Lawan to politicians: Ó yẹ́ kí àwọn olóṣèlú kẹ́kọ̀ọ́ lára Goodluck Jonathan, olófẹ́ ìrẹ́pọ̀ ni

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Aarẹ ile igbimọ aṣofin Ahmed Lawan ti sọ fun awọn oloṣelu Naijiria pe ki wọn lọ kọ lara aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan lori mimu igbelarugẹ ba irẹpọ lorilẹede.
Lawan sọ eyi lọjọ Ẹti nibi ifọrọwerọ kan ti aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan ṣe agbekalẹ rẹ eyi ti akori rẹ jẹ "Ijọba awa ara wa ati irẹpọ ilu".
Aarẹ ile igbimọ aṣofin sọ ninu ọrọ rẹ pe ki awọn adari ninu oṣelu ni ifarajin si wiwa alafia ati irẹpọ lorilẹede.
"Nigba ti awọn adari ba fi aye silẹ fun ifura laarin ara wọn, abajade rẹ ni pe awọn to wa ni igberiko tabi ẹya ti wọn ti wa naa yoo maa huwa bẹẹ́".
Lawan ni Naijiria nilo awọn adari ti yoo mu agbega ba ibaṣepọ to dan mọran laarin gbogbo eeyan.
Bakan naa lo tọka si pe Goodluck Jonathan ti fi ara rẹ han gẹgẹ bi adari to nifẹ si idagbasoke orilẹede.
"A pọ nibi ti a o ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP. Iyẹn fun emi jẹ ijẹri to han gedegbe pe olufẹ irẹpọ ni Goodluck Jonathan". Iwe iroyin NAN ni o sọ bẹẹ.
Bakan naa lo ni awọn gbagbọ pe Jonathan fẹ ire fun orilẹede Naijiria. "Awọn to si gbagbọ ninu eyi naa yoo maa ba ṣe pọ".
"Awọn to n ko ẹgbẹ kilaasi giga ninu oṣelu da bii ki wọn maa ṣe ọmọ iya ni, ko ni fi ṣe ẹgbẹ oṣelu too wa. Ohun to ṣe pataki ni ka tẹsiwaju lati wa ni irẹpọ, maa ṣe aṣepọ ki orilede yii lee dara sii.
Ẹwẹ, nigba ti akọwe ijọba apapọ naa, Boss Mustapha n sọrọ, o ni oun gbagbọ pe iru awọn ọrọ to n waye nibi eto fun ijọba awa ara wa ti Jonathan gbe kalẹ yii, yoo pese awọn ọna tuntun lati koju iṣoro.
Mustapha naa gboriyin fun Goodluck Jonathan fun bo ṣe n mọọmọ ṣe idari tirẹ ati akitiyan lati mu idagbasoke ba ilẹ Afirika.
















