Ìbejì tí wọ́n jí tà níléèwòsàn láti inú ẹ̀jẹ̀ pàdé ara wọn lórí TikTok

Oríṣun àwòrán, BBC/ Woody Morris
- Author, By Fay Nurse and Woody Morris
- Role, BBC World Service
Ibeji ni Amy ati Ano, amọ lẹyin ti iya wọn bi wọn tan ni awọn nọọsi gbe wọn kuro lakata rẹ, ti wọn si ta wọn fun obi ọtọtọ.
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ni awọn mejeji to pade ara wọn nipasẹ eto ori tẹlifiṣọn kan ati fidio ori ẹrọ TikTok.
Asiko ti awọn mejeji n sọrọ nipa igbesiaye wọn ni wọn to mọ pe wọn wa lara awọn ogunlọgọ ọmọ wẹwẹ ti awọn kan ji nile iwosan lorilẹ-ede Georgia, ti wọn si ta.

Oríṣun àwòrán, Amy Khvitia
Bi ibeji naa ṣe mọ nipa ara wọn
Ọmọ ọdun mejila lawọn mejeji wa nigba ti irinajo mimọ ara wọn ọhun bẹrẹ.
Lọjọ kan, Amy Khvitia n wo eto Georgia's Got Talent lori ẹrọ amohunmaworan nigba to ri ẹnikan to n jo to si ṣakiyesi pe ọmọ naa jọ oun pupọ.
O ni “Gbogbo eeyan bẹrẹ si n pe iya mi lori aago lati bere idi ti mo fi n jo lori ẹrọ amohunmaworan labẹ orukọ miran.
Ọ̣dun meje lẹyin naa ni Amy fi fidio kan sori ẹrọ TikTok ti ọmọdebirnin mii lati ọna jinjin rere, Ano Sartania, ri fidio ọhun, to si pinnu lati pade ọmọdebirnin naa nitori wọn jọ ara wọn pupọ.
Lẹyinorẹyin, awọn mejeji pade, wọn si bere bi ọrọ ṣe jẹ lọwọ awọn obi wọn, ti awọn obi naa si sọ pe ṣe ni wọn gba awọn mejeji tọ nigba ti wọn wa ni ọmọde jojolo nlaarin ọsẹ diẹ sira wọn.
Awọn mejeji tẹkọ leti lati orilẹ-ede Georgia si Germany lati ṣe iwadii nipa bi irinajo aye wọn ṣe jẹ, ati lati pade iya to bi wọn lọmọ.
Lati ọdun meji ṣeyin ni wọn ti bẹrẹ iwadii naa, eyi to mu ki wọn mọ pe kii ṣe awọn nikan ni irufẹ iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni Georgia.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba orilẹ-ede naa ni oun n ṣe iwadii iwa laabi naa, ko tii fi ṣikun mu ẹnikẹni pato.
Bi wọn ṣe ji awọn ọmọ naa nile iwosan fun tita

Oríṣun àwòrán, BBC/ Woody Morris
Ninu iwadii ati ifimu finlẹ, ni awọn ibeji naa ti ri pe ayederu ni akọsilẹ to wa lori iwe ẹri ọjọ ibi wọn, to fi mọ ọjọ ti wọn bi wọb.
Iya Amy sọ pe nigba ti oun ko ri ọmọ bi, ni ọrẹ oun kan sọ fun oun pe ọmọ tuntun kan ti iya rẹ gbe sọ nu wa ni ileewosan agbegbe wọn. Ṣugbọn yoo nilo lati san owo fun awọn dokita lati gbe ọmọ naa ko si tju rẹ gẹgẹ bi i pe oun lo bi.
Iroyin yii kan naa ni wọn sọ fun iya Ano.
Ko si eyikeyi ninu awọn idile mejeeji to gba awọn ọmọ naa tọ, to mọ pe ibeji ni wọn, bo tilẹ jẹ pe owo nla ni wọn fi gba wọn.
Wọn ni awọn ko mọ pe igbesẹ awọn ko ba ofin mu.
“A ro pe ọna to tọ ni, niwọn igba ti awọn oṣiṣẹ ileewosan lọwọ si i.”
Amọ ko si eyi to sọ iye ti wọn san lati fi ra ọmọ ninu wọn.
Bi wọn ṣe ri ojulowo iya to bi wọn
Wayi o, lẹyin ọpọlọpọ laala, awọn mejeji ti ṣalabapade iya to bi wọn lọmọ ti orukọ rẹ n jẹ Aza.
Oju opo kan lori Facebook , eyi ti ẹni kan da silẹ lati mu ki awọn ẹbi to fura pe wọn ta ọmọ wọn ni Georgia, pada pade awọn ọmọ naa.
Amy sọ itan wọn ni oju opo naa, eyi ti ọmọbinrin kan lati Germany fesi si, pe iya oun bi ibeji obinrin ni Kirtskhi Maternity Hospital lọdun 2002, amọ wọn sọ fun pe awọn ọmọ̀ naa ku.
O ni ṣugbọn iya oun ti n ṣiye meji bayii.
Ayẹwo DNA fihan pe arabinrin ni ọmọbinrin naa jẹ si awọn ibeji, to si n gbe pẹlu iya wọn, Aza, ni orilẹ-ede Germany.
Iya awọn mejeji ni ṣe ni wọn gba awọn ọmọ naa tọ lẹyin to han gbangba pe awọn ko ni le bi ọmọ laye.
Ayẹwo ẹjẹ DNA si fi han pe obinrin Aza ni iya to bi awọn ibeji ọhun
Aza ṣalaye pe lẹyin ti oun bi awọn ibeji naa tan ni oun daku fun ọpọ ọjọ nitori oun wọ ‘coma.’
O ṣalaye fun awọn ọmọ naa pe nigba ti oun ji ni awọn nọọsi sọ fun oun pe awọn ibeji ti oun bi ti ku, awọn si ti palẹ wọn mọ.
Aza pari ọrọ rẹ pe aye oun ṣẹṣẹ ni itumọ ni bayi ti oun pade awọn ọmọ ti oun ro pe wọn ti jade lọjọ to ti pẹ.

Oríṣun àwòrán, BBC/ Woody Morris
Bo tilẹ jẹ pe ijọba orilẹ-ede naa ni oun n ṣe iwadii iwa buruku naa, ko tii fi ṣikun mu ẹnikẹni pato.












