Ṣé ìrẹsì tó ti lo ọdún mẹ́wàá ní ìpamọ́ le fa ìpalára fún ẹni tó bá jẹ́ ẹ?

Oríṣun àwòrán, THAILAND MINISTRY OF COMMERCE
- Author, Onur Erem
- Role, BBC World Service
Laipẹ yii ni ijọba Thailand gbe irẹsi toto ẹgbẹrun mẹdogun tọọnu to ti kọja ọdun mẹwaa sita fun tita.
Eyi kii ṣe iṣẹlẹ lojoojumọ, nitori naa kilode ti wọn fi gbe igbesẹ naa? Orile-ede naa ti ni irẹsi ni ipamọ fun o kere ọdun mẹwaa lẹyin ti ijọba ti ra lati ọdọ awọn agbẹ fun iye to ju owo rẹ lọ ninu ọja lasiko eto kan ti ijọba gbe kalẹ.
Eto yii, ti Olootu ijọba nigba kan ri, Yingluck Shinawatra ṣe ifilọlẹ ni ọdun 2011, rii pe orilẹ-ede naa ra irẹsi milọnu mẹrinlaadọta tọọnu 54,000 lati ọwọ awọn agbẹ, eyi ti wọn ṣapejuwe ọrọ oṣelu
Ijọba san ọpọ owo toto 900bn baht (o fẹ to $24bn) lati se onigbọwọ rẹ - ti ọpọ owo naa lo si jẹ yiya.
Ṣugbọn eto naa jẹ eyi ti ko ṣe aṣeyọri. Ijọba ko ri irẹsi naa ta ni owo gbọọbi- eyi to jẹ ki irẹsi naa wa ni akata ijọba.
Ni oṣu to kọja, Minisita okowo Thailand, Phumtham Wechayachai sọ pe wọn ti ṣeto igbimọ kan lati ṣakoso tita iresi naa.
Ni ọjọ kẹtadinlogun, Oṣu Kẹfa, ile-iṣẹ Thai kan ti orukọ rẹ n jẹ V8 Intertrading Co Ltd bori ;lati ra irẹsi naa pẹlu apapọ owo to jẹ 286m baht.
Ẹ jẹ ki a wo ohun ti o ṣẹlẹ si iresi nigbati o ti fipamọ fun ọdun mẹwaa, ati nibi ti iresi Thailand le pari si.
Ki lo sẹlẹ lẹyin eto ti ijọba gbe kalẹ lori irẹsi?
Bi o ti lẹ jẹ pe o jẹ ọkan ninu awọn olutaja iresi lagbaye, ijọba Thai ko le ta irẹsi naa fun owo ti wọn ra tẹlẹ, ti wọn si padanu owo toto $15bn, gẹgẹ bii ẹkọ ile-iṣẹ Isuna Thai ṣe gbe sita.
Lẹyin ọpọ ifẹhonuhan ni ọdun 2014, Olootu ijọba, Yingluck Shinawatra ni wọn yọ kuro ni ijọba lẹtin ti iditẹgbajọba ologun kan waye. Lẹyin naa lo foju ba ile ẹjọ ni ọdun 2017 fun ohun ti ijọba padanu , ti ile ẹjọ si ni o jẹbi ẹsun aibikita.
Ki oṣuwọn irẹsi naa?

Oríṣun àwòrán, THAILAND MINISTRY OF COMMERCE
Ni oṣu to kọja, Ọgbẹni Phumtham jẹ irẹsi ni iwaju awọn akọroyin ni igbiyanju lati jẹri si aabo ati dida rẹ.
“Awọn irugbin irẹsi naa tun lẹwa. Awọn awọ le jẹ ofeefee. Eyi ni ohun ti irẹsi ọdun mẹwaa dabi, ”o sọ, ṣaaju ki o to koju awọn akọroyin pe ki wọn fi ọbẹ ja apo irẹsi eyikeyi, ki wọn ṣayẹwo didara rẹ.
Ile-iṣẹ iṣowo ti Thai ṣe ayẹwo iresi naa ni ile ayẹwo to jẹ ti ile-iṣẹ ilera, ti wọn si pin awọn abajade rẹ fun awọn akọroyin.
Wọn sọ pe ayewo wọn ko rii awọn kẹmika bii aflatoxin, deoxynivalenol, ion bromide, oxide ethylene tabi awọn kemikali majele miiran.
Ile ayẹwo naa tun ṣayẹwo bi irẹsi se sara loore to, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe ko yatọ si eyi to wa lọja bayii ti wọn n ta.
Ikanni Channel 3, ikanni ileeṣẹ momaworan Thai, ṣe ayẹwo miiran ni ile ayẹwo olominira, ti wọn si pẹlu ijọba lati sọ pe ko si ohun to lewu ninu irẹsi lati jẹ.
BBC ko ti fidi awọn ayẹwo ti ijọba tabi ti awọn ile ayẹwo aladani se lori irẹsi naa mulẹ.
N jẹ se irẹsi ma n bajẹ?
Gẹgẹ bii ohun ẹka Ounje ati Iṣẹ-ogbin ti ajọ UN (FAO) sọ, irẹsi le wa ni ipamọ labẹ awọn ipo kan - ni aye gbigbẹ ati aye ti ko gbona ju, to ni afẹfẹ, fun apẹẹrẹ - fun awọn akoko gigun.
Bakan naa, ajọ to n risi irẹsi ni US sọ pe irẹsi le wa fun igba pipẹ ti wọn fi pamọ daada.
N jẹ irẹsi ma padanu awọn aṣe ara loore? Ati pe ki lo ma waye si nawọn kokoro?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
BBC beere lọwọ FAO boya ọdun mẹwaa le ni awọn majeje tabi fa eewu majele, wọn si sọ fun wa
pe nigba to jẹ wipe wọn tẹle gbogbo itọnisọna, ko yẹ ki o jẹ eewu fun ilera.
A tun beere boya irẹsi naa le padanu awọn eroja to n se ara loore lẹyin ọdun mẹwaa.
FAO sọ pe awọn eroja fatami le kere ninu awọn irẹsi yii ṣugbọn ko ki n se ohun to le fa
“Ọkan ninu awọn eroja to se ara loore ninu irẹsi ni sitashi, eyi to le wa fun agbara,” FAO sọ.
“Eroja sitashi ni ireti wa pe ko le yipada ni akoko ti wọn fi pamọ ati ti yoo si tun le sisẹ rẹ.”
N jẹ se irẹsi naa le yatọ lẹnu?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
FAO sọ pe gbogbo irẹsi lo ma n padanu adun wọn ti wọn ba ti fi pamọ fun akoko kan sugbọn igba ti yoo waye da lori bi wọn ba ṣe fi pamọ.
Sọrọsọrọ momaworan, Sorayuth Suthassanachinda ṣe itọwo irẹsi jasmine to wa lai ọdun mẹwaa ti ko si iyatọ ninu adun rẹ ati awọn irẹsi funfun lo wa lọja.
Ki yoo gbẹyin irẹsi naa
Ni ọdun to kọja, awọn ilu to ra irẹsi Thai jẹ Indonesia ati South Africa, ni ibamu nnkan ti Ẹgbẹ to n fisi irẹsi ranṣẹ si oke okun ni Thai.
Pairot Wangdee, lati ile-iṣẹ kan ni Thailand, sọ fun BBC pe: “Pupọ awọn eniyan ti o jẹ irẹsi atijọ wa ni awọn orilẹ-ede ni wọn ko lowo.”
Yato si South Africa, Thailand tun ti ta irẹsi si ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede Afirika miiran.
Ọgbẹni Phumtham tun sọ pe ni awọn n gba ipe fun irẹsi tita lati Afirika.
Lati igba ti ijọba Thai ti kede tita, awọn eeyan lori ayelujara ni Afirika ti n fi ohun sita lori ohun ti wọn ro bii: “Gẹgẹ bii o ṣe ma ri , Afirika ni wọn yoo ju gbogbo rẹ si” ati “Afirika, ile si awọn orilẹede mii ko tẹwọgba”.
Ijọba Kenya ti sọ pe awọn yoo faye gba irẹsi naa lorilẹede naa.
Ile-iṣẹ ti o bori ni lati ra irẹsi naa, V8 Intertrading, ni gbedeke ọgbọn ọjọ lati fowo si iwe adehun lati pari rira naa.
Ko ti sọ awọn orilẹ-ede wọn pinnu lati ta irẹsi naa si.












