'Mo pàdánù ọmọ mẹ́ta sọ́wọ́ ogun ní Sudan'

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ogun làárí, kò sí ẹni tó mọ ìparí rẹ̀.
Àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Sudan ti sọ ìrírí wọn lórí bí wọ́n ṣe sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nígbà tí ojú ogun le ní orílẹ̀ èdè náà.
Arafa Adoum tó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Sudan pamọ́ tó ti sá lọ sí Chad ṣàlàyé pé àwọn ọmọ òun mẹ́ta nínú àwọn méje tí òun bí ló ti bá ogun lọ.
Ó ní òun wà nínú oyún ọmọ keje ni ogun náà bẹ̀rẹ̀ àti pé lásìkò tí òun àtàwọn mẹ́ta tó kù ń sá lọ sí Chad ni òun bímọ náà sí ojú ọ̀nà.
Arafa sọ fún BBC pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti di àwátì àti pé òun kò tilẹ̀ mọ̀ wí pé òun gbé nǹkankan nígbà tí òun fi ń sá lọ náà.
“Gbogbo nǹkan tó wà lórí mi ni bí a ṣe máa kúrò ní Sudan bọ́ sí Andre ni Chad nítorí ogun ti dé ojú rẹ̀ fún wa.”
Àwọn ọ̀gágun méjì ló ń bá ara wọn fa ìjà àgbà ní orílẹ̀ èdè Sudan tí èyí sì ti fa ogun ńlá.
Àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni wọ́n ti kó àwọn ènìyàn wọn kúrò ní orílẹ̀ èdè náà kí wọ́n má ba à fi ara gba ọta.
Èyí kò yọ Nàì















