Ilé ẹjọ́ yí àṣẹ Gómìnà Adeleke padà lórí ìyànsípò Owa ti Igbajo

Adegboyega Famodun, Gómìnà Ademola Adeleke, Oba Stephen Kayode

Oríṣun àwòrán, Adegboyega Famodun/Ademola Adeleke/Oba Stephen Kayode/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti kéde pé ìpinnu rẹ̀ láti mórílé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ náà tó ní bí ìjọba ṣe yọ Ọba Adegboyega Famodun gẹ́gẹ́ bí Owa ti ìlú Igbajo kò bá òfin mu.

Àtẹ̀jáde kan tí Kọmíṣánnà fún ètò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun, Oluomo Kolapo Alimi fi léde lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2025 ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga náà bá ìjọba lójijì.

Ní ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kìíní, ọdún 2025 ni Adájọ́ AO Ayoola ti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé bí ìjọba ṣe yọ Ọba Famodun kò tọ̀nà rárá.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ẹ ó rántí pé lásìkò tí ìṣèjọba gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ń parí lọ lọ́dún 2022 ló yan Ọba Famodun gẹ́gẹ́ bí Owa ìlú Igbajo.

Àmọ́ nígbà tí gómìnà Ademola Adeleke gba àkóso ìjọba ìpínlẹ̀ náà ló yí ìyànsípò náà padà tó sì gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti ṣe ìwádìí àwọn ọba tí Oyetola yàn lásìkò náà.

Àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ náà ló mú gómìnà Adeleke gbé òfin tuntun jáde ní oṣù Kìíní ọdún 2024.

Òfin náà sọ pé ìjọba kò tẹ̀lé ìlànà tó yẹ kó tó di pé wọ́n yan Ọba Famodun gẹ́gẹ́ bí Owa ti ìlú Igbajo, tó sì yọ Ọba náà nípò.

Lẹ́yìn náà ni ìjọba kéde Ọba Ademola Stephen Kayode gẹ́gẹ́ bí Owa ti ìlú Igbajo nínú oṣù Kẹta ọdún 2024.

Ìjọba ṣàlàyé pé gbogbo ètò tó yẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà oyè jíjẹ ìpínlẹ̀ Osun ni àwọn tẹ̀lé kí àwọn tó yan Ọba Ademola lọ́ba.

Ìgbésẹ̀ yìí kò tẹ́ ọba Famodun lọ́rùn rárá, tó sì mórílé ilé ẹjọ́ láti yí ìpinnu náà pada.

Ọba Famodun wòye pé ìjọba kò lẹ́tọ̀ọ́ láti rọ òun lóyè nítorí ìyànsípò tẹ̀lé gbogbo ìlànà òfin tó yẹ láti yàn òun gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ó rọ ilé ẹjọ́ láti dá òun padà gẹ́gẹ́ bí Owa ti ìlú Igbajo.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀, Adájọ́ Ayoola ní àṣẹ tí gómìnà Adeleke fi rọ Ọba Famodun lóyè kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti yọ Ọba tí wọ́n yàn pẹ̀lú ìlànà tó yẹ.

Adájọ́ náà ní kí ìjọba dá Famodun padà gẹ́gẹ́ bí Owa ìlú Igbajo.

Ìjọba kọ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba Osun ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga náà kò tẹ́ àwọn lọ́rùn àti pé àwọn máa pe ẹjọ́ náà níjà ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.

Kọmíṣánnà ètò ìròyìn ìpínlẹ̀ Osun, Oluomo Kolapo Alimi sọ pé ilé ẹjọ́ náà lọ́jọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 2024 lo àṣẹ gómìnà Adeleke tí wọ́n ní kò fìdí múlẹ̀ òfin gbé ìdájọ́ kalẹ̀.

Alimi rọ àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn láti ṣe sùúrù, kí wọ́n máa bá iṣẹ́ wọn lọ títí tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn fi máa gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.

Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Osun pàápàá àwọn èèyàn ìlú Igbajo láti wà ní pẹ̀lẹ́ kùtù, kí wọ́n ri dájú pé wọn kò tàpá sófin tí ìgbẹ́jọ́ náà máa fi parí.