Bíṣọ́ọ̀bù Feyi Daniels rí ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ nípìnlẹ̀ Eko

FEYI DANIELS

Oríṣun àwòrán, FEYI DANIELS

Gbajugbaja pasitọ nipinlẹ Eko, Oluwafeyiropo Daniels, ti ri ẹwọn gbere nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni Onidajọ Ramon Oshodi, ti ile ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun pataki nipinlẹ Eko, da ẹjọ naa.

Onidajọ Oshodi ṣalaye pe Bisọọpu Daniel jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan an, to si da ẹjọ ẹwọ gbere fun ẹsun kan, ati ẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun keji.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, adajọ sọ pe igbimọ to gbọ ẹsun naa fi awọn ẹri to daju han pe o jẹbi.

Onidajọ Oshodi paṣẹ pe ọgba ẹwọn Kirikiri ni ki Daniels ti lo ẹwọn rẹ.

Bakan naa lo sọ pe ki wọn kọ orukọ rẹ sinu iwe akọsilẹ awọn ti jẹbi ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko.

Awọn wo lo fi ẹsun kan Feyi Daniels?

Pasitọ naa to jẹ oludasilẹ ile ijọsin I Reign Ministry, ni ọmọ ijọ rẹ mẹta fi ẹsun kan pe o fi ipa ba wọn lo pọ ni ileegbe rẹ to wa ni Lekki, ati ninu ile ijọsin rẹ ni Ikeja.

Ninu oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni ile ẹjọ kọkọ fi si ahamọ fun ẹsun pe o fi ipa ba obinrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan lo pọ nile rẹ to wa ni Lekki.

Arabinrin naa sọ fun ile ẹjọ pe lasiko eto adura kan ni pasitọ naa ni ibalopọ tipatipa pẹlu oun.

Ohun to yẹ koo mọ nipa Biṣọọbu Oluwafeyiropo Daniels?

Feyi Daniels

Oríṣun àwòrán, Feyi Daniels

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oluwafeyiropo Daniels jẹ ẹni ti Jesu Kristi Oluwa wa farahan ni ojukoju ni jọ ikẹrinla oṣu kẹfa ọdun 2011 ni ilu Ido Ile, ipinlẹ Ekiti”.

Eyi ni akọsọ ọrọ to wa loju opo ijọ “I Reign Christian Ministry” gẹgẹ bi itan ti wọn kọ silẹ.

Itan naa tun ṣalaye pe ninu ifarahan ọhun ni Jesu ti sọ fun Feyi pe “tẹle mi, emi yoo si sọ ọ di eeyan”.

Lẹyin eyi ni itan ọhun ni pe a fi iran han Biṣọọbu Feyi pẹlu aṣẹ pe ko lọ maa ko awọ́n eniyan jọ ti yoo maa bori nile aye gẹgẹ bi Ọba.

Orilẹede Ghana ni ilu Accra ni Biṣọọbu Feyi ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ni Oluwa sọ fun un lodi si ilu Lekki ni Eko to ti kọkọ fẹ bẹrẹ.

Fun idi eyi, iṣ iranṣẹ rẹ bẹrẹ ni ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 2011 ni opopona Spintex road, Accra, Ghana lati ibẹ ni ihinrere ti tan kaakiri awn apa ibomiran nilẹ Afirika.

Wọn ni lẹyin ọdun mẹfa gẹgẹ bi ajihinrere ni awọn gba ipe lati bẹrẹ si ni gbin ijọ kaakiri.

Laarin ọdun 2017 si 2019, wọn ti ni ijọ mẹtala.

Lọwọlọwọ, Biṣọọbu Oluwafeyiropo ni ẹka ijọ rẹ ni Naijiria ni agbegbe Opebi, Ikeja ni Eko ati agbegbe Lekki Epe Peninsula ni ipinlẹ Eko bakan naa.

“Wolii Ọlọrun ni mi, Wolii akọkọ ati ikẹhin too ni lati pade. Wolii si awọn orilẹede ati adari fun gbogbo agbaye. Bakan naa, oniwaasu ọrọ Ọlọrun ati olukọni nipa idokoowo ni mi”. Feyi Daniel sọ eyi funrarẹ loju opo ijọ rẹ.