Ọmọ gbajúmọ̀ òṣèré, Sule Suebebe ṣàlàyé ohun tó fa aáwọ láàrín èèkàn eléré tíátà náà àtàwọn ẹbí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Lọjọ ti alaro ba ku la maa n mọ iye aṣọ to rẹ. Bẹẹ naa lo si ṣe jẹ pe iku ni nnkan pataki to maa n saaba tu aṣiri ikọkọ ẹda bi wọn ba lọ tan.
Eyi lohun to n ṣẹlẹ bayii lẹyin ipapoda agba oṣẹre, Dayọ Adewumi tawọn eeyan n pe ni Sule Suebebe.
Idi ni pe awọn aṣiri ti ẹnikẹni ko mọ tẹlẹ nipa baba naa lo n jade bayii.
Ọkan ninu awọn ọmọ Suebebe, Olufẹmi Adewumi to ba BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye pe ọdun 1998, iyẹn ọdun kẹrindinlọgbọn sẹyin loun ti fi oju kan baba oun gbẹyin koun too ri oku rẹ lọsẹ to kọja, niluu Ibadan.
Olufẹmi sọ pe ẹni ti ko ba gbọ ti ẹnu ẹga ni yoo sọ pe ẹga n paato, o loun ki i ṣe ọmọkọmọ, ohun to ṣẹlẹ loun n wi.
O ṣalaye bi agidi ọkan ṣe pọ fun Oloogbe Adewumi ti i ṣe baba rẹ, bi baba ṣe bi awọn lọmọ lọpọ yanturu ti awọn ko mọ ara awọn tan, bi ko ṣe bikita boya awọn kawe ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Alaye Olufẹmi Adewumi, ọmọ kẹta ninu awọn ọmọ Suebebe, gẹgẹ bo ṣe sọ ọ fun wa ree.
''Bí mo bá wo ìwà bàbá mi ni, mi ò ní í yọjú sí òkú wọn pàápàá''
''Emi o fẹẹ fi ori mi gba ègún, mi o dẹ fẹẹ ti ara baba mi ṣẹ Ọlọrun ni mo ṣe yọju s'Ibadan lati ri oku wọn lọsẹ to kọja.
Ti mo ba ro iwa wọn ni, mi o ni i fi ile mi silẹ lai ri ọmọ pẹlu iyawo mi fun ọjọ mẹrin.
''Ọlọrun kan kọ ọ pe mo maa ti ara wọn waye ni, 'one naira' wọn ko si ninu owo ti mo fi kawe, wọn o mọ bi mo ṣe kawe rara. Mi o ba ma le sọrọ lawujọ lonii to ba jẹ mi o tun ara mi bi ki n wa ọna lati kawe ni.
''Ki i ṣe emi nikan ni wọn ṣe bẹẹ fun o, gbogbo awọn ẹgbọn ti mo ba niwaju, bi wọn ṣe ṣe fun wọn niyẹn.
''Wọn bi wa ti a pọ, a ko mọ ara wa tan ba a ṣe wa yii. Wọn o dẹ beere wa.
''Ọdun 1998 ni mo ti foju mi kan wọn gbẹyin, wọn o mọ ẹyọkan bayii ninu awọn ọmọ mi ti mo bi.
''Ki i ṣe pe mi o fẹẹ ri wọn o, mo gbiyanju lati ri wọn daadaa, wọn ni ki n ma wa ni.
Ki lo si fa a to fi di pe a n ja, mo ba wọn sọ ootọ ọrọ ni.
''Mo ni ki wọn jẹ ki gbogbo awa ọmọ wọn kora pọ, ka waa ṣe adura fun wọn, ka sure fun wọn ki gbogbo ogun aye wọn ṣẹ, ṣugbọn wọn o gba. Ọlọkan lile ni wọn,agidi ọkan pọ fun wọn.
''Nitori ẹ lo ṣe ya mi lẹnu nigba to ku ọjọ meji ti wọn maa ku ti wọn waa pe mi lori foonu pe ki n wa.
''Ki i ṣe pe mo pa wọn ti, emi ni mo mọ iye owo ti mo fi ranṣẹ si wọn ni gbogbo igba ti ara wọn ko fi ya yẹn. Mi o dẹ fun mama mi lowo, ti mama mi gan-an ba gbọ pe baba ti ko tọju mi ni mo fun lowo, wọn maa gbe mi ṣepe ni.
''Ko sibi ti mo de, awọn eeyan aa maa sọ fun mi pe emi ni mo jọ baba mi ju, pe 'Carbon copy'' ẹ ni mi. Ẹ ma jẹ n parọ fun yin, mi o ro bẹẹ nitemi. Ohun ti mo n sọ fun yin nipa wọn yii, ẹdun ọkan mi ni.
''Nibi aye de duro lonii, obi ti ko ba tọju ọmọ, ko le jere ọmọ, ootọ ibẹ niyẹn.
''Emi n ṣe iwọn ti mo le ṣe fun idile mi, bo tiẹ jẹ pe ṣọọbu ẹlomi-in ni mo ti n ṣiṣẹ, sibẹ, mo n ṣetọju idile mi bo ṣe yẹ.''
Mọ̀lẹ́bí sọ̀rọ̀ lórí ìròyin tó tàn kálẹ̀ pé ẹbí Suebebe kọ̀ láti gba òkú rẹ̀ lọ́wọ́ Pásítọ̀ Agbala Gabriel

Oríṣun àwòrán, Others
Olufemi Adewunmi, ọkan lara awọn ọmọkunrin, oloogbe Dayo Adewunmi, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Sule Suebebe ti ba BBC Yoruba sọrọ lori iroyin kan to tan ka ori ayelujara wi pe mọlẹbi kọ lati tẹwọ gba oku oṣere naa lọwọ Pasitọ Ademola Amuṣan ti ọpọ mọ si Agbala Gabriel.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Aje, Olufemi fidi rẹ mulẹ pe iroyin ofege lawọn eeyan kan n gbe kaakiri pe ẹbi ko gba oku Suebebe lọwọ Agbala Gabriel.
Olufemi ni oku baba wọn ṣi wa ni mọṣuari nile iwosan niluu Ibadan.
‘’A fi oku baba silẹ si mọṣuari ni ki a fi ṣe eto isinku wọn tan, ko si ẹbi kankan to kọ lati gba oku lọwọ Agbala Gabriel.
Oku gbajumọ ni oku baba wa, kii ṣe oku ti a kan le sare ṣin bayẹn.’’
Olufemi to jẹ akọbi kẹta fun oloogbe ni ẹbi ti ṣetan lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun agba oṣere naa to doloogbe.
Nibo ati nigba wo ni eto isinku Sule Suebebe yoo waye?
Ẹbi oloogbe Adewunmi ti kede pe eto eto isinku agba osere Suebebe yoo waye ni ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun osu kẹfa yii.
Ọgbẹni Adewunmi tun fidi rẹ mulẹ pe ile ti awọn eeyan dawo jọ kọ nipasẹ Agbala Gabriel niluu Ibadan ni awọn ọmọ yoo sin baba Suebebe si.
‘’Ni ọjọ Aiku ni awọn ẹbi jokoo pẹlu pasitọ Agbala Gabriel lati sọrọ nipa eto isinku naa.
Nibi ipade yii ni a ti bi Agbala gabriel pe kinni nnkan ti a le ṣe gẹgẹ bi awa ọmọ oloogbe nibi eto isinku naa.
Agbala Gabriel sọ fun wa pe ki a maa ṣe iyọnu, amọ, awọn nnkan kan wa to maa jẹ ojuti fun eeyan.
Fun bi apẹẹrẹ, ẹtọ awa ọmọ ni lati ra posi ti a maa gbe baba wa si ati lati gbe ilẹ ti wọn yoo sin baba si.
Nibi ipade yii ni a ti fẹnuko pe a maa ṣe oku baba wa ni ọjọ Ẹti ki gbogbo rẹ kuro nilẹ.
Ti a ba wa ri ọkan ninu awọn ọmọ to ba fẹ ṣe oku alarinrin fun baba to ba ya, a ko binu si i.
Ṣugbọn awa fẹ bo aṣiri oku lọjọ Ẹti.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni oloogbe Adewunmi ki ọlọjọ to de.















