Èyí ni bí ebi ṣe ń pa àwọn ọmọdé kú ní Sudan

Aworan iya atọmọ t'ebi n pa ni Sudan

Oríṣun àwòrán, DANY ABI KHALIL/BBC

Apa Ariwa Afrika ni orilẹ-ede Sudan wa, olu ilu rẹ ni wọn n pe ni Khartoum.

Ilẹ ọlọraa to n ṣan fun goolu ati epo rọbi ni Sudan latilẹ, ṣugbọn fun ọpọlọpọ ọdun ni wọn ti n koju iṣoro oṣelu ati iṣejọba tootọ.

Eyi ti sọ ilẹ naa di ọkan ninu awọn orilẹ-ede ti ìṣẹ́ n ṣẹ ju lọ lagbaaye.

Ajọ ilẹ okeere kan ti jẹ ko di mimọ pe ìyàn to n mu ni Sudan bayii ju ti afojusun to wa nilẹ nipa rẹ tẹlẹ lọ.

Ati pe ebi ti n pa awọn ọmọde keekeeke, wọn ti n pada sajule ọrun nitori ebi.

Ileeṣẹ iṣegun Médecins Sans Frontières, sọ pe ẹgbẹrun ọmọde ati awọn obinrin ti wọn wa nibudo ogunlende l’Ariwa Dafur, ni ebi buruku n pa.

Wọn ni laarin wakati meji lojumọ, ọmọde kan yoo ṣaa ku nibudo ogunlende to wa ni Zamzam, latari ebi gidi to n pa wọn si ni.

Ogun ti lé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò nílé, wọ́n dèrò ibùdó ogúnléndé

Laarin ọdun kan, ogun to waye laarin awọn ologun Sudan atawọn alatako ti ba nnkan jẹ pupọ, paapaa lagbegbe Dafur.

Ìyàn ati ebi to n pa awọn eeyan ku ti jẹ ko di dandan fawọn oluranlọwọ lati awọn orilẹ-ede mi-in lati dide iranwọ si wọn.

Iwadii ti oṣiṣẹ oluranlọwọ kan loun ṣe nibudo ogunlende kan ṣosọ, fi han pe ebi ti ko ṣee ṣalaye lo n pa awọn ọmọde tọjọ ori wọn ko to marun-un.

Bakan naa lawọn iya wọn naa ko si ri ounjẹ jẹ.

Oṣiṣẹ kan lẹka pajawiri fi awọn fọto ipo tawọn eeyan naa wa ranṣẹ si BBC, o buru ju awọn eyi ta a ti n ri tẹlẹ lọ.

Ogun ti ba ọrọ aje Sudan jẹ, o ti le miliọnu eeyan kuro nile, o si ti ṣoro lati ṣeranwọ fawọn to nilo rẹ.

Ìpè tawọn oluranlọwọ n pe bayii ni pe ki anfaani wa lati ko ounjẹ ati nnkan iranwọ mi-in de ọdọ awọn eeyan yii, bi ireti ba wa lati ṣẹgun iṣoro wọn.