Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'styrofoam' tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko f’òfin de lílò rẹ̀ f'áráàlú

Aworan Styrofoam ati awọn ike fukẹfukẹ mii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ike fukẹfukẹ yi a maa di oju agbara lọpọ igba
    • Author, Adesola Ikulajolu
    • Role, Broadcast Journalist
    • Reporting from, Lagos

Ijọba ipinlẹ Eko lawọn fofin de lilo ike fukẹfukẹ ati awọn ike bi ijẹun ti lilo wn ko ju ẹẹkan lọ kiakia jakejado ipinlẹ naa.

Ileeṣẹ to n mojuto ayika sọ pe ifofinde yii di dandan lọna ati dẹkun aburu ti awọn ike fukẹfukẹ yi n da silẹ paapa oju agbara ti wọn n di.

Kọmisana feto ayika Tokunboh Wahab ni kiakia ni aṣẹ yi bẹrẹ si ni fẹsẹ rinlẹ. Ṣugbọn iru ipa wo ni yoo ni lara awọn to n taja ni ipinlẹ Eko?

Ni ipinlẹ Eko to jẹ orisun ọrọ aje pataki ni Naijiria, awọn eeyan a maa pese ike yi tawọn eeyan mii a si maa lo nidi ọrọ aje lojumọ.

Bawo wa ni wọn ṣe fẹ ṣe.

Alaye ọna abayọ ko ye wa si ṣugbọn ọga agba kan nileesṣẹ ayika ati ọrọ omi ni Eko sọ fun BBC pe aṣẹ ti gun ọrọ yi gẹgẹ bi Kọmiṣana ṣe pa .

Ki ni Styrofoam ati awọn ike fukẹfukẹ anumadaro oni lilo ẹekan ṣoṣo yii?

Boya ka fi apejuwe ṣalaye ọrọ yi.

Ṣe ẹ ri fukẹfukẹ to wa ninu cooler ounjẹ ọmọ yin ti kii jẹ ki ounjẹ tete tutu nii?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Styrofoam niyẹn.

Tabi fukẹfukẹ to maa n ba pali nkan elo tuntun ti ẹ ba ṣẹṣẹ ra, ohun laa n pe ni Styrofoam.

Wọn a tun maa lo nibi ile kikọ tabi lati fi dina mọ ki ariwo wọ inu iyara tabi ayika kan.

Awọn abọ ounjẹ taa n lo lẹẹkan ṣoṣo ni ti wọn kii ṣe aimọ fun ọpọ.

Wọn a maa pe wọn ni ike ''disposable''

Bi eeyan ba ra ounjẹ lọwọ awọn olounjẹ ohun ni olounjẹ fi n ta ounjẹ taa mọ si ike anumadaro.

Yala ṣibi ni tabi nkan elo ta fi n jẹun gbogbo awọn ike yi kii ṣe ike ta maa n saba lo ju ẹẹkan lọ.

Ni ipinlẹ Eko tori bi awọn eeyan ṣe n ṣe inawo lọpọ igba, awọn ike anumadaro yi pọ gidi gaa an lawujọ.

Labẹ alaye taa n ṣe yi ni pe awọn ike fukẹfukẹ kan wa to ṣe pe wọn ko le parẹ mọ inu ilẹ tawọn mii a si maa parẹ mọ ilẹ.

Awọn to le jẹra ni oloyinbo n pe ni bio degradable.

Awọn ti yoo ṣi wa bẹẹ titi laye ni non bio degradable.

Pupọ awọn ike Styrofoam ati ike anumadaro taa n wi yii ni ko le jẹra mọlẹ.

Ni ipinlẹ Eko lọdọọdun, idọti fukẹfukẹ anumadaro to to tọọnu 870,000 ni wọn n ko jọ, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe fi han.

Styrofoam ati awọn anumadaro ike fukẹfukẹ a maa di oju agbara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ike fukẹfukẹ anumadaro

Ki lo fa ifofinde lilo Styrofoam yii?

Gẹgẹ bi ohun ti Kọmiṣana ayika kọ soju opo Twitter X rẹ, o sọ pe ọpọ oju agbara ni ipinlẹ Eko lo kun fun Styrofoam ti awọn eeyan da sinu rẹ.

O ni ijọba ko wa le kawọ pọnyin maa wo ti talubọ yoo fi ko si ipinlẹ naa loju tori ọrọ Styrofoam yii.

O ṣalaye pe ẹka alamojuto imọtoto ayika, Lawma, a maa ko ọpọ awọn ike wọnyi ninu ọja, ati awọn gareeji ọkọ, nigba ti wọn ba n ṣiṣẹ.

O ni pẹlu ifọwọsowọpọ ajọ Kick Against Indisipline, KAI, awọn yoo bẹrẹ si ni fofin yi rinlẹ nipinlẹ ọhun.

Awọn to ba n pese Styrofoam ati awọn to ba n lo yoo koju ijiya nipa titi ileeṣẹ wọn pa.

Kọmiṣana sọ pe iru idọti ti Styrofoam maa n da silẹ lo le ṣokunfa iyipada oju ọjọ, omiyale ati itankalẹ aarun lawujọ.

Ki ni awọn onimọ sọ?

Onimọ nipa ayika ati iyipada oju ọjọ taa ba sọrọ, Nicholas Adeniyi sọ pe ofin yi ko ni ba awọn eeyan ipinlẹ Eko lara mu lootọ.

Ṣugbọn o ni o ṣe pataki lati tẹle aṣẹ yi nitori pe ipinlẹ Eko jẹ ibi ti omi pọ si ati pe omi a maa gbe awọn ike naa kaakiri lati ibikan si omiran.

Ọgbẹni Nicholas fi kun pe ohun ti wọn tun le ṣe ni pe ki wọn pada si oko aarọ lilo awọn nkan taa le lo ju ẹẹkan ṣoṣo lọ, to fi mọ baagi ti wọn fi paper ṣe lati rọpo awọn ike ti ijọba fofin de yii.

Gẹgẹ bi Nicholas ṣe sọ, iyipada yi yoo mu okun ba ilera mutumuwa nitori pe awọn nkan taa fẹ fi rọpo ike wọnyi ko ni kẹmika ninu ti yoo si jẹ ki wọn tete parẹ mọ ilẹẹlẹ.

Aworan styrofoam ati ike anumadaro to rọ di oju agbara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn orileede to ti fofin de lilo Styrofoam ati ike anumadaro

Ipinlẹ Eko ni ipinlẹ Naijiria akọkọ ti yoo gbe iru igbesẹ yIi.

Orileede Kenya lọdun 2017 fofin lelẹ pe ki awọn alejo si awọn ibudo igbafẹ wọn ma ṣe gbe awọn ike anumadaro tabi ike irọmi wa sibẹ.

Zimbabwe naa ti fofin lile kalẹ nipa owo itanran gọbọi fawọn to ba gbe ounjẹ sinu cooler ti wọn fi ike ṣe.

Orileede mii bi Rwanda ati Morocco naa ti fofin de lilo awọn ike anumadaro.

Lagbaye, China, Ilẹ Gẹẹsi ati America wa lara awọn orileede to ti fofin de lilo ike anumadaro.

Aworan awọn nkan eelo mii tawọn eeyan le fi rọpo styrofoam ati ike anumadaro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan yoo ma wa nkan ilo mii lati fi rọpo awọn ike ti ijoba fofin de

Ki la le lo dipo styrofoam ati awọn ike anumadaro?

Bi ijọba ba ti bẹrẹ si ni fofin yi rinlẹ, o di dandan kawọn eeyan maa wa nkan mi ni lilo dipo styrofoam ati ike anumadaro.

Ninu awọn ohun to le rọpọ wọn ni apo ijẹun ti wọn fi 'paper' ṣe, ife omi ti a ko fi ike ṣe,awọn nkan ijẹun onirin,ṣibi onipako.

Koda a le fi awọn abọ ijẹun onipako rọpo anumadaro tabi awọn 'take away' taa n gba lode ti wọn ba ti gbe ounjẹ fun wa.