Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko f’òfin de lílo abọ́ fùkẹ̀fùkẹ̀ ‘take-away’

Aworan abọ fukẹfukẹ

Oríṣun àwòrán, Tokunbo Wahab/Facebook

Ijọba ipinlẹ Eko ti fi ofin de lilo ati pinpin igo onike ati abọ fukẹfukẹ ni ipinlẹ naa.

Kọmiṣọna ọrọ ayika ati awọn alumọni inu omi, Tokunbo Wahab lo fọrọ yii lede lọjọ Aiku loju opo X rẹ.

Fukẹfukẹ yii ni wọn maa n lo gẹgẹ bi abọ tawọn ti wọn fi n ta ounjẹ kaakiri ibi ti wọn ti n ta ounjẹ.

Ọgbẹni Wahab ni ijọba gbe igbesẹ yii latari ewu ti igo onike ati abọ fukẹfukẹ ti ko le jẹra n fa fun ayika nipinlẹ Eko.

Kọmiṣọna ni gbogbo koto idaminu ni igo onike ati abọ fukẹfukẹ n di bi tilẹ jẹ pe ajọ LAWMA n ko awọn koto idaminu naa ni gbogbo igba.

Ọgbẹni Wahab ni awọn abọ fukẹfukẹ lo pọju ninu awọn idọti ti awọn oṣiṣẹ ajọ LAWMA maa n gba lawọn ọja ati opopona lojoojumọ.

Kọmiṣọna ni ijọba ko le laju silẹ ki o maa wo bi awọn kan ṣe n ba ayika jẹ nipinlẹ Eko.

Ọgbẹni ti wa ke pe ajọ LAWMA ati KAI lati bẹrẹ si ni maa mawọn to ba kọ eti ikun si aṣẹ ijọba.

Bakan naa lo tun sọ fun awọn ajọ mejeeji lati kilọ fun gbogbo ileeṣẹ to ba n ṣe abọ fukẹfukẹ yii wi pe ki wọn dẹkun ṣiṣẹ rẹ.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Ofin to ṣatilẹyin fun igbesẹ ijọba ipinlẹ Eko

Kọmiṣọna ọrọ ayika ati awọn alumọni inu omi ṣalaye pe ijọba gbe igbesẹ yii latari ofin lori ọrọ ayika ti ọdun 2009 eyi ṣokunfa idasilẹ ajọ NESREA eyi to fi ofin de lilo ike ni Naijiria.

Ọgbẹni Wahab tun fikun ọrọ rẹ pe ofin miran lọdun 2017 lori itọju ayika fun ijọba lagbara lati dẹkun tabi ṣe idaduro ohunkohun to ba le mu ewu dani fun eto ilera araalu tabi ayika.

Ọrọ Tokunbo Wahab

Oríṣun àwòrán, Tokunbo Wahab/X

Ijiya fun ẹnikẹni to ba kọ eti ikun si aṣẹ ijọba

Kọmiṣọna wa rọ awọn eeyan to n lo abọ fukẹfukẹ yii atawọn ileeṣẹ to n ṣe e wi pe ki wọn wa nkan mii lo, bi bẹẹ kọ wọn o san owo faini to ga tabi ki ijọba ti ileeṣẹ wọn pa.

Ara ijiya fun ileeṣẹ ti aje ọrọ yii ba ṣi mọ lori ni pe ki ileeṣẹ naa san ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ti ijọba fi gba titi ati owo ti ijọba fi n ko gọta lojoojumọ.

‘’A o le gba kawọn eeyan kan ti wọn ni ileeṣẹ ti wọn n ri owo ribiribi nibẹ maa ṣakoba fawọn ọgọọrọ olugbe ipinlẹ Eko pẹlu bi abọ fukẹfukẹ ati igo onike ti wọn n ṣe n dọti ayika.

Awọn nkan yii lo n fa ẹkun omi, ayipada oju-ọjọ ati arun bi onigbameji.

Abọ fukẹ-fukẹ ati igo onike ti eeyan le ju nu dun un lo ni tootọọ, amọ, akọba lo n ṣe fun awujọ,’’ kọmiṣọna lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Wahab wa rọ awọn onibara atawọn eeyan ipinlẹ Eko lati dẹkun lilo abọ fukẹfukẹ ati igo onike.

O ni ki wọn gbiyanju lati maa lo abọ gidi fi ra ounjẹ ati kondoro ti wọn le maa rọ omi si.