Wo ọ̀pọ̀ ewu tó rọ̀ mọ́ ìdí fífọn àti ọ̀nà tó ń gbà mú ẹ̀mí lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹ abẹ idi fifọn toloyinbo n pe ni Brazilian butt-lift (BBL) jẹ iṣẹ abẹ to maa mu ki idi eeyan tobi si tabi ko tubọ sun soke sii.
Awọn dokita oniṣẹ abẹ yoo gbe eroja silikọnu sinu idi tabi ki wọn ko ọra kuro lati ẹya ara kan, lọ sinu idi, ko le e tobi si i.
Ẹgbẹ awọn dokita oniṣẹ abẹ ẹya ara ti ilẹ Britain fi ọpọlọpọ ikilọ sita nipa ewu tó rọ̀ mọ́ iṣẹ abẹ idi fifọn, eyi to n gbewọn soke julọ pẹlu ida ogun ninu ọgọrun lodọọdun.
Ki ni idi ti awọn eeyan fi n ṣe isẹ abẹ yi?
Dokita Anu Sayal-Bennett oṣiṣẹ eleto ilera kan sọ erongba ọkan rẹ pe, irori fifẹ di ilumọọka ati ọrọ itakun agbaye lo saba maa ṣokunfa ohun ti awọn eeyan fi n ṣe iṣẹ abẹ BBL.
Ọpọ awọn eeyan lo gun baalu lọ silẹ okeere lati ṣe iṣẹ abẹ naa laarin ọdun 2018-2022 amọ ti wọn ko ri se.
Ẹgbẹ awọn dokita onisẹ abẹ ti ilẹ Britain si lo fẹnu ko lati mase sisẹ abẹ idi naa laarin ọdun ta sọrọ rẹ yii.
Ọna wo ni iṣẹ abẹ idi fifọn fi lewu?
Awọn eeyan maa n tipasẹ iṣẹ abẹ idi fifọn padanu ẹmi wọn nitori bi wọn ti ko ọra kuro ninu ara lọsi inu iṣan to tobi ti yoo si gba ibẹ lọsi awọn ẹya ara miran.
Bi iroyin iku nipa iṣẹ abẹ naa ti pọ, lo faa ti ẹgbẹ awọn dokita onisẹ abẹ ti ilẹ Britain fi paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati dẹkun ṣiṣe rẹ.
Dokita Nugent ṣalaye pe awọn idi naa yoo wu kọja oju ẹ, omiran maa n di egbo lẹyin ti wọn bati ko ọra to wa ninu idi fifọn ọun jade tan.
Awọn dokita ọun mẹnuba pataki itọju idi fifọn naa leyin ti iṣẹ abẹ ba waye.
Gbọ ohun ti ẹka eto ilera sọ
Gbogbo iṣẹ abẹ to nii ṣe pẹlu oge ṣiṣe lo ni ewu ọtọọtọ to rọ mọ nipasẹ ṣiṣe akoba fun igbe aye ẹni, yala nipa ti ilera tabi idurore aabo ẹda.
Dokita Nugent wa gba ẹnikẹni to ba fẹ gunle ṣiṣe iru iṣẹ abẹ naa nimọran lati maa ṣe ọfintoto iwadi nipa eyikeyi iṣẹ abẹ to ba niiṣe pẹlu oge ṣiṣe.
Bakan naa lo ni iru ẹni bẹẹ gbọdọ rii daju pe gbogbo eto lo ti to lee lori ati bi yoo ti maa gba itọju to peye lẹyin ti iṣẹ abẹ naa bati di ṣiṣe tan lati dena awọn ewu rẹ.
Aboki sọ fún mi pé lóòtọ́ọ́ ni Aunty Ramota lọ fọn ìdí, tó sì wà lẹ́sẹ̀ kan aye, ẹsẹ̀ kan ọ̀run, èmi kò mọ nkànkan nípa rẹ̀ - Ìjọba Lande ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Instagram
Aboki sọ fún mi pé lóòtọ́ọ́ ni Aunty Ramota lọ fọn ìdí, tó sì wà lẹ́sẹ̀ kan aye, ẹsẹ̀ kan ọ̀run, èmi kò mọ nkànkan nípa rẹ̀ - Ìjọba Lande ṣàlàyé
Gbajugbaja adẹrinposonu, Ganiyu Kehinde Morufu, ẹni ti ọpọ mọ si ijoba Lande ni o ko mọ ohunkohun nipa ohun to ṣẹlẹ si gbajugbaja oṣere tiata, Ramota Adetu, ẹni ti ọpọ mọ si Aunty Ramota ati pe ko le sọ ibi pato Ramota wa lọwọ yii
Ijoba Lande ni awọn eeyan to wa pẹlu gbajugbaja oṣere tiata Aunty Ramota ni oun da lẹbi lori iroyin to lu sita pe Aunty Ramota lọ fọn idi.
Lanaa, ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa ọdun 2024 ni iroyin lu sita lori ayelujara pe Aunty Ramota wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọọrun lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ BBL lati fọn idi.
Iroyin naa ni ile iwosan kan ni Ikorodu ni Aunty Ramota ti ṣe iṣẹ abẹ naa.
"Aboki ni kii ṣe ere sinima ni Ramota n ṣe sugbọn lootitọ ni pe Aunty Ramota lọ fọn idi"
Ijọba Lande ninu fọnran kan to gbe sori opo ayelujara rẹ fẹsun kan awọn to wa layika Aunty Ramota fun bi wọn ṣe kuna lati tan imọlẹ si ohun to ṣẹlẹ pato si Aunty Ramota.
Bẹẹ ba gbagbe, Ijoba Lande sọ fun BBC Yoruba lana pe iroyin ofege ni iroyin nipa pe Aunty Ramota lọ ile iwosan lati lọ fọn idi.
“Ẹyin ọmọ Naijiria, Aunty Ramota ko si ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọọrun; lakọkọ mo ro pe ere lasan sugbọn nigba ti mo ri fọnran pe wọn gbe Ramota wọ wọọdu ni kigba sita
“Oju gba mi ti fun Dare ati Ebute Council lori ohun to ṣẹlẹ si Ramota; paapa iwọ Aboki, o sọ pe o ko mọ ohunkohun nipa ohun to ṣẹlẹ.”
Ijọba Lande ni ọpọ igba ni oun kan si Aboki pe ko jẹwọ fun oun pe ṣe ere sinima ni Ramota n ṣe sugbọn o sọ fun oun pe otitọ ni pe Aunty Ramota lọ fọn idi.
“Mo pe Dare, Ebute Council ati Aunty Lara sugbọn wọn ko gbe ipe mi. Ni gba to ya ni mọ gba ipe pe Aunty Lara rin irinajo.
“Mo pe Aboki, mo bẹ pe ko jẹwọ fun mi to ba jẹ pe ere sinima ni fọnran Ramota to ja kiri lori ayelujara tabi otitọ sugbọn o sọ fun mi pe otitọ ni pe Ramota fọn idi.”
“N ko mọ ibi ti Aunty Ramota wa lọwọ sugbọn mo ki gbogbo lọ fọkanbalẹ nitori ere lasan ni.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ta ni Aunty Ramota?
Ramota Adetu, ti ọpọlọpọ maa n pe ni Aunty Ramota jẹ ọmọ bibi ilu Ikorodu nipinlẹ Eko, ọdun 1981, eyiun ọdun mẹtalelogoji sẹyin ni wọn bi sile aye.
Amọ Aunty Ramota ni aisan kan lara eyi ti ko jẹ ko dagba soke, to si ri kekere bi ọmọde, ti ko si dabi agbalagba rara.
Ọdun mẹta sẹyin ni mama Ramota ku, ti ko si si ẹni to mọ nipa baba rẹ.
Osere tiata ni Ramota, to si tun maa n dẹrin pa osonu.
Bo se da bi ọmọde lo mu ki ọpọ eeyan nifẹ lati wo, to si maa n se ọmọ ile ẹkọ pẹlu gbajumọ adẹrinposonu miran, Ijaba Lande.















