Dino Melaye kan sárá sí ààrẹ àná, Jonathan, ó ní irú olóṣèlù rẹ̀ ṣọ̀wọ́n láwújọ

Goodluck Jonathan ati Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye

Gbajugbaja oloselu nni to tun fi igba kan jẹ Sẹnetọ to n ṣoju ipinlẹ Kogi ni ile asofin agba Naijiria ti tọrọ aforiji ni gbangba lọwọ Aarẹ Naijiria ana Goodluck Jonathan.

Ọgbẹni Melaye ni nigba toju ṣokunkun loun fi sọ kobakungbe ọrọ si aarẹ naa ṣugbọn bayi ti oju oun ti la, aforiji loun n wa lọdọ Jonathan.

Lasiko ti wọn n se ifilọlẹ iwe kan ti wọn fi peri Jonathan ni Melaye fi ọrọ yi lede nilu Abuja.

Àkọlé fídíò, Florence Onwuasoanya: Mo jẹ́ àsèjẹ, mo mu àgbo tí kò ṣe e fẹnu sọ kí ń lè gbé ọmọ jó ṣùgbọ

Lara awọn to doju ija kọ ijọba Jonathan ni idibo ọdun 2015 ni Melaye wa to si polongo takuntakun lati tako Aarẹ ana naa ati awọn igbesẹ ti ijọba rẹ gbe paapa julọ nipa aabo ati eto ọrọ aje.

Dino ṣalaye pe lọpọ igba ni igbe aye oun ko dan mọran laarin ọdun marun to kọja yii debi pe oun fẹẹ le gbẹmi ara oun.

''Emi Sẹnẹtọ Dino Melaye mo sọ nitagbangba pe lẹyin ọpọ isẹlẹ ati awọn ohun toju wa ti ri bayi, mo fẹ sọ pe nigba kan loju mi di, ṣugbọn bayi o ti la kedere''

Bẹẹ naa ni Melaye gbosuba kare fun Aarẹ Jonathan fun igbesẹ pipe aarẹ Buhari lori ago lati gba pe oun padanu ibo ọdun 2015.

Awọn eekan Naijiria pẹlu aarẹ Jonathan

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye

Aarẹ Jonatha ati aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

O ni labẹ eleyi ati iwoye iru nkan to n sẹlẹ ni Amẹrika ti aarẹ Donald Trump ko fẹ gba pe oun ti fidirẹmi ninu idibo, o yẹ ka kan saara si Jonathan.

Yatọ si Dino Melaye, awọn eekan miran to wa nibi ifilọlẹ iwe yi ti wọn pe akọle rẹ ni "Dear President Goodluck Jonathan (An Open Letter)," ti akọroyin kan Bonaventure Philips Melah kọ, tunbọ gbosuba kare fun Jonathan.

Lara wọn ni Gomina ipinlẹ Kano to wa ninu ẹgbẹ oselu APC to ni awọn mọ riri eto Almajiri ti aarẹ Jonathan gbe kalẹ lati koju ipenija awọn ọmọ Almajiri ti ko ri ẹkọ to peye gba.

Aarẹ Jonathan ni aarẹ Nigeria akọkọ to pe alatako lati ki i ku orire aseyọri ninu idibo botilẹ jẹ wipe awọn kan sọ pe ijọba rẹ faye gba awọn aisedeede kan bi iwa ajẹbanu ati aidoju ija kọ awọn ikọ Boko Haram bo ti se yẹ.