Àwọn agbébọn pa àádọ́ta èèyàn, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ni Katsina

Awọn agbegbọn

Oríṣun àwòrán, DefenceHQ

O le ni eeyan marundinlọgbọn ti awọn agbebọn kan ti ṣekupa, ti wọn si tun ji ọpọ gbe lọ lasiko ikọlu kan to waye nipinlẹ Katsina.

Awọn olugbe agbegbe Yargoje sọ fun BBC pe ọjọ kinni ọsẹ yii ni awọn agbebọn ti n kọlu agbegbe naa.

Wọn ni awọn agbebọn kan sadede yawọ ilu naa pẹlu ọkada ni alẹ ọjọ Aiku , ti wọn si bẹrẹ sini sina bolẹ ko to di pe wọn ji ọpọ eeyan gbe lọ.

“Awọn eeyan ti awọn agbebọn yii ṣekupa le ni aadọta nitori a si n ri oku awọn eeyan ninu igbo.

“Wọn ṣekupa ọmọde, obinrin ati ọkunrin, wọn tun wa ji ọpọ eeyan gbe lọ.

"Ọpọ eeyan to le ni ọgbọn lo tun farapa yanayana ninu ikọlu naa ti wọn wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.” Eyi ni ọrọ olugbe kan ti ko fẹ darukọ rẹ.

Bakan naa Al Hassan Ya’u ba awọn akọroyin sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ pe iṣẹlẹ naa ba ọpọ lojiji, to si jẹ pe lati ọjọ Aiku ni ikọlu naa ti bẹrẹ

“Wọn kan sina bolẹ fun gbogbo eeyan, nibẹ ni wọn ti ṣekupa aadọta eeyan, pẹlu aburo mi,” Al Hassan Ya’u ṣalaye lori foonu.

Olugbe agbegbe naa, Abdullahi Yunusa sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ori lo ko oun yọ nigba ti awọn agbebọn naa kọlu ilu rẹ.

“Wọn sọ ilu wa ni ilẹ paniyan, ko fẹ si ile ti ko fara kasa iṣẹlẹ yii.

“A si n ri oku awọn eeyan ninu igbo.” O ṣalaye.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmisana fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Nasiru Bababgida Mu’azu sọ fun BBC pe awọn ẹsọ alabo to n sọ agbegbe naa wa lara awọn to fara kasa ikọlu naa.

Ki lo ti waye tẹlẹ?

Ko ki n ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ ikọlu bayii yoo waye ni agbegbe ariwa orilẹede Naijiria, koda, o ti di ohun to wa lorekore nijọba ibilẹ Kankara.

Pẹlu gbogbo adehun ijọba ati awọn ẹsọ alabo lorilẹede Naijiria, o da bi pe agbara wọn ko ka awọn agbegbọn yii lati le fopin si ikọlu to waye ni gbogbo igba.

Ninu oṣu kejila ọdun 2020, o le ni ọọdurun akẹkọọ ti wọn agbebọn ji gbe ni ile ẹkọ kan ni Kankara.

Wọn gba itusilẹ lẹyin ọsẹ kan ti ijọba ipinlẹ Katsina kede pe wọn ti bẹrẹ si ni ma ba wọn sọrọ.

Bakan naa ni oṣu kẹta ọdun 2024, ọpọ awọn ero ọkọ ni wọn ji gbe lọsan gangan ni agbegbe ijọba ibilẹ Kankara yii ni ipinlẹ Katsina to jẹ ipinlẹ ti Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti wa.