Ernest Bai Koroma, Ààrẹ Sierra Leone tẹ́lẹ̀ tó ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìdìtẹ̀gbàjọba, balẹ̀ sí Nàìjíríà fún ìtọ́jú

Aworan Ernest Bai Korina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ tẹlẹ fun orilẹede Sierra Leone, Ernest Bai Koroma ti morile Naijiria fun itọju ara rẹ pẹlu bi o se n jẹjọ pe o lọwọ ninu iditẹgbajọba to waye ni olu ilu orilẹede lọdun to kọja.

Ernest Bai Koroma ni ileẹjọ giga to joko lọjọ Ọjọru fun aye oṣu mẹta lati lọ ṣe itọju ara rẹ.

Aare Sierra Leone ti sapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bii eyi to fi wa ọmọluabi han.

Sugbọn ọpọ lo gbagbọ that adehun wa to fun Bai Koroma lati lọ se atipo ni ilẹ okere.

Igbẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan ni yoo bẹrẹ ninu oṣu kẹta ọdun 2023.

Bai Koroma lo jẹ olori fun Sierra Leone fun ọdun mọkanla lati ọdun 2007 wọ ọdun 2018, ti aarẹ to wa ni lọwọ, Julius Maada Bio si gba ipo lọwọ rẹ lẹyin eto idibo.

Baalu Aarẹ Naijiria lo gbe aarẹ tẹlẹ naa ni papakọ ofurufo Freetown ni dede ago kan abọ.

Gbogbo lo n sẹlẹ bi awọn eeyan se n sọ pe ECOWAS ti tọwọbọ adehun pẹlu Sierra Leone lati fi aye silẹ fun aarẹ tẹlẹ, ẹni adọrin ọdun lati kuro lorilẹede naa lati fi aye silẹ fun alaafia si rogbodiyan to ti bẹ silẹ lati igba ti iditẹgbajọba naa ti waye.

Nigba to n ba awọn araalu sọrọ, Aarẹ Julius Maada Bio ni gbogbo ọrọ nipa aarẹ tẹlẹ wa niwaju ileẹjọ.

“Ileẹjọ ti fun aarẹ tẹlẹ ni anfani lati kuro lorilẹede lati lọ se itọju ara rẹ, ti wọn yoo si da igbẹjọ duro lasiko ti ku si lorilẹede.”

Aarẹ Bio ni pe Aarẹ tẹlẹ se irinajo ko tumọ si pe ẹjọ naa ko lẹsẹ mọ nilẹ, ati pe eyi ti safihan pe ọrọ naa ki i se ọrọ oṣelu sugbọn ẹtọ ni fi otitọ han sita lori ogun to waye ni ọjọ kẹrinsinlogun oṣu kọkanla

Nibi ikọlu to waye ninu oṣu kọkanla, awọn agbebọn yabo ileeṣẹ ologun ati ọgba ẹwọn, ti wọn si tui awọn ẹlẹwọn ẹgbẹrun meji silẹ.

Awọn alasẹ ni o to eeyan mọkanlelogun to padanu ẹmi wọn nibi ikọlu naa.