ni awọn o lẹlomiran mọ ni idile Adegoke tori Timothy ni gbogbo awọn gbe ọkan le.
"Oun lo n bọ iya ati baba pẹlu awọn aburo rẹ. Ọmọ mẹta ni a bi fun ara wa, ṣe owo le da oro ti won da idile Adegoke duro? Lẹyin ti wọn pa ọkọ mi ni irinajo ti ko le wale mọ, ẹ gba mi ooo."
Lafikun, Arabinrin Adegoke Bolatito Victoria ni ọ̀rọ̀ naa kii ṣe titẹ oju ọmọ eniyan mọlẹ nikan ṣugbọn pẹlu fifi ọpọlọpọ ọmọ orilẹede si ewu to le mu ẹmi lọ gẹgẹ bi o ṣe mu ẹmi ọkọ rẹ, Arakunrin Timothy Adegoke lọ.

Pẹlu omije ati ibanuje ọkan ni awon obi Timothy Adegoke, Baba Moses ati Mama Bose Adegoke ni awọn n rawọ ẹbẹ si ijọba lati ma jẹ ki iku ọmọ wọn lọ lai si idajọ ododo.
Mama Bose Adegoke ninu ọ̀rọ̀ rẹ ni ọkanlawọn ọmọ ni ọmọ awon jẹ ki iṣẹlẹ yii to ṣẹlẹ, ti iku rẹ si da ọpọlọpọ irinajo ru nitori Timothy ni o n gbọ bukata awọn ati awọn aburo r to fi mọ iyawo ati ọmọ mẹta.

Oríṣun àwòrán, OTHERS

















