Ààrẹ Tinubu ṣubú níbi àyájọ́ ìjọba àwarawa June 12 nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT/TVC NEWS
Iṣẹlẹ nla lo ṣẹ ni gbagede Eagles nilu Abuja loorọ Ọjọru lasiko ti ayẹyẹ ajọdun ijọba awarawa June 12 n waye.
Aarẹ Bola Tinubu ni o si akasọ to fẹ gun ka lasiko to n gbiyanju lati wọnu ọkọ to fẹ gbe kiri nibi ti ti ayẹyẹ ayajọ ijọba awarawa naa ti n waye.
Kete ti Aarẹ ti gbe ẹsẹ lati gun ọkọ, ni ẹsẹ Aarẹ tase, to si ku diẹ ko mori le lẹ ninu gbọngan Eagles Square niluu Abuja.
Diẹ si lo ku ki ayẹyẹ ayajọ awarawa naa dẹnu kọlẹ nitori isẹlẹ yii.
Akọroyin BBC to wa ni gbongan Eagles Square ni kete ti Aarẹ subu ni awọn ẹsọ alabo to wa ni ayika Aarẹ sure lati fa Aarẹ dide.
Sugbọn pẹlu bi Aarẹ ṣe subu yii, ko da duro lati tẹsiwaju ninu sise ayajọ ijọba awarawa pẹlu awọn arralu to wa ni gbọngan Eagles Square.
Bẹẹ ba gbagbe, o ni orilẹede Naijiria n ṣe ayajọ ijọba awarawa lorilẹede Naijira.
Ileeṣẹ Aarẹ sọrọ lori isẹlẹ naa
Olubadamọran si Aarẹ Bola Tinubu lori ọrọ Ayelujara, Dada Olusegun ti ni ki awọn araalu ma ṣe gbe ọkan soke lori ilera Aarẹ lẹyin ti Aarẹ si ẹsẹ ka lasiko to fẹ gun akasọ ọkọ ni gbọngan Eagles Square niluu Abuja.
Ninu ọrọ ti olubadamọran na gbe sori ayelujara, o ni lẹsẹkẹsẹ ti Aarẹ ni o dide to si tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ.
“Aarẹ si akasọ to fẹ gun ka lasiko ayajọ ijọba awarawa June 12 .
“Lẹsẹkẹsẹ ni Aarẹ dide, to si tẹsiwaju ayajọ naa. Ko si laburu.”

Oríṣun àwòrán, X/DOlusegun
Ààrẹ Bola Tinubu yóò bá àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ láàrọ́ òní

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ laarọ oni ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2024, to jẹ ayajọ iṣe jọba awarawa, ‘June 12’.
Ni dede aago meje aarọ ni Aarẹ yoo ba awọn araalu sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan.
Ọọfisi Aarẹ ti wa ke si gbogbo ileeṣẹ amohunmaworan ni Naijiria atawọn ileeṣẹ redio ki wọn darapọ mọ ileeṣẹ igbojunsafẹfẹ ijọba apapọ, NTA ati Radio Nigeria, ki ọrọ naa le de tile toko.
Ikede yii lo jade ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Aarẹ, Ajuri Ngelale, fi lede lọjọ Iṣẹgun.
Gbogbo ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdọdun ni ayajọ iṣejọba awarawa ni Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ayajọ ọjọ yii ni wọn kọkọ fi n ṣe iranti agba oloṣelu ni to di oloogbe, MKO Abiola.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un ni ayajọ iṣejọba awarawa tẹlẹ ni Naijiria ki wọn to yipada si ọjọ kejila, oṣu Kẹfa.
Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe ọjọ iranti ati ajayọ ijọba awara ni ọjọ yii jẹ fun ijọba Naijiria, ọpọ araalu lo maa n fi ayajọ ọjọ naa sọko ọrọ si ijọba latari bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe ri, koda awọn mii maa n fi ọjọ naa ṣe ifẹhonuhan.
Wayi o, ọpọ araalu lo n reti ohun ti Aarẹ yoo sọ, paapaa lori eto ọrọ aje to denukọlẹ, ọwọngogo epo bẹntiro, ọwọngogo ounjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.















