Èèyàn mọ́kànlá kú, 66 di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi méjì rì lọ́jọ́ kan náà

Shipreck

Oríṣun àwòrán, epa

O kere tan, eeyan mọkanla ti jade laye, ti awọn to le ni ọgọta si ti di awati lẹyin ti ọkọ oju omi meji ri ni ila oorun orilẹede Italy.

Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, RESQSHIP sọ pe oun ti yọ eeyan mọkanlelaadọta ninu ọkọ oju omi to n ri, ninu eyii ti wọn ti ri eeyan mẹwaa to ti ku sinu rẹ ni erekusu Lampedusa.

Ninu iṣẹlẹ miran lọjọ kan naa, ajọ Médecins Sans Frontières (MSF) ni eeyan to le ni ọgọta lo di awati nigba ti awọn mẹrindinlọgbọn mii ti wọn jẹ ọmọde, ni igbagbọ wa pe wọn ti ku.

Ajọ UN sọ pe awọn aṣatipo to n rinrinajo lati Libya ati Turkey ni ọrọ naa kan.

Ajọ RESQSHIP ni wọn ti fa awọn ti ori ko yọ le ijọba Italy lọwọ.

Apapọ ajọ UNHCR, UNICEF ati IOM sọ pe orilẹede Libya ni ọkọ oju omi naa ti gbera, eyii to gbe awọn aṣatipo lati Syria, Egypt, Pakistan ati Bangladesh.

Ọkan lara awọn mejila kan ti ori kọkọ ko yọ ku lẹyin to de Italy tan.

Agbẹnusọ MSF, Shakilla Mohammadi sọ pe oun gbọ pe awọn eeyan 66 ni wọn ṣi n wa, lara wọn ni ọmọde 26 wa ti ninu wọn ko tii to ọmọ ọdun kan.

O ni “odidi idile kan to wa lati Afghanistan ni igbagbọ wa pe wọn ti parun.

“Wọn kuro ni Turkey lọjọ mẹjọ sẹyin, wọn si ti mu omi yo fun nnkan bii ọjọ mẹta si mẹrin, wọn sọ fun wa pe wọn ko ni aṣọ adoola ẹmi, bẹẹ lawon ọkọ oju omi kan to ri wọn nibi ti wọn ri si kọ lati ran wọn lọwọ.”

Okun Mediterranean jẹ ọkan gboogi lara oju ọna awọn aṣatipo ati ogunlende maa gba lọ silẹ Yuroopu, beẹ ni ọpọ awọn to n gba ori okun naa ṣi maa n ku.

O le ni 23,500 aṣatipo to ti ku tabi to ti di awati lori omi naa lati ọdun 2014, gẹgẹ bii ohun ti ajọ UN sọ.