Ọwọ́ tẹ Ọlọ́pàá mẹ́ta tó jí ọkùnrin kan gbé, gbà $3000 lọ́wọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Rivers tí kede síta pe awọn ti ọwọ tẹ ọlọpaa mẹta kan to fọwọsowọpọ lati jí ọkùnrin kan gbe, ti wọn si tun gba owo toto ẹgbẹrun mẹta Dọla lọwọ rẹ niluu Port Harcourt.
Ọkùnrin naa ni awọn ọlọpaa yii gbe kuro ni olu ilu ipinlẹ Rivers, ti wọn si gbe e lọ si bi ti wọn ti fi ipa gba owo kuro ninu apo owo asunwọn rẹ, ki wọn o to tu silẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Grace Iringe-Koko lo kede ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede fun awọn akọroyin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Igbesẹ yii waye lẹyin ti ọkùnrin kan, Harrison Gwamnishu bọ sori ayelujara X, to i jẹ ko di mimọ bi awọn Ọlọpaa ipinlẹ Rivers ṣe kuro ni Port Harcourt lọ si Aba nipinlẹ Abia, ti wọn si mu ọkùnrin kan, gbe lọ sí Bayelsa, pada si Ughelli nipinlẹ Delta.
"Lẹyin ti wọn gba owo ẹgbẹrun mẹta dọla, wọn gbe ọkùnrin naa ju sì Port Harcourt.
Botilẹ jẹ pe, ẹsẹ ọkùnrin naa ti awọn Ọlọpaa fi lọ gbe ko han síta sugbọn Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Rivers ni iwadii ti bẹrẹ.
"Awọn Ọlọpaa mẹta yii ti wa ni ahamọ bi iwadii ṣe n tẹsiwaju."
O wa se leri pe gbogbo ohun to sokunkun yoo ri imọlẹ laipẹ.















