Ọrẹ́ méjì tó jẹ́ ìpè ọkùnrin lórí ayélujára kú, ọlọ́pàá ti ẹsẹ̀ bọ ìṣẹ̀lẹ̀ nàá

Oríṣun àwòrán, NDUDIM FAMILY/ HARRISON GWAMISHU
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun ti paṣẹ ki wọn gbe iwadiii dide lori bi awọn ọrẹ meji kan, Celine Ndudim ati Afiba Tandoh ṣe di oloogbe nipinlẹ Abia, ati ipa ti oniṣowo, Andrew Ochekwo, ko ninu iku wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Muyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede lọjọ Aje.
Adejobi ni ọga agba ọlọpaa ti fun awọn to n ṣe iwadii naa ni ọsẹ meji pere lati jabọ ohun ti wọn ba bọ.
Adejobi sọ pe “Nitori ọwọ ti awọn araalu fi mu ọrọ yii ati bi ẹsun naa ṣe lagbara to, olori ileẹṣẹ ọlọpaa ti paṣẹ fun ẹka rẹ nipinlẹ Abia lati bẹrẹ iwadii ni kikun lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni wọn ti n wa Andrew Ochekwo, ti wọn fura si pe oun lo ṣekupa awọn obirin meji naa lẹyin ti wọn ṣabẹwo si.
Ori ikanni ibanidọrẹ lori itakun agbaye lawọn ọrẹ meji ọhun, ti wọn gbera lati Potakot, nipinlẹ Rivers ti lọ ki Ochekwo niluu Aba, nipinlẹ abia ti pade rẹ.
Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Oríṣun àwòrán, MY FAMILY LEADER
Ọmọ Ghana ni Afiba Tandor ni tiẹ, oun ati Celine Ndudim toun jẹ ọmọ Naijiria ni wọn jọ kuro ni Ghana wa si Naijiria.
Tessy Ndudim, ṣalaye pe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin ọdun 2024 loun gba ipe kan lati ọdọ ọrẹ aburo oun kan, pe ọkunrin ti Celine ati Afiba lọọ ba ni Aba ti ji wọn gbe.
O ni ọrẹ wọn naa sọ pe oun ti lọ si Aba lati fọrọ naa to ọlọpaa leti.
O ni Celine ati Afiba fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ọrẹ wọn pe Andrew Amechi, ọkunrin tawọn lọọ ki ti ji awọn gbe o.
Ninu atẹjiṣẹ naa ni wọn ti ni ki ọrẹ awọn lọọ fi ohun to ṣẹlẹ to ọlọpaa leti.
Ki wọn si ke gbajare ki gbogbo aye gbọ.
Tessy sọ pe oun pẹlu fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti ṣugbọn wọn ko ja a kunra.
" O yẹ kawọn ọlọpaa le gba aburo mi ati ọrẹ ẹ silẹ lọsẹ ti mo sọ ohun to ṣẹlẹ fun wọn, ṣugbọn wọn ko ja a kunra.
‘’Wọn sọ fun mi pe eto ni gbogbo ẹ, pe ọrọ yẹn ko ṣee kanju ṣe.
‘’Wọn sọ fun mi pe ijamba kankan ko ni i ṣe wọn nibikibi ti wọn ba wa.
"Ṣugbọn mo taku, wọn si pada lọọ wa wọn lagbegbe ti wọn ni awọn wa gbẹyin.
‘’Wọn wo awọn ile to wa nibẹ, mo ni ki wọn wo ile kan ta a ri fidio ẹ, nitori mo ri mọto kan to jọ eyi ti wọn fi gbe wọn lọ si otẹẹli Aba yẹn.















