Wo ìdí tí nńkan ṣe ń wọ́n sí i ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty image
Fun bii oṣu meloo si asiko yii, ìṣọwọ́ ti awọn ọja fi n gbowo leri, ti wọn n wọn gege ko ṣee ṣapejuwe.
Bi eeyan ba ra ọja kan laaarọ, nigba ti yoo ba fi di irọlẹ, o le ti wọn si i.
Nigba ti yoo ba si fi di ọjọ keji si ikẹta, ọwọngogo to ju ti tẹlẹ ni yoo tun ba de.
Ki wa lohun to n fa a ti gbogbo ọja fi n ṣe bẹẹ di ọwọngogo ninu aisi owo yii, paapaa julọ, ounjẹ?
Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa bi nnkan ṣe n lọ ṣalaye idi ẹ fun BBC.
Ọmọwe Muhammad Shamsudden,olukọ nipa ọrọ aje lati Yunifasiti Bayero, nipinlẹ Kano, ṣe atupalẹ awọn idi naa:
Iye tí à ń ṣẹ́wó orílẹ̀-èdè síra wọn
‘’ Nigbakigba ti owo ilẹ okeere ba gunke si i, iye owo ti Naijiria yoo fi ra ọja nibẹ naa yoo pọ si i ni.
Bi iye ti wọn n ta awọn nnkan orilẹ-ede mi-in ti Naijiria n ra ba wọn si i bi eyi, nigba naa ni awọn eeyan wa maa n pada si nnkan tiwa-n-tiwa.
Bi awọn eeyan ba si ti n ra awọn nnkan eelo ta a n ra lojumọ to ni owo wọn naa yoo maa gara to, ti yoo maa wọn si i.’’
Àfikún owó orí, àì sí ààbò tó péye
Ọmọwe Shamsudeen ṣalaye pe afikun to n ba owo ori, jẹ idi pataki mi-in ti ohun gbogbo fi n gbowo leri ni Naijiria.
O ni ọna kan lati gba owo ori ni fifi owo kun owo ọja.
Aisi aabo to peye lo ni o jẹ idi kẹta ti owo ohun gbogbo ṣe n wọn si i.
Akọṣẹmọṣẹ naa ṣalaye pe awọn agbẹ ko le lọ soko mọ niluu mi-in.
Eyi lo si n fa a ti ọ̀dá ounjẹ fi n waye, ti iwọnba to wa lọja si di owo gege.
‘’Lọdọọdun ni ifasẹyin n ba ipese ounjẹ bayii, nitori iṣoro eto aabo
" Fun idi eyi, kijọba gbe igbesẹ lati koju ọwọngogo ounjẹ ati awọn ọja yooku yii.
Nitori ka ni wọn ti ṣe ohun to yẹ latibẹrẹ ni, a o ni i ba ara wa ninu iru iṣoro ti Naijiria wa bayii.’’
Bẹẹ ni Ọmọwe Muhammad Shamsudeen wi.
Kí ni ọ̀nà àbáyọ?
Ríró owo naira lagbara ni ọna akọkọ ti onimọ nipa ọrọ aje yii la kalẹ.
O ni bi naira ba lagbara, yoo bori ọwọngogo ọja, nitori owo diẹ yoo le ra ohun to jọju.
Shamsudeen sọ pe ki wọn yọwọ iranwọ lori ina, epo ati agbara.
O ni kijọba waa dẹkun afikun owo ori, ki wọn ma si ṣe fi owo kun owo ẹnu ibode.
O ni ko ju bẹẹ lọ ti nnkan yoo fi bẹrẹ si i daa.
Bijọba ba le tẹle awọn ilana yii,Ọmọwe Shamsudeen sọ pe itura yoo de ba Naijiria.
Ninu alaye ajọ ‘Nigerian Bureau of Statistics’ to n sọ onka bi nnkan ṣe n gbowo leri si, wọn ni ida 44.66 lounjẹ fi wọn loṣu karun-un ọdun 2024.
Bẹẹ, ida 24.82 lo wa lọdun to kọja.














