Ohun táwọn ènìyàn nílò láti kojú àwọn ìpèníjà tó ń bá Nàìjíríà fínra rèé - Ọọni

Àkọlé fídíò, Ooni sọrọ lori ipenija Naijiria
Ohun táwọn ènìyàn nílò láti kojú àwọn ìpèníjà tó ń bá Nàìjíríà fínra rèé - Ọọni
Ọọni Ogunwusi

Ọọni Ile Ife, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Kejì ti rọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa fi àdúrà ran orílẹ̀ èdè yìí kí ìgbà ọ̀tun lè bá ìgbé ayé àwọn ènìyàn.

Ọọni ní gbogbo ìpèníjà tó ń kojú Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́ ni àwọn náà mọ̀ nípa rẹ̀ àti pé òun kò fi ìgbà kankan má fi gbàdúrà fún orílẹ̀ èdè yìí.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí Ọọni ṣe pẹ̀lú BBC News Yorùbá ni baba ti tẹmpẹlẹmọ pé àdúrà jẹ́ ọ̀kan lára èròjà gbòógì tí Nàìjíríà nílò láti gòkè àgbà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrétí pípẹ́ máa ń ṣe ọkàn láàárẹ̀ nítorí ìyàn tó mú ní orílẹ̀ èdè Nàijíríà báyìí, tí gbogbo nǹkan gbówó lórí, síbẹ̀ ó ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò láti ṣe súùrú gidigidi fún ìṣèjọba tó wà lóde.

“À ti wọ ọkọ̀ láti ibìkan dé ibìkan, gbogbo ẹ ló gbówó lórí.”

Ooni lasiko ti wọn nṣọdun nile Ife

Ọba alayé náà ní Ọlọ́run ló kẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí gbogbo nǹka ṣì fi ń lọ létòlétò nítorí àwọn orílẹ̀ èdè tí nǹkan kò le tó báyìí fún míì yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fa rògbòdìyàn.

“Àdúrà wa pọ̀ kí yánpọnyánrin má bẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ nítorí ìyàn mú lóde, ara ń ni ará ìlú ṣùgbọ́n ìjọba tuntun yìí, wọ́n ń gbìyànjú, wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n gbé.

“À ti ba nǹkan jẹ́ ló rọrùn jù, à ti tún nǹkan ló nira, kí Ọlọ́run Olódùmarè má jẹ̀ ẹ́ kí ara ni wá ni.”

Ọọni Ogunwusi tún rọ àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà lórí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ṣe ń fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀ nítorí bí nǹkan ṣe kú díẹ̀ káàtó ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé gbogbo nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó ni yóò padà di ìrọ̀rùn àti pé sùúrù tó lọ́jọ́ ni ọ̀rọ̀ Nàìjíríà.

Bákan náà ló gbàdúrà pé àwọn tó ti ṣe ìrìnàjò kúrò ní orílẹ̀ èdè yìí kò ní gbé sájò.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ètò ààbò, Ọọni ní gbogbo bí ìjínigbé ṣe ń wáyé káàkiri Nàìjíríà jẹ́ ohun tó n kan ènìyàn lóminú.

Ó rọ àwọn àwọn ènìyàn láti máa wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí nítorí ọ̀rọ̀ ààbò kò ṣe é fi dá ẹnìkankan lásìkò yìí.