Ọdún 1996 ni Aládùúrà ti sọtẹ́lẹ̀ pé màá jọba, tó sì wá sí ìmúṣẹ

Àkọlé fídíò, Aseyin ti Iseyin: Bẹ́ńsù ojú, ni mo fi kọ ilà mẹ́ta sí ẹ̀ẹ̀kẹ́, kí n tó kọ ilà gidi
Ọdún 1996 ni Aládùúrà ti sọtẹ́lẹ̀ pé màá jọba, tó sì wá sí ìmúṣẹ

Awọn Yoruba lo ni ori ti yoo dade, ko ni se alai dade, ọrun ti yoo lo ejigbara ilẹkẹ, ko ni se alai lo o, bẹẹ ni ibadi ti yoo lo Mọsaaji, aọ ọba to jina korokoro, ko ni se alai lo.

Bẹẹ si ni ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere bayii ni yoo ti maa jẹnu samusamu.

Bẹẹ ni ọrọ igba kekere Aseyin tilu Iseyin, Ọba Olawale Semiu Oyebola ri nitori atọbatẹlẹ, ko to jẹ ba ni.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ni aafin rẹ, Oba Oyebola salaye bo se lo kekere rẹ, bo se de ori apere ọba ati ipo ti awọn oriade wa ninu isejọba.

Bakan naa, Aseyin tun sọrọ nipa asa ẹ dide, ẹ joko ti Oloye Olusegun Obasanjo se.

Aseyin ti Iseyin

“Bẹ́ńsù tí tawọn obinrin fi n tọ́ oju, ni mo fi fa ila mẹta si ẹẹkẹ mi, ki baba baba mi to kọ mi nila”

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba Aseyin tilu Isẹyin ni oun fẹran ila kikọ pupọ, gbogbo ẹbi oun si lo kọ ila, oun ko si fẹ da yatọ laarin wọn.

“Nigba ti mo wa ni kekere, ni wọn gbe mi wa ri baba baba mi, Mustapha Adisa Oyebola, mo ri ila ni ẹẹkẹ gbogbo ẹbi mi, mo wa beere pe ki lo de ti emi ko fi kọ ila, wọn ko si mu ọrọ naa lọkunkundun pẹlu mi.

Mo wa wọle, mo si mu bẹnsu tawọn obinrin fi n fa oju, mo fi kọ ila mẹta-mẹta si ẹẹkẹ mi, baba baba mi eleyi ti mọ nnkan ti oun yoo jẹ niyẹn

Bi wọn se kesi awọn oloola wa, pe ki wọn kọ ila fun mi niyẹn, ti mo si di ẹni to n kọ̀ ila.

Mo lọ̀ silu oyinbo, mo lọ sile ẹkọ̀ lati kọ̀ nipa imọ̀ ẹ́rọ̀ ayarabiasa, ti mo si n kọ̀ awọ̀n eeyan ba ti n se nnkan yii.”

Aseyin ti iseyin

“Ọdun 1996 ni Aladura kan ti riran si mi pe maa jọba, to si wa si imusẹ”

Ọba Oyebola tun salay efun BBC Yoruba bi ipo ọba se kan ati bo se gori itẹ awọn baba nla rẹ.

“Awọn ẹbi mi lo ronu kan mi pe emi ni ipo ọba Asẹyin tọ si, ironu naa lo di ohun loni, ti mo si gori itẹ awọn baba mi bii Asẹyin tilu Isẹyin.

Lọdun 1996, mo pade aladura kan to sọ fun mi pe Ọba ni mi, lati igba naa, n ko ri baba aladura naa mọ.

Nigba ti awọn ẹbi mi pe mi pe ki n wa jọba, mo bi wọn pe baba aladura to gbadura fun mi ni 1996 naa, se wọn le ri.

Wọn sọ pe awọn le ri nitori o si wa laye.

Mo wa ni ki wọn lọ fun ni orukọ mi pe ko gbadura si. Ohun ti baba aladura naa sọ ni 1996, naa lo tun sọ pe emi ni ọba.”

Bakan naa ni Kabiyesi tun sọrọ lori awọn afojusun rẹ ati igbesẹ to n gbe lati fa oju awọn ọmọ oye ti wọn dijọ du ipo Asẹyin mọra.

A ko kan le sadede wọnu rẹ, a gbadura si ni bi o tilẹ jẹ pe mo ti gbe ilu oyinbo, mo pẹ nibẹ”

“Alaafia, Iserere ati irẹpọ ni afojusun mi tawọn ọmọbibi Iseyin mọ pẹlu mi”

Asẹyin tun salaye pe oun mọ ibi ti oun n lọ tori oun ni afojusun ti oun.

“Awọn ọmọ isẹyin mọ afojusun mi, awọn afojusun mi naa ni Alaafia, Iserere ati irẹpọ. Gbogbo ohun ti mo fẹ jẹ da lori nnkan mẹta yii.

Mo si tun fẹ se asaro pẹlu awọn eeyan, paapaa, awọn ti a dijọ dupo ọba, ọpọ wọn ti wa pẹlu mi, ti a dijọ n se ijọba.

Awọn kan ko tii wa, wọn si maa wa nitori isejọba mi da lori alaafia.”

Olusegun Obasanjo

“Lori asa Ẹ dide, ẹ joko ti Baba Obasanjo sọ fawọn oriade, mo bẹ awọn ọmọ Naijiria, ẹ dari jin baba”

Aseyin tilu Iseyin tun sọ ero rẹ lori ohun kan ti Oloye Olusegun Obasanjo se laipẹ yii, ti ọpọ eeyan ri bii iwa ọyaju ati Abuku sawọn oriade nilẹ Yoruba.

Isẹlẹ naa lo waye nilu Isẹyin nigba ti awọn Ọba agbegbe Oke Ogun pe jọ nibi ti Oloye Obasanjo ati gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde peju si lati si ẹka fasiti LAUTECH to wa nilu Iseyin.

Nibẹ si ni Obasanjo ti fajuro si awọn ori ade to wa nikalẹ pe wn ko dide duro lasiko ti gomina n fẹ gun pepele lati sọrọ.

Kia si ni Obasanjo, to jẹ ajagunfẹyinti tẹlẹ, ti n pasẹ fun wọn pe ki wọn dide, duro, nigba to tun ya lo ni ki wn joko.

Idi ree ti awọn eeyan se n pe asa naa ni Ẹ dide, ẹ joko.

Aseyin ni asa ẹ dide, ẹ joko ti di sajẹ ni Naijiria eyi ti baba Olusegun Obasanjo sọ fun awọn oriade.

“Agbalagba ni baba, a ko le sọ pe wọn ko mọ asa ati ise ilẹ Yoruba amọ wọn si inu bi lọjọ yẹn ni.

Ibi ti awọn naa ba wa bayii, wọn yoo ti ronu jinlẹ, da ọrọ naa ro lati se atunse, ti iru rẹ ko si le waye mọ.

Baba lo ni ọba, awọn ọba naa si lo ni baba Obasanjo.

Mo wa n rọ awọn ọmọ Naijiria lati dari jin baba Obasanjo lori ọrọ ẹ dide, ẹ joko tori baba wa ni..”

“Oselu ti gba ipo ọba, awọn ọba ko si ni ipo to yẹ ki wọn wa mọ.”

Nigba to n sọrọ lori ipo ti wọn to awọn ọba alaye si ni Naijiria, Aseyin ni awọn ọba ko si ni ipo to yẹ ki wọn wa mọ nitori oselu ti gba ipo ọba.

“A ti fi agbara fun awọn oloselu, agbara awa ọba si ni wọn n lo.

Ki ni itumọ ijọba gan, itumọ rẹ ni ijọ awọn ọba eyi to di ijọba.

Agbajọ ọwọ awọn ọba ati iselu ọba la ko fun awọn oloselu.

Mo wa n rọ awọn to n dari ijọba pe ki wọn fi aaye gba awọn ọba alaye ninu akoso ijọba, ki wọn wa jọ da si nitori ajeje ọwọ kan ko gbe ẹru dori.