Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kéde gbèdéke tuntun fún ṣíṣe, títà àti lílo Styrofoam

Abọ ounjẹ styrofoam

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ipinlẹ eko ti kede afikun ọjọ si gbedeke to fun awọn ileeṣẹ to n ṣe abọ ounjẹ fukẹfukẹ, Styrofoam, ati awọn to n ta a.

Opin ọsẹ to kọja ni ijọba ipinlẹ naa kede pe oun ti fi ofin de lilo awọn ike ati abọ ounjẹ ti ko ṣe e lo ju igba kan lọ.

Ijọba sọ pe awọn abọ ounjẹ naa ati awọn nnkan elo miran ti wọn n fi styrofoam ṣe n ṣe akoba fun ayika, to si tun n fi awọn olugbe ipinlẹ naa sinu ewu aarun.

Ṣaaju ni ijọba kede pe lọgan ni ofin tuntun naa yoo bẹrẹ iṣẹ, ṣugbọn nigba ti yoo fi di Ọjọbọ, ijọba yi ohun pada.

Eyi jẹyọ ninu ọrọ ti kọmisanna fun ayika nipinlẹ eko, Ọgbẹni Tokunbo Wahab sọ nibi ipade ijiroro to ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn ileeṣẹ to n ṣe Styrofoam.

Awọn ọmọ ẹgbẹ awọn oludasilẹ ile ounjẹ naa kopa nibẹ.

Ọgbẹni Tokunbo sọ pe ijọba ko ni i yi erongba rẹ pada lori fi fi ofin de lilo awọn abọ naa.

O ṣalaye pe lati bi ọdun mẹta ni ofin naa ti wa nilẹ, to si jẹ pe lati igba naa ni ijọba ti n jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ to n ṣe wọn lori ọna ti opin yoo de ba awọn ike to ni ilo ẹẹkan.

“Wahala ti awọn ike wọn yii n da silẹ laarin ilu, lasiko ojo ati lẹyin rẹ, ko ṣe fi ẹnu sọ.

“Iye ẹmi to si ti ṣofo nipasẹ lilo styrofoam, iparun to n mu ba awọn ẹranko inu omi, ati bo ṣe n dọti ayika, naa ko sẹ ṣakawe.”:

Ọgbẹni Tokunbo sọ pe ẹmi awọn araalu ṣe iyebiye si ijọba ipinlẹ Eko, ju ere ti awọn ileeṣẹ fẹ ẹ jẹ lori ṣiṣe styrofoam.

O ni ilẹkun anfaani kan ṣoṣo ti ijọba le ṣi silẹ fun awọn to n ṣe e , ati awọn alagbata rẹ ni pe ko fi ọsẹ mẹta kun gbedeke to fun wọn.

“Eyi jẹ ọna lati jẹ ki wọn o ta gbogbo ọja ti wọn ti ṣe silẹ tan.”