‘Ẹ̀mí èèyàn kò níyì mọ́ níbí torí ìbálòpọ̀ àti ìpànìyàn ti di gbẹ̀fẹ́’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Mohamed Osman
- Role, BBC News Arabic
**IKILỌ: IROYIN YII NI AWỌN AWORAN TO LE BA Ọ NINU JẸ
Asiko ti Saadia (kii ṣe orukọ ti obi sọ ọ) lọ bẹ aladugbo rẹ wo ni El-Fasher, ni ado oloro jabọ le ori ile to n gbe.
O salọ sile rẹ lati ba oku awọn ọmọ rẹ obinrin mejeji lẹyin ti ado oloro naa ja le wọn lori.
Ṣaaju iṣẹlẹ yii ni ija ti kọkọ n waye laarin awọn ọmọ ogun ijọba atawọn ogun Rapid Support Forces (RSF).
Saadia sọ fun BBC pe o ṣoro fun oun lati gba ohun ti oju oju ri gbọ lasiko ti oun dele.
O ni “Ohun ti mo ri ko ṣe fẹnusọ, mo ba awọm ọmọ mi Samar ati Sahar ti wọn ti ja wẹlẹwẹlẹ lẹyinkunle wa, ti baba wọn si n wa ẹkun mu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun ti oju iya ri...
Saadia ni “O san fun mi ki n ku, ju awọn ọmọ mi ti mo padanu lọ.”
Asiko to n ro ọrọ naa lọwọ lo gbọ ariwo ẹkun lati ile to ti ile rẹ.
O gbọ pe ado oloro to jabọ sile rẹ naa tun bọ sile to ti ile rẹ, eyii to ṣekupa ọmọ wọn ọkunrin, Riad.
Saadia ati ọkọ rẹ pinnu lati fi ile wọn silẹ, lọ si agọ awọn ogunlende.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn tẹwọ gba idile wọn nibẹ amọ ko pẹ ti wọn de ibẹ ti awọn agbebọn tun kọlu agọ naa.
O ṣalaye pe o ṣoro lati fi ilu El-Fasher silẹ latari bi awọn ṣe n koju oniruru ibudo awọn ologun, ti awọn yẹn si n gba owo ibode ki wọn to le kọja.
Sadia ni oun gbagbọ pe oun to mu ki oun le jade kuro ninu ilu naa ni pe ko si ọkunrin tabi ọdọ kankan pẹlu oun atawọn ti wọn fi ilu silẹ.

Pataki ilu El-Fasher lagbegbe Dafur
Ilu El-Fasher ni ilu kankan ṣoṣo ti awọn ọmọ ogun ijọba ṣi n ṣakoso rẹ lagbegbe Dafur.
Ti ijọba ba le padanu ilu naa, o n tumọ si pe yoo wa labe iṣakoso Mohamed Hamdan Dagalo, ti ọpọ mọ si Hemedti, to jẹ olori ọmọ ogun RSF.
Ilu naa nikan lawọn ajọ oloju aanu le gba ko ounjẹ ati ohun iranwọ wọ agbegbe Dafur.
Amọ ija lemọlemọ to n waye nibẹ ti mu ki igbesẹ aanu bẹẹ sọro.
Akọwe ẹgbẹ awọn agbẹjọro lagbegbe Dafur, Sadiq Hassan sọ pe, nnkan bii ọọdunrun eeyan lo ti ku lagbegbe naa bo tilẹ jẹ pe ijọba sọ pe idaji iye naa lo tii ku.
Hassan sọ pe “Ẹmi eeyan ko niyi mọ nibi, gbogbo igba ni wọn n gbẹmi alaiṣẹ, awọn jagunjagun si n kọlu ara wọn, ninu eyii ti ọpọ awọn alaiṣẹ ti n faragba.””
Hassan ni ifipabanilopọ ko jẹ tuntun mọ nibẹ, bẹẹ ni ipaniyan ni ipakupa.

Oríṣun àwòrán, Mohieldin Mokhtar
Ado oloro bọ sile iwosan
Awọn dokita ile iwosan kan ṣoṣo to n ṣiṣẹ ni el-Fasher sọ pe awọn ti gbe agadagodo sẹnu ọna ile iwosan naa lẹyin ti wọn ju ado oloro sibẹ.
Ile iwosan ọhun, ti ajọ Médecins Sans Frontières (MSF) n ṣeranlọwọ fun lo ti dahoro bayii.
Fun ọpọ ọjọ ni iroyin so pe ado oloro n balẹ sile iwosan South Hospital niluu naa, eyii to fa ọpọlọpọ iku ati ifarapa.
Awọn olugbe agbegbe ọhun ko ni ireti iwosan mọ bayii leyin ti ile iwosan el-Fasher di titi pa.
Ajọ UN ti sọ pe awọn ẹgbẹ to n kọju ija sira wọn n mọọmọ kọlu awọn ile to ṣe koko si araalu.















