Ìdí táwọn rẹfirí ọmọ Nàìjíríà kò ṣe kópa nínú ìdíje Afcon tó ń lọ lọ́wọ́ rèé - CAF

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ CAF to n ri si ere bọọlu nilẹ Africa ti ṣalaye idi tawọn rẹfiri ọmọ Naijiria ko ṣe pẹlu awọn rẹfiri to n fọn feere ninu idije Afcon to n lọ lọwọ lorilẹede Ivory Coast.
Noumandiez Doue to jẹ adari awọn rẹfiri sọ pe lootọọ ni awọn rẹfiri ọmọ Naijiria koju oṣunwọn, amọ, o ni wọn si niṣẹ lati ṣe sii.
Ko tii si rẹfiri ọmọ Naijiria to tii ṣe rẹfiri ifẹsẹwọnsẹ kankan ninu idije Afcon fun ọdun mejidinlogun bayii.
Ọrọ naa si ti di ohun ti ọpọ eeyan n jiroro le lori pe ki lo le de to bẹẹ gan an.
Ni oṣu Kẹsan an ti ajọ Caf kede awọn rẹfiri ti yoo dari awọn ere idaraya ninu idije Afcon 2023, ko si orukọ ọmọ Naijiria kankan nibẹ.
Ọrọ naa kọ ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ni Naijiria lominu.
Amọ, ninu ọrọ rẹ adari awọn rẹfiri, Doue ṣalaye pe awọn to fakọyọ julọ ni ajọ Caf n lo ni idije Afcon to n lọ lọwọ, ki i ṣe awọn to kan koju oṣunwọn diẹ.
‘’Otitọ ni pe awọn rẹfiri Naijiria dara, amọ, rẹfiri to ba maa kopa ninu idije Afcon gbọdọ fakọyọ daadaa.
Awọn rẹfiri Naijiria ni lati gbiyanju sii tori eto lati yan awọn rẹfiri ti yoo dari ifẹsẹwọnsẹ ni idije Afcon ti bẹrẹ lati bii ọdun kan ati abọ sẹyin.
Oriṣiiriṣii isọri ni a ni fawọn rẹfiri ti a n lo, ninu isọri to fakọyọ julọ ni a ti yan awọn rẹfiri ti a n lo ninu idije Afcon to n lọ lọwọ,’’ adari awọn rẹfiri lo ṣalaye bẹẹ.












