Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ ọ̀kan lára àwọn ajínigbé tó pa Nabeehah ni Kaduna

Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi
Ọwọ ṣinkun ofin ti tẹ ọkunrin kan, Bello Mohammed, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) ti wọn ni ọkan lara awọn to ji baba kan atawọn ọmọ rẹ obinrin marun-un gbe l’Abuja, ti wọn si tun pa Nabeeha to jẹ agba ninu awọn ọmọbinrin naa ni.
Ogunjọ oṣu kin-in-ni ọdun 2024 yii ni ọwọ ba Bello. Ọmọ ipinlẹ Zamfara ni ṣugbọn Kaduna ni wọn ti mu un lotẹẹli kan lagbegbe Tafa.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe fidi ẹ mulẹ, miliọnu meji ati ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn (2.25m)ni wọn ba lọwọ afurasi ajinigbe naa.
Wọn fi kun un pe ajinigbe apaayan yii gbiyanju lati fun awọn ọlọpaa ni miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo ẹyin, ki wọn le yọnda rẹ, ki iwadii iwa ọdaran rẹ si dopin.
Wọn fi kun un pe ajinigbe apaayan yii gbiyanju lati fun awọn ọlọpaa ni miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo ẹyin, ki wọn le yọnda rẹ, ki iwadii iwa ọdaran rẹ si dopin.
Adejobi salaye pe, “Osisẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti ẹkun agbe Tafa yawọ ile itura kan ni agbegbe Tafa nipinlẹ Kaduna, nibi o ti mu Bello pẹlu owo to le milọnu meji to jẹ owo to gba lọwọ ọkan lara awọn to kosowọ rẹ nipasẹ ijinigbe ni agbegbe naa.
“Afurasi, lasiko ti wọn fi ọrọ jomitoro ọrọ, jẹwọ pe oun wa lara agbebọn to ji awọn mọlẹbi Barrister Ariyo ni agbegbe Bwari lọjọ keji oṣu kinni ọdun 2024, ti wọn si sekupa ọkan lara awọn ji gbe paapa Nabeeha, ọdọmọbinrin to jẹ ọmọ agbẹjọro lọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun 2024 ni bi ahamọ ti wọn ko wọn si nipinlẹ Kaduna.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
“Afurasi yii gbero lati fun ọlọpaa ti mu ni milọnu kan naira sugbọn ọlọpaa na kọ owo naa, to si se iṣẹ rẹ ni ilana to ba ofin mu.
“Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, IGP Kayode Adeolu Egbetokun ti wa palasẹ pe ki afurasi naa, ẹni to tun jẹwọ pe oun lọwọ ninu awọn ẹsun mi pe, pe ko wa ni ahamọ awọn ikọ ọlọpaa DFI-IRT niluu Abuja fun iwadii ẹkunrẹrẹ , ti wọn ri pe wọn mu awọn afurasi yooku ti wọn lọwọ ninu iwa ibajẹ naa.
“Afurasi naa se ran awọn ọlọpaa ninu iwadii wọn.”
Bakan naa ni IGP tun kan sara si DPO Tafa, SP Idris Ibrahim fun bi o ṣe fi ọkan ṣe iṣẹ rẹ ni ilana to ba ofin mu.
Egbedokun tun wa fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe Ileeṣẹ ọlọpaa tun jawọ ninu iwadii wọn lati pe gbogbo afurasi naa fi oju ba ofin ileẹjọ naa.















