Àwọn aṣòfin dábàá ṣáà ọlọ́dún mẹ́fà fún ààrẹ àti àwọn gómìnà

Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin

Oríṣun àwòrán, HOUSE OF REPRESENTATIVES/FACEBOOK

Awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Naijiria kan ti dabaa lọjọ Aje pe, ki awọn aarẹ ati awọn gomina, maa lo saa kan ṣoṣo ti yoo jẹ ọlọdun mẹfa.

Wọn n fẹ ki eyi dipo saa ọdun mẹrin ti wọn ma n ṣe ni ẹẹmeji.

Awọn aṣofin naa ti Ikenga Ugochinyere, to n ṣoju ẹkun idibo Ideato Federal Constituency, sọ pe atunṣe si ofin ọdun 1999 yoo mu ayipada rere ba iṣejọba.

Aba ofin ọhun to ti wọ ipele kika keji, ni wọn ṣalaye pe yoo mu adinku ba iye owo iṣejọba ati ipolongo.

Bakan naa ni wọn ni yoo mu ki iṣọkan, idagbasoke ati idajọ ododo ko wa, ti yoo si tun dena magomago lasiko idibo nitori pe ajọ INEC yoo ni ominira.

Awọn aṣofin ọhun labẹ aburada Reform Minded Legislators, tun dabaa pe ki igbakeji aarẹ jẹ meji - ẹnikan lati Gusu, ikeji lati Ariwa.

Igbakeji aarẹ akọkọ ni yoo dabi adele, o si gbọdọ wa lati ẹkùn kan naa pẹlu aarẹ. Oun ni yoo si rọpo aarẹ ti ko ba l'agbara lati ṣe ijọba mọ.

Ẹnikeji yoo si jẹ minisita fun amojuto ọrọ aje.

Ẹgbẹ aṣofin naa tun fẹ ki idibo gomina ni gbogbo ipinlẹ mẹrindinlọgbọn maa waye ni akoko kan naa.

Wọn ni awọn n fẹ ki aarẹ maa wa lati ẹkùn mẹfa to wa ni Naijiria, ni ṣiṣẹ-n-tẹle. Igbagbọ wọn ni pe yoo din kirakita lati di aarẹ, dinku.