Ọlọ́pàá ká ẹ̀yà ara àti orí èèyàn mẹ́jọ nínú àpo gaàrí mọ́ ọkùnrin kan lọ́wọ́ l‘Ondo, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ti tẹ afurasi ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Yusuf Adenoyin, ẹni ti won ka orí eeyan mẹjọ mọ lọwọ nigba to n ririn ajo lọsí ipinle Osun.
Adenoyin, ẹni ọdún mọkanlelogbon jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi, ṣo fun ileeṣẹ ọlọpaa pe ilu Osogbo ni awọn onibara rẹ wa ati pe igba kẹta niyii to n ko ẹya ara eeyan lo si Osogbo fun tita, ko to dipe owo palabare segi.
Awọn nnkan miran ti Yusuf ni awọn ọlọpaa ka mọ oun lọwọ ni: ọkan Aja mẹfa ati oju ara maalu merin.
Afunrasi ọdaran na salaye pe o sese ko je awọn ọmọ Yahoo ni awọn onibara oun fí awọn eroja yii ṣiṣe fun.
Bawo ni Yusuf Adinoyi ṣe rí awọn ori eeyan yii?
Afunrasi ọdaran naa ni nnkan bi osu mẹta sẹyin ni ọrẹ rẹ to n jẹ Ismaila ja oun si iṣẹ karakata awọn ẹya ara eeyan.
O ni oun gba lati darapọ mọ isẹ yii lati tete wa owo ile iwosan fun iya rẹ to wa ni idubule aisan ti dokita sì n bere fún miliọnu meji naira lati toju iya naa.
Yusuf ṣalaye pe ọrẹ rẹ Ismaila ma n lọ si awọn oriko ti won n sin ọku si lati lọ wu oku lẹyìn ti awọn mọlebi wọn ba ti sìn ara oloogbe naa tan, to si ma ge awon ẹya ara to wulo fún tita.
Ti Ismaila ba ti mu awọn ẹya ara yii tan, Yusuf ni yoo wa ta ori kan fun oun ni egberun meji naira.
Ninu ọrọ rẹ, Yusuf ni inu apo garri ni oun ma n ko awọn ori gbigbẹ yi si lọsí ilu Osogbo fún tita
O ni " isẹ karakata epo pupa ati koro cashew ni mo n ṣe tẹlẹ ko to di ẹni to n ta ẹya ara eeyan nitori mo n wa owo fun itọju Iya mi to wa n'ipo aisan.
" Orí itakun ibanidọrẹ Facebook ni mo ti pade onibara mi to wa ni Osogbo.
Ni igba akọkọ ti mo maa ko awọn ori gbigbẹ yii lati ipinlẹ Kogi lọ si Osogbo, Ori mẹrin ni mo lọ ta. Ni ẹlẹẹkeji, mo ta ori mẹta.
Igba kẹta ni mo ko si panpẹ ọlọpaa pẹlu ori eeyan mẹjọ"
Yusuf ṣalaye pe ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì naira (35,000) ni oun man ta ori gbigbẹ kan sugbọn nigba miran, wọn le ra ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ( 30,000 )
O darukọ awọn onibara rẹ bi Opeifa, Oṣioyemi, Alfa Agba, ati Al Mosuru.
Bawo ni Yusuf ṣe ko si panpẹ ọlọpaa?
Kọmisana Ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Peter Abayomi nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe Ikọ Ọlọpaa ni agbegbe Isua Akoko ni wọn da ọkọ ti afunrasi naa wa duro fún ayẹwo, ko to di pe arakunrin naa gbiyanju lati fẹsẹ fẹ ẹ.
"Owurọ ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa ni awọn Ikọ Ọlọpaa to n mojuto alaafia ni opopona marosẹ laarin ilu Epinmi ati Isua Akoko ni wọn da ọkọ Nissan Salon kan duro lati ṣe ayẹwo.
"Nigba ti wọn ṣe ayẹwo yii lọwọ ni ọkan lara awọn ero ọkọ naa fẹ gbiyanju lati fẹsẹfẹ eyi to mú kí awọn agbofinro naa le mu.
"Lẹyìn ti ọwọ tẹ ni wọn ṣe ayẹwo ẹru ti arakunrin naa gbe rin irinajo, wọn si ba ori eeyan mẹjọ gbigbẹ, ẹran ara ti o jọ mọ ara eeyan ati awọn oogun abẹnugọngọ ninu ọra ti won gbe pamọ si inu apo garri"
Abayomi to ni wọn ma ṣe ayẹwo awọn ẹya ara naa, wa rọ awọn araalu lati ni ifọwọsowọpọ pelu awọn agbofinro.
Ọga ọlọpaa na fikun pe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria labẹ idari ọga agba ọlọpaa Kayode Egbetokun, mu ìtọjú awọn ọlọpaa lọkunkundun fun alekun isẹ wọn.















