Wo nǹkan mímu tí ìjọba ló ṣokùnfa àrùn Kọ́lẹ́rà n'íjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa l’Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Eko ti ṣawari ohun to fa arun onigbemeji to bẹ silẹ nipinlẹ Eko bayii.
Ijọba ibilẹ Lagos Island, Eti-Osa ati Kosofe ni arun naa ti gbilẹ julọ lati igba ti o ti bẹ bẹ silẹ nipinlẹ Eko.
Akọsilẹ fihan pe eeyan mẹrinlelogun ni arun naa ti pa nipinlẹ Eko nigba ti eeyan marundinlogoji ti ni arun ọhun.
Ijọba ibilẹ Eti Osa ni akọsilẹ fihan pe ibẹ ni awọn to larun naa ti pọ julọ nipinlẹ Eko.
Oludamọran pataki si gomina Babajide Sanwo-Olu, Dokita Kemi Ogunyemi, ṣalaye ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch pe ijọba ṣe iṣẹ iwadii ni ijọba ibilẹ Eti-Osa lẹyin ti akọsilẹ fihan pe nibẹ ni arun naa ti gbilẹ julọ.
Dokita Ogunyemi ṣalaye pe iwadii ijọba fihan ọti ẹlẹrindodo ‘’tiger nut’’ lo jẹyọ ninu iwadii ọhun.
O ṣalaye wi pe gbogbo awọn ti wọn gbe wa sile iwosan fun itọju arun kọlẹra lo sọ pe ‘’tiger nut’’ lawọn mu.
Oludamọran gomina ipinlẹ Eko fikun ọrọ rẹ pe awọn to ṣe nnkan mimu ẹlẹrindodo yii ko forukọ rẹ silẹ pẹlu ajọ NAFDAC to n ṣakoso ọrọ ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria.
‘’Bayii ni a bẹrẹ si ni wa nnkan mimu ‘’tiger nut’’ kaakiri ni ijọba ibilẹ Eti Osa lati ṣe ayẹwo lori rẹ.
A ri awọn igo ti wọn fi n ta nnkan mimu yii, amọ ko si nọmba ajọ NAFDAC lara rẹ.
A beere lọwọ awọn to ra nnkan mimu yii wi pe nibo ni wọn ra a, amọ, a ko ri igo ti ‘’tiger nut’’ si kun inu rẹ.
A pe nọmba ti wọn kọ sara igo ti a ri, ṣugbọn nọmba ọhun ko lọ.
Nigba ti a ṣe ayẹwo igbẹ awọn eeyan to wa nile iwosan ni a ri pe wọn ti lugbadi arun kọlẹra.













