Àwọn onítíátà Yorùbá kò yọjú síbi ìsìnkú Sule Suebebe, ọmọ rẹ̀ ní ìyá òun kọ òun lọ́mọ fún wíwá síbi ìsìnkú bàbá rẹ̀
Bi awọn eeyan ṣe n sọrọ nipa iwa ati ipapoda agba oṣere, Dayo Adewumi, (Sule Suebebe), akọbi rẹ, Wale Adewumi, naa ti sọ ohun ti iku baba rẹ mu ba a.
Nibi isinku Suebebe to waye n’Ibadan, lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ọdun 2024 yii ni Wale ti ṣalaye pe iya oun ti kọ oun lọmọ nitori ibi oku baba toun yọju si.
‘’Nnkan ti mo n ṣe yii, ko yẹ ki n ṣe e. Iya mi ko fẹ ki n wa sibi oku baba mi.
Nitori mo wa sibi oku baba mi yii, iya mi kọ mi lọmọ. Ṣugbọn emi naa fẹ ki ọmọ rere gbeyin mi ni mo ṣe wa, emi ati baba mi ko ja, ko si si aawọ kan laarin wa.
Ọrẹ timọtimọ ni wa ki wọn too ku, inu mi si dun pẹlu ipejọpọ oni yii ti awọn eeyan waa ṣe fun wọn"
Bẹẹ ni Wale, akọbi Oloogbe Sule Suebebe wi.
O dupẹ fun aduroti ati ifẹ ti awọn ẹbi Oloogbe ni si i ti wọn fi wa.
Ẹbi ara, ọrẹ sin Sule Suebebe de ile ikẹyin

Oríṣun àwòrán, BBC
Gbajugbaja oṣere tiata Dayo Adewumi ti ọpọ eeyan mo si Sule Suebebe ni awọn ati ẹbi rẹ gbe wọ kaa ilẹ loni nile rẹ to wa ni agbegbe Egbeda nilu ilu Ibadan.
Ninu iwaasu rẹ pasitọ Makinde Abiodun rọ awọn eeyan to wa nibi isinku ọhun lati wu iwa rere ki ọpọ le ranti wọn si rere, nigbati ohun lo apẹẹrẹ Thabita inu Bibeli, Makinde rọ awọn eeyan lati fi iṣe rere lele ki wọn to jade laye.
Lara awọn oṣere tiatia to peju sibi eto isinku naa ni Mustafa Bakare tí ọpọ mo si Otolo, ninu ọrọ ikẹdun rẹ o jẹri si ise dada Dayo Adewumi, oni botile jẹ wi pe oloogbe naa ni kudie kudie kọkan sugbọn ko to papọda o tọrọ fun idarinjin awọn
O rọ awọn ẹbi ati idile ologbe Dayo Adewumi lati wa ni isokan lẹyin iku Dayo Adewumi ti ọpọ eeyan mo si Sule Suebebe.
Àwọn onítíátà kò yọjú síbi ìsìnkú Sule Suebebe

Iyalẹnu lo jẹ, pe bi Oloogbe Dayọ Adewumi ṣe jẹ agba oṣere to, awọn onitiata ẹgbẹ rẹ ko yọju sibi eto isinku rẹ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.
Ṣe igbagbọ ọpọ eeyan ni pe ẹsẹ ko ni i gba ero nibi isinku naa pẹlu bo ṣe jẹ pe agba oṣere ni Suebebe nigba aye rẹ. To si ti ba awọn eeyan nla lagbo oṣere ṣiṣẹ pọ daadaa.
Ati pe awọn onitiata ẹgbẹ rẹ yoo wa sibẹ, wọn yoo ṣeto ẹyẹ ikẹyin to yẹ fun un ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ rara.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi eto naa woye pe Alagba Mustafa Bakry tawọn eeyan mọ si Otolo, nikan ni elere ori itage to wa sibi isinku naa.
Ninu ọrọ ikẹdun rẹ o jẹri si ise dada Dayo Adewumi, oni botile jẹ wi pe oloogbe naa ni kudie kudie kọkan sugbọn ko to papọda o tọrọ fun idariji awọn to ṣẹ.
O rọ awọn ẹbi ati idile ologbe Dayo Adewumi lati wa ni isokan lẹyin iku rẹ.
Ohun to ṣẹlẹ yii lo mu awọn eeyan maa beere pe ṣe Suebebe ko ba ẹgbẹ onitiata kankan ṣe ni, abi ki lo ṣẹlẹ ti ko fi si aṣoju kankan lati ọdọ wọn.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun yii ni sule Suebebe jade laye lẹyin aisan kan ti n ba finra fun ọjọ pipẹ.
Òní ni ètò ìsìnkú Sule Suebebe yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod
Oni, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 ni wọn yoo sin oku gbajugbaja oṣere tiata Yoruba to doloogbe, Dayo Adewumi, ti ọpọ mọ si Sule Suebebe.
Ile ijọsin Agbala Gabriel to wa niluu Ibadan ni eto isinku naa yoo ti waye.
Ikede eto isinku naa lo waye ninu atẹjade kan ti awọn mọlẹbi rẹ fi lede lọsẹ to kọja.
Akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ tiata, Kunle Afod naa tun kede eto isinkun ọhun loju opo Instagram rẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun yii ni sule Suebebe jade laye lẹyin aisan kan ti n ba finra fun ọjọ pipẹ.
Lẹyin iku rẹ ọhun ni pasitọ Ademola Amusan, ti ọpọ mọ si Agbala Gabriel kede rẹ.
Ṣaaju iku Suebebe ni Agbala Gabriel ti kọkọ n ṣetọju rẹ to si gbiyanju lati gbe iranlọwọ dide fun un.
Ki Suebe to ku lo ti sọ ninu fidio kan pe oun gbe igbeaye agbere nigba ewe, ti oun si ti ṣẹ ọpọ obinrin.
Oloogbe naa jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣere to gbe tiata Yoruba laruge nilẹ Yoruba ati ni Naijria.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni Suebebe ki ọlọjọ to de.















