Kí ni ìwọ mọ̀ nípa ìlú Ilorin? Jẹ́ ká lọ sí ìlú mi BBC balẹ̀ sí ìlú Àfọ̀njá

Àkọlé fídíò, Kí ni ìwọ mọ̀ nípa ìlú Ilorin? Jẹ́ ká lọ sí ìlú mi BBC balẹ̀ sí ìlú Àfọ̀njá
Kí ni ìwọ mọ̀ nípa ìlú Ilorin? Jẹ́ ká lọ sí ìlú mi BBC balẹ̀ sí ìlú Àfọ̀njá

Lara awọn ilu ti ọpọ awuyewuye so rọ mọ itẹdo ati agbekalẹ rẹ ni ilu Ilọrin wa.

Amọṣa, bi eniyan ba fi eyi ti si ẹgbẹ kan, lara awọn ilu to dun ju lati gbe tabi ṣe abẹwo si ni ilu Ilọrin jẹ.

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ ilu lorilẹede Naijiria, ati ni ilẹ Afirika, ilu to ni ọpọ ẹya ni ilu Ilọrin jẹ.

Lori itan itẹdo rẹ, bi awọn kan ṣe gbagbọ pe afọnja lo tẹ ilu Ilọrin do, lawọn miran gbagbọ wi pe, ki agbado to de ile aye, o kuku ni nnkan kan ti adiyẹ n jẹ; nitori naa awọn kan ti n gbe ni ilu Ilọrin ko to di pe Afọnja, to jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo fun Alaafin Ọyọ nigba naa to wa dara pọ mọ wọn lẹyin iṣẹlẹ manigbagbe kan to waye lode Ọyọ pẹlu aawọ to waye laarin Afọnja ati Alaafin Aolẹ.

Ki ni awọn itan to so rọ mọ itẹdo ilu Ilọrin sọ?

Oniruuru itan lo so rọ mọ ilu Ilọrin. Gbogbo rẹ si ni awọn onimọ nipa itan sọ wi pe o lẹsẹ nlẹ.

“Awọn Bariba lo kọkọ tẹdo si ilu Ilọrin. Awọn ni wọn si n gbe adugbo ti wọn n pe ni Bariba nilu Ilọrin titi di oni”; eyi ni ohun ti gbajumọ onpitan kan, Alhaji L.A.K. Jimoh ṣe lalaye fun ikọ ‘Ẹ ka lọ si ilu mi’ BBC.

O ni Afọnja atawọn Baruba yii jijọ pa ala ni titi di oni yii.

Aworan awọn ẹlẹṣin ni ilu Ilọrin

Amọṣa o, itan miran sọ pe ẹya Yoruba lo tẹ Ilọrin do lọdun 1450 ki o to di olu ibudo ikọ ogun ijọba ilẹ Ọyọ ki o to di wi pe Shehu Alimi, Alfa oniwasu ẹsin Islam kan gba akoso ilu naa nitori itankalẹ ẹsin Islam nigba naa.

Eyi yoo wu ki itan yii jẹ, ohun kan to dada, gẹgẹ Alhaji Jimoh ṣe fidi rẹ mulẹ ni pe, o ṣoro lati ri eeyan kan nilu Ilọrin ti yoo sọ pe Yoruba pọmbele ti ko labula, tabi Fulani pọnbele ti ko ni adalu ni oun, nitori pe wọn ti wọ inu ara wọn nipasẹ igbeyawo ati ibimọ.

Ede wo lo gbajumọ nilu Ilọrin?

Aworan Ilu Ilọrin

Ilu to jẹ adalu ẹya ati aṣa ni ilu Ilọrin jẹ, pẹlu awọn ẹya Yoruba, Fulani, Nupe, Bariba, Kanuri, koda Igbo ati Hausa ko gbẹyin nibẹ.

Amọṣa Ede Yoruba lo gbajumọ ti gbogbo awọn ọmọ ilu Ilọrin, yala, Yoruba ni o, Fulani ni o, tabi Baruba.gbogbo awọn ẹya to wa ni ilu Ilọrin lo n sọ Yoruba to dan mọran lẹnu.

Ilu to gba alaafia ẹsin ni ilu Ilọrin

Aworan ajodun Durbar ni Ilu Ilọrin

Lara awọn oriki ti awọn eeyan maa n ki ilu Ilọrin ni ilu to jinna sina to sunmọ Aljana. Eyi to jẹyi nitori bi ẹsin Islam ṣe gbalẹ kan nibẹ. Lootọ ẹsin Islam lo gbalẹ kan ni ilu Ilọrin, sibẹ ẹsin Kristẹni gbilẹ pupọ nibẹ; bakannaa ni ẹsin abalaye pẹlu wa nibẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe lawọn asiko kan laipẹ yii, awọn ede aiyede kan bẹ silẹ lori ọrọ ẹsin laarin awọn alfa musulumi kan atawọn oniṣẹṣe kan nibẹ, yatọ si eyi, ilu to gba alaafia ẹsin laaye ni ilu Ilọrin jẹ.

Awọn ibudo to lorukọ nilu Ilọrin

Aworan ẹlẹṣin kan ni Ilu Ilọrin

Lara awọn ibudo lo lamilaaka ti ọpọ awọn arinrinajo le ṣe abẹwo si lo wa ni ilu Ilọrin.

Lara wọn ni Mọṣalaṣi apapọ ilu Ilọrin. Ni ọdun 1820 ni itan sọ pe wọn kọkọ kọ mọṣalaṣi naa.

Awọn ibudo irinajo afẹ miran to wa nilu Ilọrin ni Oke Sobi, eyi ti wọn ni o ṣe abo fun awọn eeyan ibẹ lasiko ogun laye igba ni.

Aworan Emir ilu Ilọrin ataọn eekan ilu naa kan

Okuta Ilọrin, ti awọn onimọ nipa itan sọ pe Okuta ilọ irin ni orukọ rẹ ni ipilẹ nitori ibẹ ni awọn eeyan ti wa maa n lọ irin wọn bii ada ọkọ ati bẹẹbẹẹ lọ nigba naa, eyi gan ni a gbọ wi pe Ilọrin fi gba orukọ rẹ.

Bakan naa ni owo ikoko mimọ, ati aṣọ pẹlu ko gbẹyin ni ilu Ilọrin.