Àrùn Lasa àti kọ́lẹ́rà mú ẹ̀mí èèyàn 202 lọ ní Naijiria láàrín oṣù mẹ́fà – NCDC

Oríṣun àwòrán, Getty images
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC, ti kede pe ko din ni eeyan mejilenigba to ti jade laye lẹyin ti wọn lugbadin arun kọlẹra ati Lasa laarin ọsu mẹfa sẹyin.
NCDC lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede.
O ni eeyan 6,704 lo ni iba Lasa ni ijọba ibilẹ 125, ti eeyan 162 si jade laye ni ipinlẹ 28 lati ọwọ arun naa.
Nigba ti kọlẹra to ṣẹṣẹ bẹ silẹ laipẹ yii ti mu ẹmi eeyan 40 lọ.
Gẹgẹ bii nnkan ti NCDC sọ, bi Lasa ṣ n gbẹmi eeyan ti le si lati ida 17.1% si ida 17.8%.
O sọ siwaju si pe ipinlẹ Ondo, Edo, ati Bauchi ni ida 65% awọn to ni Lasa ti wa ni Naijiria nigba ti ida 35% to ku wa lati awọn ipinlẹ marundinlọgbọn mii.
Ninu ida 65% awọn to ni Lasani Naijiria, 25% ninu wọn lo wa lati ipinlẹ Ondo, 22% wa lati Edo, ti ida 18% si waye nipinlẹ Bauchi.
Ajọ naa ṣalaye pe awọn ọdọ lo pọ ju ninu awọn to n lugbadi Lasa.
O ni “ọjọ ori awọn to n ni arun naa jẹ lati ọdun mọkanlelogun si ọgbọn ọdun.”
Ẹwẹ, adari NCDC, dokita Jide Idris ti sọ pe awọn ko ni abẹrẹ ajẹsara to to lati koju arun kọlẹra.
Amọ o fi kun pe awọn ti bere abẹrẹ naa lọwọ awọn ajọ to n pin lọfẹẹ lati oke okun bo tilẹ jẹ pe ajọ naa ko mọ igba ti abẹrẹ ọhun yoo wọlesi Naijiria.













