NYSC: Wo ìdí tí ẹgbẹ́ NBA fi pe Kenny Ogungbe àti Mínísítà Nàìjíríà lẹ́jọ́ lórí ọ̀rọ̀ àgùnbánirọ̀

Aworan Minisita Hannatu ati Kenny Ogungbe

Oríṣun àwòrán, Facebook/FMACCE/Kenny Ogungbe

Egbẹ awọn agbẹjọro Naijiria NBA ti rọ ile ẹjọ lati paṣẹ ki wọn yọ Minisita fọrọ aṣa ati iṣẹ ọna Naijiria Hannatu Musawa nipo.

Igun ẹgbẹ naa eyi to n mojuto ọrọ to nii ṣe pẹlu araalu ati ofin idagbasoke ni eyi ṣe pataki tori pe Minisita naa tapa si ofin idasilẹ ajọ agunbanirọ Naijiria NYSC.

Ẹgbẹ naa tun rọ ile ẹjọ lati paṣẹ ki wọn wọgile iwe ẹri ti wọn fun Minisita yi ati gbajumọ alagbega eto orin kikọ nii Kenny Ogungbe tori pe iwe ẹri ti wọn fun wọn tako ofin NYSC,Cap N84.LFN 2024 .

Awọn olupẹjọ yi ninu iwe ipẹjọ FCH/ABJ/05/90/2024 la gọ pe o jẹ alaga NBA-SPIDEL, John Aikpokpo-Martins, ati akọwe NBA-SPIDEL, Funmi Adeogun.

Musawa, Ogungbe, NYSC, ati ijọba apapọ Naijiria ni wọn pe lẹjọ yi.

Ọran ti NBA sọ pe wọn da

Abala ofin NYSC taa darukọ ṣaaju ni awọn olupẹjọ sọ pe awọn wọnyi tapa si ti ọrọ fi di pe awọn pe wọn lẹjọ.

Wọn tẹsiwaju pe fifi aaye gba awọn wọnyi, Musawa ati Ogungbelati kopa ninu eto isinru ọlọdun kan NYSC lẹyin ti wọn kọja ọgbọn ọdun tapa sofin.

Wọn ni ko tọna bẹẹ si ni o ta epo si aṣọ aala awọn to bukata ifarajin fun orileede ẹni.

Bẹẹ naa ni wọn fẹsun kan Musawa ati Ogungbe pe iwe ẹri moyege ti ajọ NYSC gbe le wọn lọwọ ko tọna tori naa otubantẹ lasan ni wọn gbe le wọn lọwọ.

Awọn olupẹjọ n beere nipa ilana ofin idasilẹ NYSC lati ri wi pe ko yẹ ki wọn gba awọn ti wọn fẹsun kan naa ṣiṣẹ yala labẹ ijọba apapọ tabi lọdọ aladani kankan lai ṣe pe wọn ni iwe ẹri NYSC lọwọ.

Wọn ni tori eleyi ni Musawa ko fi lẹtọ lati di ipo Minisita mu lorileede Naijiria lai ṣe pe o di iwe ẹri NYSC mu labẹ ofin NYSC Act, Cap. N84, LFN 2004.

Aworan Kenny Ogungbe ninu aṣọ agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, 2baba/Instagram

Ni oṣu Kẹwa ọdun 2023 ni aworan gba oju opo ayelujara eyi to ṣafihan Kenny Ogungbe ninu aṣo agunbanirọ.

Ohun to to kọ lakọle si awọn aworan yi ni pe ''Aworan ipari NYSC ni Eko.mo dupẹ pe mo pari eto isinru NYSC.''

Aworan yi fa ọpọ awuyewuye nigba naa to jade tori pe awọn eeyan n ṣeemọ pe ṣe igbalaye wa fun ẹni to ba ti kọja ọgbọn ọdun lati kopa ninu eto yi?

Lasiko ti Ogungbe fi aworan yi sita, ẹni ọdun mẹtalelaadọta nii ṣe.

Iru ohun to difa fun Ogungbe yi naa lo mu ki ajọ ajafẹtọmọniyan Naijiria nii, Huriwa figbe sita pe ko yẹ ki Hannatu Musawa dipo Minista mu tori pe o ṣi n kopa nidi eto isinru lọwọ lasiko to burawọle sipo Minisita.

Bẹẹ o si ti kọja ọgbọn ọdun ti ofin faaye kalẹ fun ẹni ba fẹ kopa lati le fi jẹ anfaani yi.

Ati Minisita Hannatu ati Kenny Ogungbe ko ti fesi lori ọrọ yi.

Ohun to ku ti awọn eeyan n beere bayi ni pe ṣe ijiya yoo wa fun awọn mejeeji yi to tapa si ofin idasilẹ NYSC tabi ko ni si ijiya fun wọn.