Àwọn ọ̀dọ́ opó l'obìnrin sọ ìrírí wọn l'awùjọ àti irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti gbomijé lójú wọn lẹ́yìn ikú ọkọ wọn
Arábìnrin Lydia Davies to jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdílógójì ṣàlàyé pé lẹ́yìn ọsẹ̀ kan ti tí òun bi ọmọ keji ni ọkọ oun kú.
Arábìnrin Davies ni osù mẹ́sàn-án gbáko lo fi dùbúlẹ̀ ní ilé ìwòsàn ti ó si jẹ irora gidi ki o tó papodà.
Bakan náà ni opó kejì tó ti wọn ipò yìí láti ìgbà tí o ti gbé ẹnu le ọgbọ̀n ọdún, ó ṣàlàyé pé, ẹnu iṣẹ́ ni ọkọ òun ti pàdé ikú tirẹ gẹ́gẹ́ bi jórínjórin.
Àwọn méjèèjì ṣàlàyé bi nǹkan ko ṣe rọgbọ fún àwọn mẹ́jèèjì láti àsìkò náà.
Ní ti Davies to pári ẹkọ́ fásíti, ó ṣàlàyé pé, iṣẹ́ olùkọ tí òun ń ṣe, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndílógún ni owó oṣù pẹ̀lú ọmọ méjì lọ́wọ́.
Ní ti arábinrin Ojo Bolanle ó ni láti ìgbà ti ọkọ òun ti kú ni òun ti ni òun kò ṣetán láti fẹ́ ọùnrin mííràn ńitorí òun ti ni ọmọ méjì sílẹ̀.
Ó ní iṣẹ́ bíbá àwọn ènìyàn tójú ilé ni òun ṣe, àti pé ni ọ̀ps ìgbà àwọn ènìyàn wọnyi náà ló má náwọ ìrànwọ́ sí òun.
Sùgbọ́n ní àsìkò yìì, aláfíà rẹ ko ṣe dáradára mọ́ tí kò sì sí ọ̀nà àti àti jẹ àti mu mọ́.
Ilé iṣk ẹlẹyinju àànú kan ti ko lọ́wọ́ ìjọba nínú èyí ti arábìnrín Queen Abosede ń dari, ṣàlàyé pé, ó ṣe pàtàkì láti máá bójú tó àwọn opó àti àwọn tó ku díẹ̀ káàtó fún ni àwùjọ.
Ó ni nǹkn ti ojú opó n rí kìí ṣe kèrémi ńitorí náà ó ṣe pàtàkì láti máa náwọ́ oore sí wọn.



