Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Fadá ìjọ Aguda ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ? Ohun tí a mọ̀ rèé

Aworan Alufaa ati iyawo

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun un ọdun 2024 yii ni iroyin kan jade eyi to sọ pe alufaa Fada Jude Obasi ti ijọ Aguda ni Ebonyi ṣe igbeyawo pẹlu ọrẹbinrin rẹ ni ilu Abakaliki.

Koda, fọto alufaa ọhun ati ololufẹ rẹ naa to wọ aṣọ igbeyawo wa ninu iroyin ọhun.

Bakan naa ni fọto naa ṣe afihan bi alufaa Obasi ṣe mu ẹni ti wọn pe ni iyawo rẹ lọwọ niwaju ọpọ alejo to jokoo labẹ pẹpẹ.

Fọto mii tun ṣafihan bi alufaa yii ati iyawo ti ẹnikẹni ko mọ ṣe n rẹrin-in muṣẹ.

Otitọ ni pe awọn to ba jẹ Fada ninu ijọ Aguda maa ti n ṣe ibura wi pe awọn ko ni ṣe igbeyawo tabi ni ibalopọ pẹlu obinrin kankan.

Amọ, iroyin to jade naa sọ pe Fada Jude ni oun ko ni igbagbọ ninu igbe-aye ẹtan ti ọpọ alufaa n gbe.

Aworan Alufaa Jude Obasi ati obinrin to wọ aṣọ iyawo

Oríṣun àwòrán, NTV

Ijọ Aguda ẹkun Abakaliki sọrọ lori iroyin igbeyawo Fada ati ọrẹbinrin rẹ

Ẹwẹ, alakoso ijọ Aguda ẹkun Abakaliki, Matthew Opoke ti ṣalaye pe ko si otitọ kankan ninu iroyin to sọ pe Rẹfẹni Fada Obasi ṣe igbeyawo pẹlu ọrẹbinrin rẹ.

Ninu atẹjade ti Opoke fi sita, o ṣalaye pe ko si alufaa ijọ Aguda kankan ti orukọ rẹ n jẹ Jude Obasi ni Abakaliki.

Bakan naa ni o tun sọrọ lori iroyin ọhun to sọ pe ijọba ibilẹ ariwa Afikpo nipinlẹ Ebonyi ni Alufaa Obasi naa ti wa.

Opoke ni ijọba ibilẹ ariwa Afikpo ko ni alufaa ijọ Aguda kankan ti orukọ rẹ n jẹ Obasi.

O tun fikun ọrọ rẹ pe ko si ijọ Aguda kankan to n jẹ St. Mary’s ni ẹkun Abakaliki.

Opoke tun ṣalaye pe ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe ayẹyẹ igbeyawo kankan waye laarin alufaa kan ati ẹnikan kan ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Karun un ọdun 2024.

Lakootan, Opoke sọ pe iroyin ofege ni iroyin to sọ pe Fada ṣe igbeyawo ni ẹkun Abakaliki.

Aworan atẹjade ijọ Aguda

Oríṣun àwòrán, CATHOLIC DIOCESE OF ABAKALIKI/FACEBOOK

Nibo ni iroyin ofege yii ti wa?

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Okoronkwo Ejike lo fi iroyin naa lede loju opo ayelujara rẹ wi pe Rẹfẹni fada Jude Obasi to jẹ ọmọbibi ijọba ibilẹ ariwa Afikpo nipinlẹ Ebonyi ṣe igbeyawo pẹlu ọrẹbinrin rẹ ti wọn ti jọ wa fun ọdun mẹfa ni ijọ Aguda St. Mary’s niluu Abakaliki.

Okoronkwo sọ ninu atẹjade ti o fi lede loju opo ayelujara rẹ pe Fada Obasi ni oun kọ lati gbe igbe-aye ẹtan ti ọpọ alufaa n gbe ni ikọkọ.

Okoronkwo ni ọpọ eeyan ni ko mọ pe awọn alufaa ijọ Aguda yii ti wọn n gbe igbe aye ẹtan lo bi ọpọ awọn ọmọ awọn obinrin ti ko si nile ọkọ lawujọ.

O ni bawo ni iru awọn alufaa yii ṣe fẹ gori pẹpẹ lati maa waasu tako iwa agbere, ifẹkufẹẹ, iwa aṣẹwo to fi mọ awọn to n lu jibiti lori ayelujara nigba tawọn naa n huwa bẹẹ.

Ọgbẹni Okoronkwo ni ko si ohun to buru nibẹ ti alufaa ti ko ba le mu ara duro ba fẹ iyawo.

O ṣalaye pe iwe mimọ gan an ko tako ki alufaa fi ọkan ninu ọmọ ijọ ṣe aya.

Aworan alufaa ati iyawo

Oríṣun àwòrán, Okoronkwo Ejike/Facebook

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Okorokwo to pe ara rẹ ni oniroyin ori ayelujara yoo fi ọrọ lede nipa ijọ Ọlọrun.

Ti ẹ o ba gbagbe, Okoronkwo wa lara awọn marun un ti Pasitọ ati akọrin ẹmi Nathaniel Bassey gbe lọ sile ẹjọ lori pe wọn n gbe iroyin ofege kiri lori baba ọmọ akọrin ẹmi, Mercy Chinwo.

Okoronkwo pada tọrọ aforijin lori ọrọ naa.

Gbogbo akitiyan BBC lati ba Okoronkwo sọrọ, pabo lo jasi.

Kinni orisun fọto igbeyawo to lu ori ayelujara pa yii?

Fọto igbeyawo to lu ori ayelujara pa yii jẹ fọto Edwin Gathang'i Waiguru, ọmọ ijọ ‘’Catholic Charismatic Church’’ni Kenya eyi to yatọ si ijọ Aguda ti wọn n pe ni ‘’Roman Catholic.’’

BBC Africa fidi rẹ mulẹ pe wọn ṣekupa Gathang'i Waiguru lọjọ kejilelogun ọdun 2023 lẹkun Kiambu niluu Nairobi ti i ṣe olu ilu orilẹede Kenya.

Ọjọ yii gan an ni wọn ni o ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ, Margaret Wanjira Githui.

Nitori naa, kii ṣe ijọ Aguda tawọn alufaa ko ti lanfani lati fẹ iyawo ni ijọ naa.

Ijọ 'Catholic Charismatic Church’ sọ pe awọn gbagbọ ninu ijọ Aguda, ṣugbọn iyatọ to wa laarin awọn mejeeji ni pe awọn alufaa le ṣe igbeyawo ninu ijọ tawọn.