Wo orin ìbílẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá tí Awolowo gbé kalẹ̀, táwọn Gómìnà fòǹtẹ̀ lù

Àkọlé fídíò, Ó yá o, ẹ wá kọ́ orin ìbílẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá tí Awolowo gbé kalẹ̀, táwọn Gómìnà fòǹtẹ̀ lù

Awọn gomina ilẹ Yoruba ti kede sita pe awọn ti fẹnuko lori orin ibil kan soso to yoo ṣapejuwe ilẹ Yoruba.

Ikede yii lo jade lasiko ti wọn yan alaga tuntun fun ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Yoruba.

Awọn Gomina naa, eyi ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu jẹ alaga fun bayii kede igbesẹ naa ni ile ijọba ipinlẹ to wa ni Alausa Ikeja nipinlẹ Eko pẹlu awọn Gomina ilẹ Yoruba yooku.

Awọn Gomina to wa nibi ipade naa ni Gomina Babajide Sanwo-olu ti ipinlẹ Eko, Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo, Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun, Gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun, Gomina Biodun Oyebamiji ti ipinlẹ Ekiti ati Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyadatiwa.

Aworan awọn Gomina iwọ oorun orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, facebook.com/jidesanwooluofficial

Ta lo sẹda orin iyin ilẹ Yoruba ati pe ọdun wo ni wọn kọ sita?

Agba ọjẹ ninu oṣelu ati olori iwọ oorun nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Oloye Obafemi Awolowo lo ṣe ẹ̀dá orin naa ni ọdun 1978 nigba to da ẹgbẹ oṣelu UPN silẹ.

Awolowo ṣapejuwe orin naa gẹgẹ bii ohun idanimọ fun awọn ilẹ Yoruba ni ile loko lati le ma ṣe iranti orisun wọn.

Nigba to n sọrọ nipa orin yii, Gomina tẹlẹri nipinlẹ Osun, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ni Oloye Obafemi Awolowo lo kọ orin, to si ransẹ pe oloogbe Herbert Ogunde lati ran oun lọwọ fi adun ati ilu si.

Ipinlẹ Ondo ati ipinlẹ Osun ti yan orin yii laayo gẹgẹ bi orin ipinlẹ wọn saaju ikede ti awọn Gomina ilẹ Yoruba.

Wo orin Ibilẹ ilẹ Yoruba

ORIN ÌBÍLẸ̀ FÚN ILẸ̀ YORÙBÁ LÁPAPỌ̀

1. Iṣẹ wa fun ilẹ wa

Fun Ilẹ ibi wa

Ka gbe e ga

Ka gbe e ga

Ka gbe e ga f'aye ri

2. Igbagbọ wa ni wi pe

B'ati b'ẹru, la b'ọmọ

Ka sisẹ,

Ka sisẹ,

Ka sisẹ, ka jọ là.

3. Isọkan ati ominira

Ni kẹ jẹ ka maa lepa

Tẹsiwaju, f'ọpọ ire

Ati ohun to dara.

4. Ọmọ Oodua dide

Bo si ipo ẹtọ rẹ

Iwọ ni imọlẹ

Fun gbogbo Adulawọ

Àkọlé fídíò, Aseyin ti Iseyin: Bẹ́ńsù ojú, ni mo fi kọ ilà mẹ́ta sí ẹ̀ẹ̀kẹ́, kí n tó kọ ilà gidi

Wo kókó mọ́kànlá tí àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá fẹnukò lé níbi ìpàdé wọn tó wáyé l‘Eko

Southwest governor's forum

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu

Agbarijọpọ awọn gomina ilẹ Yoruba ni Naijiria ti fẹnuko pe awọn ko fẹ iyapada ilẹ Yoruba kuro lara Naijiria.

Nibi ipade wọn to waye ni Alausa, niluu Eko ni wọn ti fẹnuko bẹẹ.

Ẹgbẹ awọn gimina ọhun tun tun yan gomina ipinlẹ Eko, Babjide Sanwo-Olu gẹgẹ bii olori wọn.

Igbesẹ yiyan Sanwo-Olu yii lo waye lẹyin iku olori wọn tẹlẹ, gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo to jade laye lọdun to kọja.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni gomina Seyi Makinde (Oyo), Dapo Abiodun (Ogun), Lucky Aiyedatiwa (Ondo), Ademola Adeleke (Osun), Biodun Oyebanji (Ekiti), ati gomina Babjide Sanwo-Olu (ipinlẹ Eko).

Iwọnyii ni awọn koko tawọn gomina naa fẹnuko le lori

  • Yato si pe wọn tako idasilẹ Yoruba Nation ti awọn eeyan kan n bere fun, ipese ounjẹ ati bi eto ọrọ aje ilẹ Yoruba yoo ṣe gberu si lo lewaju ijiroro wọn
  • Wọn tun jiroro lori ọrọ eto abo iwọ oorun Naijiria, wọn si fẹnuko pe awọn fọwọ si idasilẹ ọlọpaa agbegbe
  • Awọn gomina ọhun tun jiroro lori bi awọn ileeṣẹ eto abo Naijiria yoo ṣe maa fọwọsowọpọ pẹlu ikọ alaabo Amotekun
  • Lọna ati pese ounjẹ lọpọ yantutu fun awọn araalu, awọn gomina naa ke si gbogbo awọn kọmiṣọna eto ọgbin kọọkan wọn ki wọn bẹrẹ ajọṣepọ lori ipese ounjẹ
  • Lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, awọn gomina naa sọ pe awọn faramọ igbesẹ ati akitiyan ijọba apapọ lati yanju ọrọ naa pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ
  • Awọn gomina ọhun tun sọrọ nipa awọn ohun alumọni ilẹ Naijira, ninu eyii ti wọn ti ni awọn n fẹ ki ijọba apapọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn ipinlẹ lori ọrọ iwakusa
  • Ni ti Yoruba Nation, awọn gomina fẹnuko pe awọn ko fọwọ si, awọn ko si fẹ ki ilẹ Yoruba yapa kuro lara Naijiria, nitori Yoruba Nation kọ ni yoo tan iṣoro ti ilu n dojukọ lasiko yii
  • Ninu apero wọn, wọn fenuko pe ki ilẹ Yoruba ni ori iyin kan ṣoṣo eyii ti orukẹ rẹ n jẹ ‘Iṣẹ wa fun ilẹ wa.” Orin naa ni ẹgbẹ Afenifere kọ ni ọpọ ọdun sẹyin, orin ọhun si ni wọn fọwọ si fun gbogbo ipinlẹ mẹfẹfa to wa nilẹ Yoruba dipo orin ti awọn ipinlẹ naa n lo tẹlẹ
  • Awn gomina ilẹ Yoruba tun koro oju si iwa kotọ kan tawọn eeyan kan to n pe fun ominira ilẹ Yoruba, Yoruba Nation n hu, ti wọn si kede pe awọn nigbagbọ ninu isọkan orilẹede Naijiria
  • Ohun ti wọn fẹnuko le lori kẹyin ni ti ajọ DAWN, eyii ti wọn ni yoo mu irẹpọ ati idagbasoke ba gbogbo ipinlẹ ilẹ Yoruba, yoo tun mu ki eto abo awọn ipinlẹ naa nipọn siwaju si
  • Lẹyin gbobo apero wọn ni wọn yan gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko gẹgẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina naa.