Òde kò dára fún ikọ̀ adigunjalè tó ń ṣòwò ẹ̀gbà ọrun ọlọ́pọ̀ bílíọ́nù Naira, ọlọ́pàá ya bo ibùba wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile iṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria ti doju ibudo awọn to n ṣowo ẹgba ọrun ẹlẹgbẹgbẹ billiọnu Naira eyi ti wọn n gba lọwọ awọn alọni lọwọgba to wa nigboro ilu Abuja ati agbegbe rẹ ka.
Tẹẹ ba gbagbe pe lọjọ kejidinlọgbọn osu kẹrin ọdun 2024 ni isọwọ awọn adigunjale wa ṣọṣẹ ni ibugbe awọn agbofinro to wa ninu ọgba olu ile iṣẹ ọlọpaa ti Naijiria ni agbegbe Lugbe ilu Abuja.
Akasilẹ ẹrọ amunimọda CCTV to wa nibẹ safihan bi awọn adigunjale ọhun ti gbe apoti kan ti oriṣiriṣi ẹru bii ẹgba ọrun, iwe ẹri ikẹkọ, ẹrọ ibanisọrọ pẹlu awọn dukia olowo nla to jẹ ti awọn olugbe ibẹ salọ.
Bakan naa lo si jẹ wipe diẹ lo ku ki wọn gbẹmi lẹnu ọlọpaa kan nipasẹ bi won ti so aṣọ mọọ ninu ati oju lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.
Ẹrọ amunimọda to ṣe akasilẹ gbogbo bi iṣẹlẹ ọhun ti lọ, si lo ti bẹrẹ si ni ṣeranwọ fun iṣẹ iwadi to ti n lọ lọwọ.
Ni itẹsiwaju iwadi ti wọn ṣe lori ọrọ naa, wọn tọpasẹ awọn ẹru ti wọn ji ko ọhun de ọja Wuse nibi ti ẹnikan ti n jẹ Alhaji Auwal ti ra awọn ẹru naa.
Ọlọpaa ni irọ funfun balau ni iroyin to jade nipa idigunjale ni ilegbe ọga wọn.
Ile iṣẹ ọlọpaa si ti saaju ṣekilọ tako irufẹ ilana rira ọja lọna aitọ bẹẹ ninu ẹgbẹ awọn olowo goolu ni ilu Abuja, ṣugbọn ti Alhaji Auwal ṣe atọna rira ọja ọun pẹlu atọsọna lori bi ẹni naa yoo ti ṣe e si
Iwadi tun fidi ẹ mulẹ pe, Alhaji Auwal ati ọmọ rẹ ọkunrin wa lara awọn to n lọwọ ninu kara kata owo awọn ẹgba ọrun tabi goolu ti awọn alọnilọwọgba ba ji ko.
Ẹgbẹ ọun ni wọn si ti tọpasẹ de ọdọ awọn ikọ min eyi ti awọn ọlọpaa ṣi n ṣe iwadi le lori nilu Abuja lori irufẹ ẹsun kan na.
Gẹgẹbi atẹjade ti Olumuyiwa Adejobi, tii ṣe Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria fi lede ti wi, Afurasi ẹni Ọdun mẹrindinlọgbọn ati awọn minran ti ọwọ ṣikun agbofinro tẹ, lo ti wa latimọle lori aṣẹ tile ẹjọ pa, lẹyin ti iwadi ba pari tan ni gbogbo wọn yoo di ero kootu.
Adejobi tọ ka sii pe eyi yatọ si iroyin to gbode nipa bi wọn ti n gbe e kiri pe ninu ilegbe Ọga agba yaanyan ile iṣẹ ọlọpaa ti Naijiria ni igbesẹ idigunjale naa ti waye.
O tẹsiwaju salaye wipe iru awọn eeyan to n polongo ninu ilegbe ọga agba ọlọpaa ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ko fi bẹẹ mọ ile ti ọga ọlọpaa n gbe ti ri, ati wi pe ko si adigunjale kan to lee ni anfaani ati wọle sibẹ rara toripe eto aabo to wa nibẹ duro wamu wamu.
Ile iṣẹ ọlọpaa naa sọ pe wọn ni ifarajin to nipọn lori bi idajọ ododo yoo ti mulẹ labẹ ofin, O wa gba awọn eeyan ilu niyanju lati kọyin si iru iroyin ọun.
Atẹjade naa niwọn tun fi parọwa si awọn to wa nidi gbigbe eyikeyi iroyin to lee ta epo si aṣọ aala ileiṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria ni gbogbo igba wi pe ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ inu aṣọ.












