#EndSARS: Amẹrika ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ìwàdìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìwọ́de #EndSARS ní Lekki toll gate

Protesters at Lekki Gate

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Amẹrika ti ni oun n reti esi ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Eko lori abọ igbimọ to ṣe iwadii lori iwọde #EndSARS nibi tawọn eeyan ti sọ pe awọn ọlọpaa ati sọja pa awọn oluwọde ni Lekki toll gate niluu Eko ni ogunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.

Igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹjọ ti adajọ to ti fẹyinti, Doris Okuwobi, fi abọ iwadii rẹ ṣọwọ si ijọba nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe awọn sọja ati ọlọpaa yinbọn pa awọn eeyan to n ṣe ifẹhonuhan wọọrọwọ ni Lekki toll gate.

Igbimọ naa sọ ninu abọ rẹ to fi sita pe o kere tan eeyan mẹsan an ni wọn ṣekupa nini iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀dọ́ opó l'obìnrin sọ ìrírí wọn l'awùjọ

Eeyan mejelaadọta ni igbimọ ọhun sọ pe wọn farapa ninu eyi ti mejilelogun fara gba ọta ibọn nigba ti awọn sọja ati ọlọpaa ṣe ikọlu sawọn mẹẹdogun.

Victor Sunday Ibanga, Abuta Solomon, Jide, Olalekan Abideen Ashafa, Olamilekan Ajasa, Kolade Salami, Folorunsho Olabisi, Kenechukwu Ugoh, ati Nathaniel Solomon ni orukọ awọn ti wọn lo gbẹmi mi nibi iṣẹlẹ naa.

Igbimọ ọhun tun sọ pe Abiodun Adesanya, Ifeanyi Nicholas Eji, ati Tola ati Wisdom naa ṣagbako iku nibi iṣẹlẹ naa.

Amọ, akọwe ijọba orilẹede Amẹrika to n ri si ọrọ ile okeere, Anthony Blinken, sọ lasiko ipade rẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ilẹ Amẹrika n reti igbesẹ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ Eko lori abajade igbimọ oluwadii to fi esi rẹ ṣọwọ si ijọba.

Blinken sọ fun Buhari pe ki ijọba gba ọrọ awọn ẹbi awọn eeyan to ku tabi farapa ninu iṣẹlẹ ọhun ro.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Itunu Babalọla Death: Ìjọba Nàíjìríà fèsì sí ìbéèrè Baba Itunu Babalola lórí òkú ọmọ rẹ̀!

Abọ iwadii naa tun fidi rẹ mulẹ pe eeyan mọkalelaadọta lo ku lapapọ lasiko iwọde EndSARS nipinlẹ Eko.

Igbimọ naa sọ pe ara oku awọn eeyan yi ni oku mọkandinlọgọrun ti wọn pin kaakiri ile iwosan niluu Eko.

Ṣugbọn agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Eko, Abiodun Owonikoko (SAN), ni kudiẹ kudiẹ wa ninu abọ igbimọ oluwadii to fi ṣọwọ si ijọba.

O ni kudiẹ kudiẹ bi ogoji lo wa ninu abọ igbimọ naa ati pe o lodi bi igbimọ ọhun ti jẹ ki abọ iwadii rẹ han sita si gbogbo eeyan.