Tani Olohun wọ ẹjọ́ tuntun mìíràn ní Ilorin, agbẹjẹ́rò kan fẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ kàn-án

Tani Olohun

Ni ọjọ Iṣẹgun, ọgbọnjọ, oṣu Kin-in-ni ọdun 2024 ni Abdulazeez Adegbola ti gbogbo eniyan mọ si Tani-Ọlọhun tun gba iwe ipẹjọ mii latọwọ agbẹjọro U S Imam.

Tani Olohun to wa nile ẹjọ lati lọ koju awọn igbẹjọ rẹ to ku pẹlu ireti pe ki ile ẹjọ wọgile awon ẹsun mẹta yooku gẹgẹ bi o ṣe sẹlẹ ni ile ẹjọ Upper Area lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti Alfa Okutagidi fi kan an.

Sugbọn iyalẹnu lo jẹ fun un pe iwe ipẹjọ tuntun miiran lo tun gba nigba to de ile ẹjọ lowurọ yii.

Ẹjọ ti U S Imam ati Dokita Ahmad Olanrewaju Al-Fulani gbe dide ni ile-ẹjọ Majisireeti ni pe arabinrin kan, Osatola Abimbola ti ọpọ mọ si Isẹse Lagba ati Abdulazeez Adegbọla, Tani Ọlọhun ba awọn lorukọ jẹ lori ayelujara.

Ẹsun ibanilorukọjẹ, irọ pipa, ọdaran, dida omi alaafia ilu ru ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn fi kan wọn ati pe awọn ẹsun naa lodi si ofin Naijiria.

Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí rèé

Agbẹjọro awọn Alfa Ilọrin, iyẹn US Imam ati Dr. Ahmad Olanrewaju Al-Fulani ni wọn kọ iwe ẹsun wọn lọjọ kọkanla, oṣu Kin-in-ni ọdun 2024, ti wọn si gba ile-ẹjọ Majisireeti lọ pe awọn fẹ ki Tani-Ọlọhun wa wi tẹnu rẹ lori awọn ẹsun ta wọn ka si lọrun.

Wọn sọ ninu iwe ipẹjọ naa wi pe, Tani Ọlọhun ti o jẹ olujẹjọ keji gbeṣẹ fun olujẹjọ kiini, iyẹn Osatọla Abimbola to n gbe ni orilẹ ede Italy lati maa parọ mọ awọn ati lati maa sọ awọn ọrọ alufanṣa si awọn lori ayelujara.

Wọn ni nise ni o maa n gbe aworan awọn sori ayelujara ti awọn araye yoo si maa ṣepe ati sọ orisirisi ọrọ sii awọn.

Iwe ti wọn fi pe Tani Olohun lẹjọ
Iwe ti wọn fi pe Tani Olohun lẹjọ

Wọn ni koda, niṣe lo tun parọ gbigbero lati seku pa Laji Abass, (Aare Opitan) mọ olupẹjọ keji.

Iwe naa ka pe awọn ọrọ naa jẹ ibanilorukọjẹ ti ẹgbẹẹgbẹrun eeyan si ti wo kaakiri agbaye.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun naa ṣe fi han, ọjọ Karun-un, oṣu Keji, ọdun 2024, ni Tani-Ọlọhun ni igbẹjọ ẹsun naa yoo bẹrẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, Tani-Ọlọhun lo ti n jẹjọ lọna mẹrin ọtọọtọ niluu Ilọrin ni Upper Area Court.

Awọn ẹjọ naa ni eyi ti Alfa Okutagidi pe e, eyi ti awọn ẹgbẹ Ogo Ilọrin pe e, eyi ti Alfa Labeeb Lagbaji pe e ati eyi ti Madrasati Muhammad ka si lọrun.

Alfa Okutagidi ti wọgile ẹjọ ti ẹ to ni ko maa lọ layọ ati alaafia lẹyin ti wọn pe ipade alaafia laarin wọn, ti ẹjọ rẹ si din ku si mẹta.

Wayi o, ẹjọ tun ti di mẹrin lọrun Tani-Ọlọhun pada.