Miyetti Allah Fulani: Àfojúsùn tá a fi dá ikọ̀ aláàbò tiwa sílẹ̀̀ rèé

Oríṣun àwòrán, BELLO BODEJO/FACEBOOK
Laipẹ yi ni ikọ Miyetti Allah Kautal Hore Fulani, to jẹ ẹgbẹ awọn darandaran Fulani lorilẹede Naijiri ṣe agbekalẹ ikọ alaabo lati le koju ipenija aabo awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ.
Wọn ṣe eleyi ni paapa lawọn agbegbe to n koju ipenija aabo julọ ni Naijiria.
Ikọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Nomadic Vigilante lede Gẹẹsi la gbọ pe o ni to ọmọ ikọ to le ni ẹgbẹrun meji ni ipinlẹ Nasarawa.
Aarẹ ẹgbẹ Miyetti Allah Bello Abdullahi Bodejo sọ fun BBC pe awọn ṣe idasilẹ ikọ alaabo yii lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo ijọba lati koju awọn agbebọn ati ajinigbe to n ji awọn eeyan ati maalu gbe ni ipinlẹ naa.
''Wọn yoo jọ ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo-ọlọpaa, ologun ati awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati tọpinpin awọn ọdaran tawọn eeyan ko mọ ibi wọn sa pamọ si''
Bello Bodejo sọ pe awọn ko ti fẹnuko tan pẹlu ijọba lori ipinnu yii ṣugbọn o lawọn lero pe ijọba ko ni lodi si.
''A lero pe yoo ri itẹwọgba ijọba apapọ tabi awọn ikọ alaabo Naijiria tori pe a o ran ijọba lọwọ ati awọn Gomina ipinlẹ lori ipenija aabo taa n wi yi.''
Iye awọn ọmọ ikọ alaabo naa

Oríṣun àwòrán, BELLO BODEJO/FACEBOOK
Ikọ alaabo to wa nilẹ yi lawọn ọmọ ẹgbẹ to le ni ẹgbẹrun meji ti wọn si wa ni ipinlẹ Nasarawa ni arin gbungbun Naijiria.
O ni ero awọn ni pe awọn fẹ gb aeeyan ẹgbẹrun mẹrin sinu ikọ naa ṣugbọn awọn to le ni ẹgbẹrun meji ni wọn ri ni Nasarawa nikan.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ireti Miyetti Allah ni pe ki ijọba ati awọn ikọ alaabo ijọba tẹwọgba idasilẹ ikọ alaabo abẹle ti wọn yii.
O fikun pe ''Nasarawa lati bẹrẹ, mo lero pe laarin oṣu mẹfa gbogbo awọn ipenija aabo taa n koju yoo di ohun igagbe pẹlu ogo Ọlọrun''
Adisọkan ati afojusun ikọ alaabo Miyetti Allah
Olori Miyetti Allah sọ pe idi tawọn fi da ikọ alaabo naa silẹ ni lati le fi ri pe iṣọdodo waye nipa fifi iya jẹ awọn to ba lodi sofin.
O ni lọpọ igba ti wọn ba mu eeyan to hu iwa aburu,wọn kii ṣe iwadii to peye ti wọn fii pa iru eeyan bẹẹ.
O ni idi ree ti tawọn fi seto igbaradi fawọn ti wọn gba si ikọ alaabo Miyetti Allah labẹ idari awọn oṣiṣẹ alaabo ati oṣiṣẹfẹyinti nidi iṣẹ aabo.
''Koda ki eeyan jẹ ole, kii ṣe erongba wa ni lati ṣeku pawọn''
Gẹgẹ bo ṣe wi, ''a o fi to awọn ọmọ wa leti pe ti wọn ba gba ọdaran mu,kii ṣe ki wọn fi iya jẹ lọwọ ara wọn bi kii ṣe pe ki wọn fawọn le agbofinro lọwọ lati le ṣe iwadii boya o jẹbi ki wọn si gbe lọ si ileẹjọ''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipenija aabo lawọn ipinlẹ Naijiria
Lati ibẹrẹ pẹpẹn ni awọn darndaran ati agbẹ ti n ba ara wọn gbe pọ nigbe alaafia amọ lẹnu ọdun meloo kan sẹyin,ija ti n waye laarin wọn.
Nibi ọrọ de duro bayii,lemọ lemọ ni ọrọ ija ati ipaniyan laarin awọn agbẹ ati darandaran a maa waye.
Eyi si ti ṣokunfa ipadanu ẹmi ati dukia ti ko si eeyan kan to le sọ pe iye rẹ ree.
Ni ọdun 2016,abajade iwadii kan ti Mercy Corps gbe jade sọ pe ija laarin awọn agbẹ ati darandaran ṣokunfa owo to kere tan biliọnu mẹrinla dọla lọdọọdun.
Ipenija yi peleke lagbegbe aarin gbungbun Naijiria ni paapa awọn ipinlẹ bi Nasarawa, Benue ati Plateau.
Bi nkan ba ṣe bii pe o n walẹ diẹ, yoo tun rugbo pada ju ti tẹlẹ lọ.
Ipenija mii to n koju awọn Fulani ni ijinigbe.
Ipenija yi to bẹrẹ ni ariwa Naijiria ni nkan bi ọdun mẹwaa sẹyin ti wa gbogo bayii to si ko wahala ba awọn darandaran.
Ọpọ awọn afurasi to wa nidi iṣẹlẹ yi jẹ ọmọ Fulani ṣugbọn pupọ awọn Fulani naa lo maa n ko si ọwọ awọn ajinigbe yii.












