Ìwọ́de 'Ẹnúgbẹ' wáyé ní Oyo, Osun, Eko - Ọlọ́pàá kó àwọn olùwọ́de nílùú Ibadan

Awọn oluwọde ni Osogbo
Aworan awọn ọdọ to se ifẹhonuhan niluu Ibadan

Meji ninu awọn ọdọ to jade lati ṣe ifẹhonuhan ni ayajọ ọjọ ijọba awaaraawa ti di ero atimọle ni olu ileeṣẹ Ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyẹlẹ niluu Ibadan.

Ni nnkan bii aago mẹsan an owurọ yii ni awọn ọdọ naa korajọpọ lati fi ẹhonu han lori awọn ipenija to n koju eto ọrọ aje orilẹede yii ati bi nnkan ko ṣe fi ara rọ fun araalu.

Ọkanojọkan akọle si ni awọn olufẹhonuhan naa gbe lọwọ lati ṣe afihan aidun inu wọn si ipo ti orilẹede Najiria wa lọwọlọwọ bayii.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di nnkan bii aago mẹsan owurọ kọja iṣẹju mẹẹdogun, ṣa dede ni awọn ọga ọlọpaa kan ya de lati olu ileeṣẹ wọn, ti wọn si fi igbaju-igbamu ko meji lọ lara awọn to n fi ẹhonu han.

Lọwọlọwọ bayii, gbogbo ibi ti awọn ọdọ naa korajọpo si lowurọ yii ni agbegbe Mọkọla Roundabout ti da paroparo, ṣugbọn awọn agbofinro ṣi duro digbi si agbegbe naa.

Ki ṣe igba akọkọ ree ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo tu awọn oluwọde June 12 ru lorilẹede Naijiria.

Ọpọ igba ni awọn kaakiri orilẹede Naijiria ti dero ahamọ nitori wọn kopa ninu ifẹhonuhan.

Agbẹjọrọ agba lorilẹede Naijiria, Femi Falana ṣapejuwe iwa ileeṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii eyi to lodi sofin orilẹede Naijiria, to si jẹ pe awọn ọlọpaa n tẹ ẹtọ araalu mọlẹ.

Ko si nnkan amayedẹrun, ebi ati aini tẹsiwaju- ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan àti àwọn ọdọ l'Osun pariwo sita

Awọn olufẹhonuhan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipinlẹ Osun naa ko gbẹyin ninu awọn ipinlẹ tawọn eeyan ti ṣe iwọde lori bi iṣẹ ati oṣi ṣe n ba orilẹ ede Naijiria finra.

Ni agbegbe Ayetoro ni iwọde naa ti bẹrẹ to si pari si Orita Olaiya ni ilu Osogbo, olu ilu ipinlẹ Osun laaarin aago mẹjọ abọ owurọ si aago mọkanla kọja iṣẹju mẹẹdogun.

Niṣe ni awọn oluwọde naa gbe awọn oniruuru akọle ti wọn fi n rọ ijọba lati da iranwọ ori epo bẹntiroolu ati ina mọnamọna si bi o ṣe wa tẹlẹ ki ara le dẹ gbogbo ọmọ Naijiria.

Bakan naa ni wọn n rọ ijọba lati pese eto aabo to peye fun awọn agbẹ ki ounjẹ le pọ yanturu ki ọwọngogo ounjẹ le di ohun igbagbe.

Lodi si awọn nnkan to waye ni ilu Ibadan nibi ti awọn ọlọpaa ti n nawọ gan awọn oluwọde, niṣe ni awọn ẹṣọ aabo bii ọlọpaa, civil defence, DSS atawọn mii ri pe iwọde naa lọ ni irọwọrọsẹ.

Waheed Lawal, ẹni to jẹ Alaga fun ajafẹtọọ ọmọniyan nipinlẹ Ọsun ni ohun to fa iwọde ati ifehonuhan to waye naa ko ṣẹyin lati fi ehonu wọn han lori awọn nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria.

O ni o ti pe ọdún mọkanlelọgbọn bayii ti wọn fagile idibo ọjọ Kejila oṣu Kẹfa ọdun 1993 àti pe igbesẹ igba naa ni wọn fi pagidina anfaani lati mu idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba orileede Naijiria.

Awọn adari Naijiria ko ṣamulo ẹkọ kankan lara MKO Abiola

Awọn oluwọde

Lawal woye pe bi o tilẹ jẹ pe fifagile idibo ọdun naa lọhun jẹ iṣẹ ọwọ awọn adari atawọn abẹṣinkawọ wọn kan, sibẹ, wọn lo o lati fi dun orileede Naijiria atawọn eeyan inu rẹ ni anfaani si iṣẹ rere ati ifọkanbalẹ.

“O bani lọkan jẹ pe lẹyin ọdun mọkanlelọgbọn, a ko tii ni iriri nnkan to farajọ awọn afojusun ipolongo ibo MKO Abiola to duro lorii ipese awọn nnkan amayedẹrun ati igbayegbadun fun tolori-tẹlẹmu.”

O ni o jẹ ohun ibanujẹ pe awọn ẹkọ pataki ati anfaani June 12 ko farahan ni ẹka ijọba kankan rara, eyi to n mu ki ijọba huwa bo ṣe wu wọn si awọn ọmọ Naijiria, pe o dabii ẹni pe awọn adari orilẹ ede Naijiria lati oke delẹ ko ri ẹkọ kankan kọ, bẹẹ ni wọn si ti gbagbe afojusun June 12.

Waheed tun fi kun ọrọ rẹ pe bi iṣejọba buburu ṣe n tẹsiwaju lọdọọdun nipasẹ awọn adari onimọtara-ẹni-nikan laarin awọn ologun atawọn alagbada kaakiri ẹya ati ẹsin n yọri si ininilara, aini, oṣi, aisi idajọ ododo, aisi eto aabo, igbesunmọmi, anikanjọpọn, aisi ireti ati iku aitọjọ ti awọn araalu n koju bayii.

“Lọwọlọwọ bayii, awọn ọmọ Naijiria n la ipenija eto ọrọ-aje to buru ju kọja eleyii to n ṣokunfa aini ati ebi ọpagba-fọwọ-mẹkẹ.

“Oniruuru igbesẹ ti iṣejọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, nipasẹ Banki Agbaye ati ajọ IMF, n gbe lori eto ọrọ-aje tunbọ n ko inira ba awọn ọmọ Naijiria ni.

Ebi, ìṣẹ́ n ba awọn ọmọ Naijiria finra, ijọba nilo lati dide iranwọ

“Yiyọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu, afikun owo ina mọnamọna ati sisọ owo naira wa di gbantuẹyọ ti ṣakoba nla fun eto ọrọ-aje, eyi to si ti sọ awọn olokoowo di alaimọ-ọn-ṣe. Ko jẹ ki owo nitumọ mọ, o n fa ebi, aini, gbogbo owo ounjẹ lo ti gbẹnusoke, bẹẹ ni awọn nnkan ti ko ṣee ma ni ninu ile ti di goolu lọja.”

Lawal ni inira to lagbara ju bayii ni bi awọn ounjẹ gbajumọ laaarin awọn mẹkunu ṣe di ohun ti ọpọ ko le de idi rẹ mọ latari bi wọn ṣe ti gbowo lori kọja ala, to di eyi ti awọn araalu ko le de idi awọn oúnjẹ naa mọ.

O ti han kedere bayii pe ko si ẹgbẹ oṣelu tabi ẹnikẹni to le mu iyipada ba Naijiria bi ko ba si iyipada ninu bi a ṣe n ṣe oṣelu wa - Akin Asifat .

Àwọn miiran to tun kopa ninu iwọde ọhun sọ pe awọn n kan to n ṣẹlẹ ni Naijiria ti kọja ọrọ wi pe ẹnikan jẹ olootọ tabi pe ẹnikan ni ero rere.

Wọn ni eto oṣelu jẹgudujẹra ni awọn oloṣelu Naijiria n ṣe lọwọ yii, gbogbo ẹka lo si ti gbabọde, ti ko ni itumọ mọ.

Wọn ni awọn n fi iwọde yii ati ayajọ June 12 lati ke si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lati sọkalẹ lori akaba Banki Agbaye, ajọ IMF atawọn lajọlajọ agbaye ti wọn n dari iṣejọba rẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn n fẹ awujọ ipin-ko-ju-ipin, nibi ti gbogbo nnkan yoo ti wa deedee, ti aye yoo si rọrun fun gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria.

Ọlọ́pàá, DSS àti Olùwọ́de ń gbéná wojú ara wọn lórí ìwọ́de June 12 òní

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, getty images

Awọn ileeṣẹ eto abo ni Naijiria ti kilọ pe awọn ko fẹ ri ifẹhonuhan kankan ti yoo da omi alaafia ru kaakiri Naijiria lonii to jẹ ayajọ ọjọ ijọba awarawa ni Naijiria.

Lara awọn ileeṣẹ to fi irufẹ ikilọ bẹẹ sita ni ileeṣẹ ọlọpaa ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ke si awọn olori ẹka rẹ kaakiri Naijiria lati ri daju pe ko idarudapọ kankan ko waye lasiko iwọde naa ti yoo waye lonii ‘June 12.’

Agbẹnusọ ọlọpaa ni Naijiria, Muyiwa Adejobi lo fi ikede naa sita ninu atẹjade to fi sọwọ si awọn akọroyin.

Adejobi rọ gbogbo awọn to ba fẹ wọde ki wọn kọkọ fi to ọlọpaa leti ki wọn to ṣe bẹẹ, ki wọn si gba aṣẹ.

Ikede pe iwọde yoo waye

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore /Facebook

Awọn agbegbe wo ni iwọde naa yoo ti waye?

Bo tilẹ jẹ pe kaakiri ilẹ Naijiria lawọn oluwọde naa ti n pinnu lati ṣe ifẹhonuhan, O ṣeeṣe ki awọn oluwọde pọ lawọn agbegbe kan ju awọn ibomii lọ.

Ẹwẹ, lara awọn agbegbe to ṣeeṣe ki iwọde naa ti milẹ titi julọ nilẹ Yoruba ni ilu Eko, Ibadan, Akure ati bẹẹ lọ.

Niluu Eko, abẹ afara ‘Ikeja Underbridge’ ni wọn fi iwọde tiwọn si.

Niluu Akure, awọn oluwọde yoo korajọ si iwaju ileeṣẹ ifiweranṣẹ ‘post office.’

Nipinlẹ Adamawa, iwọde yoo waye ni Ribadu Square, Jimeta-Yola.

Niluu Abuja, iwọde yoo waye niwaju Unity Fountain, bẹrẹ lati aago mẹjọ aarọ.

A ko fẹ iwọde ti yoo da omi alaafia ilu ru – Ọlọpaa, DSS

DSS

Oríṣun àwòrán, X/DSS

Wayi o, ileeṣẹ ọtẹlẹmuye, DSS, ti kede pe oun ko ni ki ẹnikẹni ma ṣe iwọde ṣugbọn kele yoo gbe ọmọ to ba ta felefele.

Ọrọ lo fyii ni DSS fi lede loju opo X rẹ lalẹ ọjọ Iṣegun.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti kilọ pe ẹni to ba ṣe iwọde lati di araalu mii lọwọ loju ọna atijẹ rẹ tabi ko di awọn ọna to lọ si papakọ ofurufu tabi oju ọna ijọba, ti ṣẹ si ofin, yoo si jiya to tọ labẹ ofin.

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, X/Nigeria Police

Ikede pe iwọde yoo waye

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore /Facebook

Ko si ohun ti yoo di iwọde wa lọwọ – Awọn olufẹhonuhan

Wayi o, apapọ awọn ẹgbe to n ṣagbtẹru iwọde ọhun ti sọrọ soke pe mimi kankankan ko ni mi iwọde awọn.

Awọn ẹgbẹ naa tun fẹsun kan awọn agbofinro pe wọn ti fi olori awọn, Sanyaolu Juwon, si atimọle ṣaaju iwọde naa.

Lara awọn to n ṣagbatẹru iwọde ọhun ni Speaker Bright, olori ẹgbẹ TakeitBack Movement ni iha ariwa, Peluola Adewale, fun ẹgbẹ, Joint Action Front (JAF) ati Hassan Taiwo Soweto, adari ẹgbẹ, Education Rights Campaign.

Awọn to ku ni Ayoyinka Oni, alaga ẹgbẹ oṣelu, African Action Congress (AAC), ipinlẹ Eko ati ọgbẹni Kunle Wizeman Ajayi, olori ẹgbẹ, Socialist Workers League, niluu Akure.