Ikú òṣèré tó rì sínú omi jẹ́ kí Nollywood mójútó ètò ààbò òṣèré

Aworan Junor Pope ninu oko oju omi

Oríṣun àwòrán, Junior Pope/Instagram

    • Author, Hannah Gelbart
    • Role, BBC What in World, Lagos

Fidio to kẹyin ti oṣere tiata lorilẹede Naijiria, Junior Pope ṣe gbẹyin jẹ ki awọn ololufẹ rẹ to le ni milọnu meji lori opo ayelujara Instagram ri iku rẹ saaju iṣẹlẹ to waye.

"O ri awọn ewu, eyi eniyan, ti a n la kọja lati mu inu yin dun," oṣere ẹni ọdun mejilelogoji kigbe bi ọkọ oju-omi kekere rẹ ti n sare lọ ni Odo Niger.

O rẹrin - ko ṣe kedere ti o ba jẹ ti ayọ tabi nnkan mi - o sọ fun awakọ lati se suuru ere sisa .

"Mo n bẹbẹ fun olori-ogun pe emi nikan ni ọmọ ti obi mi bi ati pe mo ni ọmọkunrin mẹta,"

Oṣere naa - ẹniti orukọ rẹ n jẹ John Paul Odonwodo - ariwo soke bi o ti ṣe akiyesi pe omi n yabọ sọdọ ọkọ oju omi rẹ.

Ni ojo keji irawo oṣere Nollywood ti jade laye.

O ri sinu odo kan naa lẹyin ti ọkọ oju omi to wa kọlu ọkọ oju omi to pẹja.

Eeyan mẹrin miiran, pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ atukọ fiimu, naa ba iṣẹlẹ naa lọ.

Iku yii ninu oṣu Kẹrin ti ọkan ninu awọn oṣere to ni orukọ ni iṣowo fiimu lorilẹede Naijiria - ẹni to ti kopa ninu sinima to le ni ọgọrun un jẹ ohun to ba ọpọ lojiji.

Awọn oṣere ti n sọrọ jade nipa bi ajọ Nollywood ko se ki n pese ohun abo ti wọn si n pe fun iyipada.

Lẹsẹkẹsẹ ni Egbe Osere Hollywood lorilẹede Naijiria fesi wi pe awọn ti fofin de gbogbo sinima to jọ yíya lori omi tabi ni ayika omi.

Lẹyin naa wọn rọ àwọn eeyan wọn lati ma tẹlẹ ilana ti ẹgbẹ naa gbe kalẹ.

Nollywood jẹ ile-iṣẹ fiimu kẹta ti o tobi ju lagbaye - lẹyin Hollywood ati Bollywood India.

O ṣe agbejade awọn fiimu to to 2,500 ni ọdun kan - diẹ ninu sinima yii ni wọn n se ni ile.

Aworan oko oju omi

Oríṣun àwòrán, NSIB

Awakọoju omi to wa Junior Pope ko ni iwe-ẹri iwakọ, ko ni forukọsilẹ, eniyan kan ṣoṣo si lo wọ ẹwu abo oju omi ninuọkọ rẹ

Iwadii ti ajọ to n ṣe iwadi abo lorilẹede Naijiria gbe sita loṣu to kọja ri ọpọlọpọ kudiẹkudiẹ:

Awakọ naa ko ni iwe-ẹri lati ṣiṣẹ ọkọ oju omi, ko ni forukọsilẹ ati pe eniyan kan ṣoṣo ni o wọ ẹwu abo oju omi.

Arinrin-ajo yẹn lo mu ẹwu naa fun ara rẹ – o jẹ ọkan ninu eeyan ti ori ko yọ.

Ninu fidio Instagram kan ti wọn fi síta lẹyin iṣẹlẹ naa, sugbọn ti wọn ti yọ danu bayii, Olootu fiimu naa, Adanma Luke, sọ pe wọn sọ fun awọn pe awọn jakẹti wa ati pe wọn fun Junior Pope ni ọkan ṣugbọn ko gba.

"Ero mi ti bajẹ pupọ. Otutu mu mi pupọ. Gbogbo nnkan yii da bi ala si mi. Mo ro pe mo le ji lati ala yii, ”o sọ ninu fidio naa.

Lẹyin naa, o sọ pe: “Ọkan mi ti pin si wẹwẹwẹwẹ bí mo ṣe n kọ eyi… Mo n gbadura, bawo la ṣe le yi ọwọ padà?”

Ruth Kadiri - oṣere, olupilẹṣẹ, ati onkọwe - jẹ ọrẹ si Junior Pope.

“Inu-didun, irẹwẹsi pupọ, ati pe o mu agbara rere wa nigbagbogbo… ati pe mo ro pe gbogbo eniyan nifẹ rẹ gan,”

Awọn iṣẹlẹ bii eyi ti o pa Junior Pope jẹ eyi ti o wọpọ pupọ ni Nollywood - Ruth Kadiri

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn iṣẹlẹ bii eyi ti o pa Junior Pope jẹ eyiti o wọpọ pupọ ni Nollywood, Ruth Kadiri sọ fun BBC.

Oṣere naa, ẹni to ju miliọnu mẹfa awọn ọmọlẹyin lori Instagram, fun ara rẹ ranti iṣẹlẹ kan nigbati o fẹrẹ rì nigba ti o ya sinima lori omi , eyiti o jẹ ki o ronu nipa ibẹru ti oṣere naa “gbọdọ ti la kọja ni iṣẹju to kẹyin igbesi aye rẹ”.

“Mo ni lati ya fiimu kan ki a ko le lo awọn jakẹti abo.

“Mo beere lọwọ ẹgbẹ naa boya ohun gbogbo dara, wọn sọ pe ọkọ oju-omi naa dara lati ya sinima.

Nitori naa mo wọ ọkọ oju omi naa, wọn bẹrẹ si ma lọ, ní ọkọ oju-omi naa ṣubu sinu odo,” Kadiri sọ.

Akẹgbẹ rẹ kan lo doola ẹmi re, to fa soke ninu omi. Bayi, o n pe fun iyipada.

“Gbogbo wa ni a ṣe awọn nnkan to le nitori ifẹ ti a ni fun iṣẹ yii. A ṣe awọn nnkan ti ko yẹ ka ṣe…

“Bi o ṣe n dagba, wa kọ ẹkọ lati fi awọn aini rẹ siwaju. Kii ṣe nitori pe o ko fẹran isẹ yii, ṣugbọn nitori ti aṣiṣe ba wa, opin de. ”

Kadiri sọ pe ai si abo jẹ iṣoro nla fun ẹgbẹ oṣere jakejado ṣugbọn awọn olupilẹsẹ sinima nla le gbe igbesẹ to yẹ lori aabo, ọpọlọpọ awọn olupilẹsẹ sinima kekere ni ko lagbara lati na awọn owo nla.

Lati le mu awọn nnkan yipada si, o gba ni imọran pe o yẹ ki o wọn da ajọ ti yoo ma risi ipese aabo fun awọn eeyan to n ya sinima.

Oṣere Chidi Dike sọ pe iku Junior Pope jẹ “ijidide fun ọpọ eeyan”.

O gba pe "abo jẹ ohun ti ọpọ ko mu lọkunkundun", ṣugbọn sọ fun BBC pe awọn ilọsiwaju ti wa.

O ti ṣakiyesi pe awọn oludari ati awọn olupilẹṣẹ n gbiyanju bayii lati rii daju pe yiya fiimu ko pẹ titi di alẹ, eyiti o tumọ si rin irin ajo ti o lewu pada si ile yoo dikun.

“Ohun gbogbo jẹ eewu… wiwa ọkọ ewu. Igba kan wa ti mo n bọ wale lalẹ diẹ lo ku kí kosi ninu ijamba ọkọ. Ṣugbọn nnkan ti yatọ bayii. ”

Ṣugbọn awọn iyipada eyikeyi ti pẹ ju, dajudaju, fun Junior Pope.

Awọn akọroyin miran to kopa lati kọ iroyin yii ni Emily Horler, Alex Rhodes ati Chimezie UcheAgbo.