'Ọkùnrin tó fipá bá mi lòpọ̀ gbàgbọ́ pé kíkọlu àfín yóò gbà á lọ́wọ́ àìsàn'

Oríṣun àwòrán, Paul Mahlasela
Regina Mary Nlodvu sọ pe o n ṣere ni ọgba iwaju ile rẹ nigba ti ọkunrin kan ti o gbẹkẹle fọwọ tẹ lara ni ọna ti ko ni fẹ si fun igba akọkọ.
O sọ pe: “O fun mi ni awọn ounjẹ aladun o si ni ki n jokoo sori ẹsẹ rẹ. “Nigba ti mo ṣe, o gbe ọwọ rẹ soke aṣọ mi, o si n tẹ mi lara.”
Regina sọ pe eyi ni igba akọkọ ti wọn fi ilọkulọ lọ - ni ọmọ ọdun mẹjọ - ṣugbọn eyi kii yoo jẹ ikẹyin.
O sọ pe ọkunrin kan naa tun pada wa si ile rẹ ni Ennerdale, South Africa, to si n dibo bi ẹni pe o wa ṣe abẹwo si awọn obi rẹ, ti o si fipa ibalopọ ni ọpọlọpọ igba ni awọn ọdun to tẹle.
Kii ṣe oun nikan, o sọ fun BBC. Regina ni oun tun fi oju wina awọn iṣẹlẹ miiran – eyi to jẹ ti ibalopo ati eyi ti ko jẹ mọ ibalopo -fun ọpọlọpọ ọdun.
Ẹni ọdun mẹrinlọgbọn naa sọ pe erongba awọn to n kọlu yii lo da lori pe o jẹ afin, ipo ti o jogun, eyi to mu da yatọ si awọn eeyan yooku nipa ti awọ ara rẹ.
Ọkunrin to n fipa ba lopọ gbagbọ pe fifi ipa ba lopọ yoo gbe lọwọ ṣiṣe aisan lailai, Regina ṣalaye
Ero yii jẹ ọkan ninu ọpọlọpọ ewu to yi awọn afin ka.
Ni bayi, lẹyin ọpọlọpọ ọdun to fi ni irẹwẹsi ọkan, oṣere South Africa ti wọn bi si orilẹede Zambia n pe fun igbọ ara ẹniye fun awọn eeyan to n gbe pẹlu ipo naa.
Pelu kiko lati ka ati kọ nikan ni ọdun 10 sẹyin nigba to wa ni ẹni ọdun mẹrinlelogun, o tun ti kọ, to si tun kopa ninu ere sinima rẹ nipa jijẹ afin ati igbesi aye tirẹ.
Regina, ẹni to sẹsẹ bimọ fẹ rii daju pe awọn yooku ko foju wina awọn to la kọja nipa ohun to rọ afin.
Awọn eeyan kan gbagbọ pe irun funfun ori afin le mu ọrọ̀ gidi ati owo pupọ wa fun wọn, ti awọn miiran si gbagbọninu nnkan miiran to buru - pẹlu pe nini ibalopọ pẹlu ẹnikan to wa ni ipo naa pẹlu igbagbọ pe o le wo HIV.
Lati igba Covid-19, awọn iroyin ofege kan naa lu sita pe o le wo aarun Corona virus paapaa.
Awọn eeyan to jẹ afin ni wọn bẹrẹ si ni ma ko sọwọ awọn ajinigbe nitori igbagbọ pe awọn ẹya ara wọn ni agbara nla.

Oríṣun àwòrán, Handout
O ranti: “Nigba ti mo jẹ ọmọ ọdun marun-un, ogunlọgọ awọn ọmọda maa n pe jọ sí ẹnu ọna ọgba wa lojoojumọ.
Nigba ti Regina ba sun mọ wọn, pẹlu ero pe awọn fẹ ṣere, wọn maa sa lọ.
O ro pe eyi jẹ apakan ere naa, titi to fi di igba kan obinrin kan wa sinu ọgba wọn pẹlu ọmọbirin rẹ kekere ni ọjọ kan.
O sọ pe: “Ọmọbìnrin kekere naa wo mi loju kan, o si bu sẹkun.
“O ro pe aderubaniyan ni mi, to si bi mi ninu gaan.” Regina tun ṣe akiyesi pe awọn ọmọ ile-ẹkọ to jẹ akẹgbẹ rẹ yoo tutọ sinu awọn aṣo wọn bi o ti n kọja lọ.
Lẹyin naa o fura si ihuwasi naa - nnkan ti wọn ro pe yoo daabobo wọn lati ma le ni eegun ti yoo mu wọn bi ọmọ to jẹ afin.
Regina tiraka lati pari iwe ẹkọ nitori ipo rẹ. O ṣoro fun un lati ri patako naa nítori iríran rẹ to to din ku (eyi jẹ ohunto wọpọ fun awọn afin), o si le ri awọn nnkan to ba sumọ. Ṣugbọn nígba to ṣalaye fun olukọ rẹ, olukọ naa sọ pe “ko si akanṣe eto ” ti wọn se fun un.
Regina kuro ile-ẹkọ, ti ko si kọ lati ka tabi ka iwe, eyi tumọ si pe ko ni anfani lati ri iṣẹ.
Amọ lọdun 2013, o ṣawari iwe ohun Bibelo, to yi igbesi aye rẹ pada. O ṣalaye pe:
“Mo maa n di ti mo ba ti ri iwe—wọn mu mi riri ara mi bi omugọ, ti idaduro si de ba ile aye mi ,” o ṣalaye.
“Ṣugbọn lẹyin naa Mo bẹrẹ si tẹ ti si awọn iwe ohun, Mo rii pe asopọ ẹwa wa laarin awọn ohun ati awọn ọrọ - ati ile aye ṣii fun mi.”
O ri anfani lati ma ṣe ere sinima, pẹlu iranlọwọ The Young African Leaders Initiative, o ni anfani lati le kọ, to si tun kopa ninu sinima rẹ to jẹ obinran kan lo ṣe “Mary, My voice.
"Nigbati mo wa ni ọdọ, ko si aṣoju fun eeyan to jẹ afin ninu ere sinima," o sọ. "Mo fẹ yi pada."
Ẹnikan ninu awọn olugbo eto Regina, ti ri ẹko gba nipasẹ ere rẹ, sanwo fun lati pese iranlọwọ fun olukọ aladani lati bẹrẹ kọ ẹkọ bi a ti se n ka ati kọ.
O ṣalaye pe: “Mo ṣi maa n ṣoro fun mi lati ka ati lati kọ iwe, amọ nibi ti wa de duro, ẹru ko ba mi bi ti tẹlẹ mọ.”
Regina nireti pe ni ọjọ kan oun yoo ni anfani lati ṣe iranlọwọ fun ọmọ obinrin nipa iṣẹ amurele ile-ẹkọ rẹ.
Ni bayii bo ti lẹ jẹ pe, o sẹẹsẹ n mu ọkan kuro nipa jijẹ abiyamọ - nipa awọn inira to lakọja ninu oyun.
“Ẹ wo o, ẹ wo bo ti ṣe rẹwa to...,” o sọbi o ‘se sumọ ọmọ rẹ tuntun, ọmọbìnrin ti orukọ rẹ n jẹ Bohlale Sabelo Isabel.
Bohlale ni wọn ko bi pẹlu awọ iya rẹ to jẹ afin ṣugbọn Regina sọ pe, bo ba jẹ bẹ inu “yoo dun”. O sọ pe: “O jẹ ohun ti mo ti kọ lati nífẹẹ.” O sọ.
“Oun ni gbogbo aye mi, mo sì nireti lati fun un lawọn anfani ti n ko ni ri.”















