Goodluck Jonathan: Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan ti sọ̀rọ̀ sókè, Ó ní wàhálà Nàìjíríà fẹ̀rẹ̀ gbẹ̀mí ìyá òun lásìkò ìwọ́de 2012

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Naijiria nigbakan ri, Goodluck Jonathan ti ṣalaye pe kii ṣe ọgbẹ diẹ ni aworan posi oun tawon eeyan kan n gbe kiri lasiko iwọde lori epo bentiro to waye lọdun 2012 da sara iya oun.
Aare Jonathan ṣalaye eyi ninu iwe rẹ tuntun to ṣẹṣẹ gbe jade to pe ni "My Transition Hours.".
O ni "Iwode naa n tẹsiwaju. Ninu gbogbo ẹ, eeyan kan ti aanu rẹ ṣemi julọ ni iya mi to wa pẹlu mi ni ile aarẹ nigba naa.
- Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa Saheed Adigun (Adogan) tó kú nílé Sunday Igboho
- "DSS yin ọta ìbọn 48 sí Adogan, kò sì kú, ni wọn bá fi ọmọ odó fọ lórí"
- Sunday Igboho ń dáró èèyàn kejì tí DSS pa nílé rẹ̀
- "Alhaji Fatai, ti DSS pa nílé Sunday Igboho ni kò ríran"
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- DSS kò mú mi lọ́dọ̀ Guru Maharaji, èmi rèé n‘Ibadan, ẹ sinmi àhesọ ọ̀rọ̀ -
Goodluck ni pe : "Ojojumọ lo n rii lori mohunmaworan bi awọn oluwọde ṣe n gbe fọto posi mi kiri ti wọn si n kọ akọle 'sun re o' sii lara."
Aarẹ Jonathan ni ọpọlọpọ eeyan bii Alufaa agba inọ Winners Chapel, Bisọbu Oyedepo, alufa agba ijọ Anglican, Nichola Okoh atawọn mẹjọ miran lo n wa ba oun pe ki oun yi owo ori epo naa pada.
O fi kun un pe ohun to kọ oun lominu ju nipe awọn alatako nilu Eko ti ja iwọde naa gba debi pe wọn tun ko ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ìjọba oun ti ṣalaye bi ọrọ ẹkunwo epo se hẹ mọ abẹ lati b'awọn darapọ mọ iwọde naa.









