Tinubu jèrè inú rere mi, ni àga gómìnà Eko kò ṣe gbóná mọ́ ọ nídìí - Atiku

Tinubu ati Atiku

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Igbakeji Aarẹ tẹlẹri ni Naijiria, to tun jẹ eekan pataki ninu ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar, ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ to n ja nilẹ.

Bẹẹ lo sọ idaniloju ọrọ Aare Bola Tinubu lo ti jẹ anfaani nipasẹ atilẹyin ti ohun ṣe fun un.

Lọjọbọ ọsẹ to kọja ni igbakeji Aarẹ ilẹ Naijiria, Kashim Shettima, salaye wipe Atiku ati Nuhu Ribadu jẹ anfaani Tinubu nigba to fun wọn nibi ti wọn fori pamọ si lasiko isoro oselu.

Shetimma tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ilegbe Aarẹ Tinubu to wa ni adugbo Bourdillon nilu Eko, ni Atiku maa n fara pamọ si nigba ti wahala ba dide sii ninu ẹgbẹ oselu PDP.

Ninu atẹjade ti Atiku fi lede nipasẹ agbẹnusọ iroyin rẹ, Paul Ibe fọwọsi, o tọka sii pe irọ ni ọrọ ti shetiima sọ ati wipe Aarẹ Tinubu gan lo jẹ anfaani inu re Atiku lagbo oselu.

O salaye wipe atilẹyin ti oun ṣe fun un lo jẹ ko rọwọmu lati di Gomina nipinlẹ Eko, bakan naa lo ni oun ba Tinubu dena iyọnipo.

Atiku ni ohun ko gbe apoti labẹ ẹgbẹ oselu ti Aarẹ Tinubu jẹ adari fun rara, pẹlu alaye lori bi igbe aye oselu rẹ ti ri lasiko eto idibo ọdun 2007.

O wa gba Shettima nimọran lati dẹkun sisọ awọn ọrọ ti alaye rẹ ko ba ye e daada.

Atẹjade naa tun ran Shettima leti pe, Atiku ko gbe apoti ibo labẹ ẹgbẹ oselu ACN sugbọn to jade labẹ ẹgbẹ oselu AC leyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDM ati awọn alatilẹyin min, lati igun ti Aarẹ Tinubu lẹgbẹ oselu AD, si darapọ mọ.

O tẹsiwaju pe Aarẹ Tinubu ko lagbara lati gba a laaye lati dije sugbọn to jẹ wipe awọn asoju lati ipinlẹ kọọkan lo panupọ faa kalẹ.