Ohun tá a bá lágbára la máa san gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù - Ààrẹ sọ̀rọ̀, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yarí

Aworan aarẹ Bola Tinubu ati Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, X/official BAT/NLC

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ni o dabi pe ọrọ wọn fẹ maa tako arawọn nipa ọrọ owo oṣu to kere julọ tuntun fawọn oṣiṣẹ.

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti jẹ ko di mimọ pe oun ṣetan lati buwọlu ohun ti agbara ijọba ka nipa owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ.

Bakan naa ni Aarẹ fi to ile igbimọ aṣofin leti pe ki wọn maa reti aba latọwọ ijọba apapọ lori ọrọ owo oṣu to kere julọ naa.

Ẹgbẹ oṣisẹ lorilẹede Naijiria ninu atẹjade ti wọn fi lede sọ pe awọn ko i tii fẹnuko lori adehun kankan pẹlu ijọba apapọ.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ayajọ ọdun ijọba awaarawa niluu Abuja, Aarẹ Tinubu ni ohun ti agbara ọmọ Naijiria ka ni awọn yoo fi ransẹ si ile igbimọ.

Bẹẹ ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni ijiroro nipa owo oṣu tuntun wa sopin, igbimọ ijọba apapọ pẹlu awọn apapọ ileeṣẹ aladani OPS ni N62,000 ni ijọba fẹ san lati N60,000 ti wọn kọkọ gbe sita fun awọn oṣiṣẹ.

Ẹwẹ, owo ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n bere fun jẹ N250,000 loṣu.

Aarẹ sọ fun Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ati awọn akẹgbẹ rẹ ni ile igbimọ aṣofin pe ki wọn ṣe ohun to tọ ni ibamu pẹlu ofin.

“Aarẹ ile igbimọ aṣofin, igbakeji Aarẹ, ẹ o gbọ lati ọdọ mi ti mo ba ti yi erongba mi pada lori ọrọ owo oṣu to kere ju.

“A setan lati se ohun ti a ni lagbara. Wọn ka gẹ aṣọ wa gẹgẹ bii ohun ta ni lagbara.”

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fèsì lórí ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ sọ lórí owó oṣù tuntun

Ọrọ lori owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ni o da bi pe ko ti ni iyanju lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ tako ọrọ ti Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu sọ pe awọn ihun mejeeji ti fẹnuko lori owo oṣu tuntun.

Aarẹ, ninu ọrọ rẹ isiti rẹ si awọn araalu sọ pe awọn igbimọ to n risi owo oṣu tuntun yoo ti gbe ohun ti wọn ti wọn pinnu le siwaju ijọba, ti ijọba yoo si kan si ile igbimọ aṣofin ni laipẹ lati gbe igbesẹ to yẹ.

Igbimọ to n risi owo oṣu awọn oṣiṣẹ ti ni N62,000 ni ijọba apapọ n gbero lati san awọn oṣisẹ gẹgẹ bii owo oṣu tuntun.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria tun ti fi ake kọri pe awọn ni tẹwọgba owo oṣu ti ijọba n gbero lati san .

Ko si adehun kankan pẹlu ijọba apapọ-NLC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

NLC, ninu atẹjade ti Adewale Adeyanju, ẹni to duro fun Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ, Joe Ajaero nibi ipade kan to waye ni Geneva lorilẹede Switzerland.

“O yẹ ki awọn olubadamọran Aarẹ le sọ fun Aarẹ pe a ko ti fẹnuko lori ọrọ owo oṣu tuntun pẹlu ijọba apapọ.

“Owo ti a n bere fun ni N250,000, a ko yi pada, wọn ko ti fun wa ni idi pe a yi ipinnu wa pada, eyi ti a gbagbọ pe yoo ṣe atunṣe aye awọn oṣiṣẹ.

“O ya wa lẹnu ohun ti Aarẹ sọ pe a ti fẹnuko lori ọrọ owo oṣu tuntun. A gbagbọ pe awọn olubadamọran Aarẹ lo si Aarẹ lọna to pe gbagbọ pe ijọba ti fẹnuko pẹlu NLC ati TUC.

“Ko si nnkan to jọ mọ bẹ, o ṣe koko ki Aarẹ ati awọn ti ọrọ kan mọ pe ijiroro si n lọ lọwọ nipa owo oṣu tuntun.

“A ko ti ri iwe ti igbimọ ni awọn fi ransẹ si Aarẹ di asiko yi.”

Ẹgbẹ oṣiṣẹ fikun pe awọn ko ni tẹwọgba owo oṣu ti ko tan iṣoro awọn oṣisẹ lọwọ yii.

“A ko le ma siṣẹ, ki iya tun ma jẹ wa. A fẹ idajọ ododo, didọgba ati fifarahan fun awọn ọmọ Naijiria, ti a si lero pe igbesẹ Aarẹ yoo fun wa ni ireti to dara.

“Anfani ree fun Aarẹ lati fi han awọn araalu pe lootọ ni oun ṣetan lati ma gbọ ohun ti araalu n sọ.”

Wo kókó ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Bola Tinubu báwọn ọmọ Nàíjíríà sọ ní àyájọ́ ìjọba àwaarawa

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/Instagram

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu kan sara si awọn ọmọ orilẹede Naijiria fun bi wọn ṣe gba alaafia ati ijọba awarawa laaye lorilẹede Naijiria.

Aarẹ sọ eyi nigba to n ba ki awọn ọmọ orilẹede ku orire ayajọ ijọba awarawa ti ọdun 2024.

Bẹẹ ti mọ pe mo ko si bi a ṣe fẹ peto ijọba awarawa ti a ko ni darukọ Oloye Moshood Kashimawo Abiola, Aarẹ Tinubu kan sara ipa ti Abiola ati iyawo rẹ Kuburat Abiola ko lọdun 1993.

Bakan naa Aarẹ gbe oṣuba fun gbogbo agba ọjẹ lorillẹede Naijiria fun iṣẹ takutaku ti wọn gbe ṣe lati mu ki ilọsiwaju de ba orilẹede Naijiria.

“Lonii lọdun mọkanleloun sẹyin, a bẹrẹ irinajo si ijọba awarawa to wa fun otitọ ati idagbasoke orilẹede wa.

“Bo ti lẹ jẹ pe ipenija wa bi aṣe gunle irinajo yii. Padanu awọn akikanju lọkunrin ati obinrin. Ninu irinajo yii ni ati padanu Oloye MKO Abiola ati iyawo rẹ, pẹlu awọn ologun bii Ọgagunb Shehu Musa Yar’Adua ati Pa Alfred Rewane ti fun bi wọn ṣe fi ẹmi wọn le lẹ fun orilẹede Naijiria.”

A ti fẹnuko lori ọrọ owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ

Aarẹ Bola Tinubu sọrọ nipa iyanṣẹlodi ti awọn egbẹ oṣisẹ gunle lori ọrọ owo oṣu tuntun, pe ijọba oun ko fi igba kankan tẹ oju awọn oṣiṣẹ mọlẹ bi ijọba apaṣẹwa.

O ni awọn di aye silẹ fun ẹgbẹ oṣisẹ lati fi ehonu wọn han sita .

“A ko dunkoko mọ ẹnikẹni, tabi fofin mu ẹnikẹnu, a fi aye silẹ fun ijiroro, ti a si ransẹ pe ẹgbẹ oṣisẹ.

“A ti jiroro nipa ọrọ owo oṣu tuntun yii, ti a ko si ni pẹ fi ohun ta fẹnuko ransẹ si ile igbimọ aṣofin lati ṣe ohun to tọ.”

Bakan naa ni Aarẹ tun pe fun fọwọsowọpọ araalu lati jẹ gbogbo erongba ijọba rẹ wa si imusẹ.

“Mo mọ iṣẹ to wa ni iwaju mi, mo si n fi dayin loju pe inu mi dun pe mo wa nipo lati mu ayipada de ba orilẹede wa.

“Mọ mọ pe inira wa sugbọn fun igba diẹ ni nitori a ti pe ohun ti yoo jẹ ka ni ọjọ ọla rere.”

Bakan naa ni Aarẹ tun pe fun fọwọsowọpọ araalu lati jẹ gbogbo erongba ijọba rẹ wa si imusẹ.

Inira ti eto ọrọ Aje n mu wa

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ṣalaye pe oun mọ inira ti eto ọrọ Aje mu wa fun awọn araalu sugbọn o ni oṣe koko ki atunṣe to yẹ ko ti wa tipẹtipẹ si eto ọrọ Aje waye .

O tẹsiwaju wi pe ipinlẹsẹ eto ọrọ aje naa lo da lori ohun ti ko le mu ilọsiwaju ti a n fẹ wa si eto ọrọ aje.

“Igbesẹ ti a gbe ni lati sẹda ọrọ aje to munadoko, ti yoo nipa nla fun ọja ọla wa.

“Ko si anini pe igbesẹ yii mu inira dani sugbọn sibẹsibẹ o wa lati mu ki eto ọrọ aje wa jẹ ohun amuyangan ti yoo ma pese anfani fun gbogbo araalu.

“Bi a se n tẹsiwaju ninu igbesẹ yii, mi o ni kọ eti sọrọ araalu , n ko si ni kọ ẹyin mi si yin rara.”

Aare kan sara si awọn akikanju to fi apẹrẹ ijọba awarawa silẹ

Aarẹ ni ko si bi a ṣe fẹ sọrọ nipa ijọba awarawa ti a ko ni darukọ awọn akinkanju eeyan kan to fi ẹmi wọn le lẹ lati jẹ orilẹede Naijiria ni ilọsiwaju rere.

Aarẹ kan sara si Oloye Anthony Enahoro, Oloye Abraham Adesanya, Commodore Dan Suleiman, Oloye Arthur Nwankwo, Oloye Chukwuemeka Ezeife, Admiral Ndubuisi Kanu, Oloye Frank Kokori, Oloye Bola Ige, Oloye Adekunle Ajasin, Oloye Ganiyu Dawodu, Oloye Ayo Fasanmi, Oloye Gani Fawehinmi, Oloye Olabiyi Durojaiye, Dr. Beko Ransome-Kuti, Chima Ubani, ati awọn mii

Bakan ni Aarẹ orilẹede Naijiria ko ni gbagbe ohun ti Ọgagun Alani Akinrinade, Ọjọgbọn Bolaji Akinyemi, Ọjọgbọn Wole Soyinka, Oloye Ralph Obioha, Oloye Cornelius Adebayoati awọn gbe ṣe lasiko ti orilẹede Naijiria n pe fun ijọba awarawa jẹ ohun mọnigbagbe nitori fun ọdun méfa ni wọn fi wa ninu inira pe wọn le wọn kuro lorilẹede.