Mọ̀lẹ́bí sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa Sule Suebebe lẹ́yìn tó dé ọ̀dọ̀ Pásítọ̀ Agbala Gabriel

Oríṣun àwòrán, Others
Toyin Abimbola, ọkan lara mọlẹbi Dayo Adewunmi, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Sule Suebebe ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to se okunfa iku agba osere naa.
Bẹẹ ba gbagbe, BBC Yoruba ti mu iroyin wa fun yin saaju pe Sule Suebebe ti dagbare faye ni owurọ ọjọru, ọjọ Kejila Oṣu kẹfa ọdun 2024.
Nigba to n salaye iku to pa oloogbe naa lori foonu lasiko ti BBC Yoruba pe e lori aago, Toyin Abimbola ni o ti pẹ diẹ ti agba oṣere naa ti wa lori idubulẹ aisan.
O ni ti pẹ ti agba oṣere naa ti n ṣe aisan ko to di pe o dero ile iwosan nibi to dakẹ si.
"Miliọnu mẹwa Naira ni Sule Suebebe ri gba nigba to tọrọ owo fun itọju ara rẹ"
Toyin Abimbola tẹsiwaju pe ile iwosan ti wọn gbe oloogbe naa lọ nigba ti aisan yii tun bẹrẹ pada, ni ọlọjọ ti de ba a.
"Gbajugbaja olusọ aguntan, Gabriel Amusan lo wa lati gbe agba oṣere naa kuro ni Ado Ekiti to wa, to si gbe wa si ilu ibadan nibi to ti n gba itọju.
“Ile iwosan to wa ni Ibadan ni wọn dakẹ si. Emi ni mo n tọju wọn.
“Aisan yii ti wa tipẹ, ti Agbala Gabriel si wa lati wa gbe wọn kuro ni Ado Ekiti wa si ilu Ibadan.
“Ile iwosan ni wọn dakẹ si ni owurọ oni.”
Lọdun to kọja ni Sule Suebebe rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria lati se iranlọwọ owo fun oun lori kudiẹ kudiẹ to de ba ilera rẹ.
O ri milọnu mẹwaa naira gba lọwọ awọn ololufẹ rẹ lasiko naa ti Agbala Gabriel ṣe atọna bi o ṣe ri owo naa gba.
Agbala Gabriel ni ile ti Suebebe n gbe ni awọn ti bẹrẹ atunṣe, to si n rọ awọn araalu lati ma gbadura ilera to peye fun agba oṣere naa nigba to ṣe abẹwo si lọdun to kọja
Àgbà òṣèré, Sule Suebebe jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajugbaju oṣere tiata Dayo Adewunmi, ẹni ọpọ mọ si Sule Suebebe ti jade laye.
Iroyin nipa iku agba oṣere tiata naa ni gbajugbaja pasitọ, Gabriel Ademola Amusan ti fidi rẹ mulẹ lori opo ayelujara rẹ.
O ni se ni laanu pe agba oṣere naa jade lẹyin gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi rẹ ni ile iwosan.
“O ṣe ni laanu pe Baba Suebebe jade laaye ni owurọ oni ni ile iwosan. Ki Ọlọrun ba wa tẹ wọn safẹfẹ rere."
Bẹẹ ba gbagbe lọdun to kọja, Suebebe kesi awọn ọmọ Naijiria lati ran lọwọ lori kudiẹkudiẹ to de ba ilera rẹ.
Gẹgẹ bii ọrọ ti Agbala Gabriel gbe sita ile iwosan ni agbe oṣere naa ti dagbere faye.

Oríṣun àwòrán, Screengrab
Lọdun to kọja naa Sule Suebebe tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn obinrin to ti sẹ lagbo ere sinima tabi ni ibo miiran
O tọrọ aforijin naa ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara Facebook.
Suebebe, ẹni to jẹ gbajumọ lagbo ere sinima agbelewo nigbakanri lo nni ipenija ilera, ti ko si ni anfani lati le rin mọ bayii.
O ni o se koko ki oun tọrọ aforijin lọwọ gbogbo obinruin ti oun ti fẹ ri.
"Gbogbo ẹni ti mo ba sẹ, yala ẹni ti mo mọ tabi ti n ko mọ, ẹ jọwọ, ẹ darijin mi.
"Ori idọbalẹ lo yẹ ki ti ma sọ eleyii sugbọn ko si aye fun mi lati dọbalẹ.
"Ẹ jọwọ, paapa awọn obinrin ti mo ti sẹ, nitori mo mọ pe mo ti tẹ ọpọlọpọ ẹmi mọ lẹ."















