Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nipa àrùn Onígbá-méjì tó ti pa èèyàn ọgbọ̀n ní Nàìjíríà àti bí o ṣe lè dènà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty image
Arun onigba-meji ti a mọ si Kọ́lẹ́rà ti pa eeyan ọgbọn (30) ni Naijiria bayii, gẹgẹ bi ẹka to n ri si didena arun lorilẹ-ede yii ṣe sọ.
Kọlẹra to maa n mu eeyan nipasẹ ounjé tabi omi ẹlẹgbin maa n fa igbọnsẹ gbuuru, eebi ati ki omi ara gbẹ pata.
Ajọ NCDC to n ri si didena arun sọ pe arun onigba-meji yii ti de ipinlẹ ọgbọn (30) ninu ipinlẹ mẹrindinlogoji (36) ti Naijiria ni.
Wọn ni o si ti kan ijọba ibilẹ mẹrindinlọgọrun-un (96).
Koda, nipinlẹ Eko to jẹ ibusọ aje Naijiria, eeyan mẹẹẹdogun (15) lo ti ku latari arun yii.
Eeyan mẹtadinlogun mi-in ni akọsilẹ si tun wa pe Kọlẹra ti mu niluu naa.
Bakan naa ni wọn ni apẹẹrẹ tun foju han, pe eeyan irinwo din laaadọta (350) ni arun yii tun ti fọwọ ba.
Àwọn ibi tí àrùn onígbá-méjì kò tí ì dé ní Nàíjíríà kò tó ǹnkan
Bi akọsilẹ awọn eleto ilera ṣe wi, awọn ibi ti arun onigba-meji ko ti i de ni Naijriia lasiko yii ko to nnkan.
Ni Naijiria, kọlẹra jẹ ọkan lara awọn arun to maa n ṣẹlẹ latigba degba, paapaa julọ lasiko ojo. Eyi maa n ri bẹẹ lawọn ibi ti imọtoto ba ti mẹhẹ.
Itan sọ pe ajakalẹ arun onigba-meji akọkọ bẹ silẹ ni Naijiria laarin ọdun 1970 si 1990.
Awọn eyi to lagbara mi-in tun waye ni 1992, 1995-1996 ati 1997.
Laaarin oṣu kinni, ọdun 2010 si oṣu kẹwaa, eeyan 1,434 ni ileeṣẹ eleto ilera kede pe kọlẹra pa ni Naijiria.
Ni 2011, eeyan 728 ni wọn ni o pa.
Bí o bá ń rí àwọn ǹnkan wọ̀nyí nípa kọ́lẹ́rà, àpẹẹrẹ ni
Gẹgẹ bi ajọ ‘National Health Service’ (NHS) to n ri si ilera ni UK ṣe wi, eyi ni awọn apẹẹrẹ arun Kọlẹra:
- Igbọnsẹ olomi gbuuru ti yoo mu ọ maa paara ile igbọnsẹ.
- Aarẹ ara
- Inu rírun
- Ki omi gbẹ lara (dehydration)
Bí o ṣe lè dènà àrùn onígbá-méjì
Ti o ba ba ara rẹ lori irin ajo lọ sawọn ibi ti kọlẹra ti n ja ran-in, eyi lawọn ohun ti o le ṣe lati dena rẹ
- Ma a fọ ọwọ rẹ loore-koore pẹlu ọṣẹ ati omi to mọ, paapaa lẹyin ti o ba lo ile igbọnsẹ tan
- Ri i daju pe o n fọ ọwọ rẹ ki o too bẹrẹ si i se ounjẹ pẹlu
- Omi inu ike ti wọn ti sè mọ tonitoni tabi ti iwọ funra rẹ sè nikan ni ki o maa mu
- Omi inu ike ti wọn ti sè tabi ti o sè funra rẹ nikan ni ki o maa fi fọ ẹnu rẹ
Àwọn ohun tí kò yẹ kí o ṣe
- Ma ṣe jẹ ewebẹ ti wọn ko fi omi inu ike fọ, ti ki i ṣe iwọ lo fọ ọ funra rẹ
- Ma ṣe jẹ salaadi ti wọn ko fi omi inu ike fọ ewe rẹ
- Yago fun awọn ounjẹ inu omi bii ede, ẹja, akan ati bẹẹ bẹẹ lọ lasiko yii
- Ma ṣe lo yinyin tabi bulọọku (ice) fun awọn nnkan mimu rẹ
Àjẹsára kọ̀lẹ́ra
Ohun to n dena arun onigba-meji yii wa, ti a le pe ni ajẹsara, ṣugbọn ọpọ eeyan ko nilo rẹ.
Niṣe ni wọn yoo fun eeyan ni ajẹsara naa bi nnkan mimu.
Fun agbalagba, ẹẹmeji ni wọn yoo gba a. Laaarin ọsẹ akọkọ si ikẹfa ni wọn maa n gba a sira wọn.
Ajẹsara yii le da aabo bo eeyan lọwọọ kọlẹra fun ọdun meji.
Ìtọ́jú àrùn onígbá-méjì
Itọju gboogi to wa fun arun Onigba-meji ni ki eeyan mu ọpọlọpọ omi, titi to fi mọ omi ti wọn maa n lo ti omi ara ba ti gbẹ.
Omi yii ni wọn tun n pe ni omi ìyè.
Iyẹfun oyinbo ti wọn ti ṣe bii oogun leeyan yoo po mọ omi lati rọpo iyọ, ṣuga ati eroja minira to ti kuro lara latari Kọlẹra.
Iyefun naa wa lawọn ile itaja oogun kaakiri.
Bi ara rẹ ko ba ya gidi, iwọ yoo ni lati lọ sile iwosan, nibi ti wọn yoo ti tọju rẹ pẹlu fifa omi si ọ lara.
Ati fifun ọ loogun apakokoro ti ko ni i jẹ ki Kọlẹra kari ara rẹ.














